Categories
Notes Yoruba

Akole Ise:- Ede:- Awon isori gbolohun Ede Yoruba Gege bi Ihun

Gbolohun ni afo ti o kun, to si ni ise to n se nibikibi ti won be ti je jade.

Gbolohun Abode/Eleyo oro-ise

Eyi ni gbolohun ti ko ni ju oro-ise kon lo

Gbolohun abode kii gun, gbolohun inu re si gbodo je oro ise kiku.  Apeere ;

Dosumu mu gaari

Aduke sun

Ihun gbolohun abode/eleyo oro-ise

  1. O le je oro ise kan.  Apeere ;  lo, sun, jokoo, dide, jade, wole
  2. Oro ise kan ati oro apola.  Apeere; 
  3. Anike sun fonfon
  4. Ile ga gogoro
  5. Oluwa, oro ise ati abo.  Apeere;
  6. Ige je eba
  7. Oluko ra oko
  8. O le  je oluwa, oro ise kan, abo ati apola atokun.  Apeere
  9. Aina ru igi ni ana
  10. Ojo da ile si odo
  11. O le je oluwa, oro ise kan ati apola atokun.  Apeere ;
  12. Mo lo si oko
  13. Bab wa si ile

Gbolohun Alakanpo

Eyi ni gbolohun ti afi oro asopo kanpo mo ara won

Akanpo gbolohun eleyo oro ise meji nipa lilo oro asopo ni gbolohun alakanpo.

Awon oro asopo ti a le fi so gbolohun eleyo oro ise meji po ni wonyi; ayafi, sugbon, oun, ati, anbosi, amo, nitori, pelu, tabi, koda, boya, yale abbl.

Apeere;

  1. Yemi ke sugbon n ko gbo
  2. Tunde yoo ra aso tabi ki o ra iwe

Igbelewon:-

  1. Kin ni gbolohun?
  2. Salaye gbolohun abode ati alakanpo pelu apeere meji meji

Ise Asetilewa:-  ko apeere gbolohun abode ati gbolohun alakanpo meji meji

Asa:-  Asa Iranra-Eni Lowo I

Awon agba bo won ni « Ajeje owo kan ko gberu dori ».  Eyi tun mo si pe owo kan soso ko gberu dori.  Bee si ni « Agbajo owo la fi iso aya » a ko le fi ika eyo kan so aya.  Bi a ba pa owo po fi se nnkan tabi bi a b pa owo po fi ran ara eni lowo, oun lo le mu iroran wa.

Emi imoore se pataki ni ile Yoruba.  Awon yoruba maa n fe ki eniyan ti a se oore fun fi emi imoore han idi nyi ti won fi n s ope Eni ti ase loore ti ko dupe o dabi ki olosa ko ni leru lo sugbon    

kii se pe ki eniyan se ni loore ki o lo soo ti i.

Asiko/igba ti Yoruba n ran ara won lowo laye atijo

  1. Asiko isoro
  2. Ni gba nnkan ayo ati idunnu won a maa fun ara won lebun
  3. Won a maa ya ara won lowo ni gba ti inawo nla ba sele si enikan abbl.

Ona ti a n gba ran ara eni lowo ni ile Yoruba

Aaro:–  Awon odomokunrin ti oko won ko fi bee jina si ara won a maa be arar won ni aaro, won yoo si maa lo si oko ara won kaakari lojo Kookan.  Won kii poju.

Awon obinrin ti iro won ko ju ara li naa maa n be ara won ni aro ti o je mo ise obinrin

Aanfaani aaro

  • O maa n mu ki ise ya
  • Ise ti o ro enikan loju lati s e yoodi sise pelu irorun bi a ba da owo boo
  • O n mu ife ati irepo wa laarin ara eni
  • O n mu ki a ni igbekele ninu ara eni
  • O je ona iranra eni lowo

Owe :-  Ise ti o ba po jaburata ti enikan ko le da se funra ra bi o ti wu ki o lagbara to ni won nfi owe se. 

  • A le fi owe sa igi ti yoo ro ile
  • A le fi pa koriko tabi ewe ti yoo fi bo ile gege bu orule.

Ana eni le be ni lowe, to kunrin tobinrin tomode tagba ni a maa n be lowe.  Gege bi apeere, bi o ba je owe agiri ile mimo, awon omode ni yo pon omi, awon gende yoo sa yepe, won yoo po o lati fi mole, awon agba obinrin yoo si maa se ounje.

Ebese :-  Eyi ni ise ti ko po ti a be awon eniyan lati se ni asiko inawo repete ti n bo ni waju

Arokodoko :-  Awon odomekunrin ti won je iro ti oko won ko jina si ara won a maa sowopo ba ara won se ise loko.

Esusu :-  Awon ti won mo ara won deledele ti won tun je olotito maa n ko ara won jo laye atijo lati da esusu won yoo  seto laarin ara won iye ti eni kookan yoo maa da gege bi agbara re se mo.  Emi ti won yan gege bu oloro won ni a n pe ni olori-eleeesu ».  iye ti eniyan ba da ni yoo gba.

Ajo :-  A maa n da ajo bi igba ti a n da esusu sugbon iyato ti o wa laarin ajo ati esusu ni pe iye ti eniyan ba da ni yo ko ninu esusu sugbon ninu ajo dandan ni ki a se eyo kan ku, o le je iye ti eniyan n da lojo kan tabi leekan soso eyi ni ere eni ti n gba ajo.

Oja Awin/aradosu :-  Ti to eni ti o n ta oja lo lati gba oja lai san owo ni kiakia wopo laye atijo.  Ti tele adehun lori ojo ti a oo san owo oja pada se pataki ki oloja le tun le se iranlowo fun inu eni bee lojo miran.

San die-die/osomaalo :-  Eniyan le ra oja awin pelu adehun lati maa san owo re diedie titi yo fi san ta.  Pelu ipa/agidi ni awon ti n sun owo fi maa n gba gbese won ni aye atijo.

Igbelewon :-

  1. Salaye ase iranra-eni lowo
  2. Asiko wo lo tona lati se iranlowo fun ara won
  3. Salaye awo ona ti a le gba ran eni lowo laye atijo

Ise Asetilewa:-N je o dara lati se iranlowo lode-oni? Salaye ona marun-un ti awon akeekoo le  gba se iranlowo fun ara won lode oni

LITRESO :-  Kika iwe litreso ti ijoba yan.

Exit mobile version