Categories
Yoruba

Igbagbo awon yoruba nipa aseyinwaye

Awon Yoruba ni igbagbo ti o jinle ninu asiyinwaye (iyen leyin iku) igbagbo ninu pipada wa si aye eni to ti ku yii wan i aye atijo bee ni o si wa titi di oni.

Ni ona kinni, nibi sinku agba fi ese igbagbo yii mule. Eyi ri bee nigba ti agbalagba kan ninu idile ba ku (yala okunrin tabi obinrin) ti iyawo omo re ba wa ninu oyun ni akoko naa ti omobinrin naa ba ti mo okunrin tabi obinrin leyin iku baba tabi iya oruko ti won yoo so inu enia bee ni (ti n baje okunrin) Babatunde, Babajide, abbl. Sugbon ti o baje omobinrin, oruko ti won yio ma a pee ni Yetunde, Yeside, Iyabo ati Yejide.

Ona keji ewe awon Yoruba tun gbagbo pet i enikan ba ku nigba ti ojo re ni oye ko tii pe lati ku kii lo si orun taara se ni won yoo wa ibikan tedo si tabi ki won maa rare kiri titi ojo re yoo fipe ni aye ki o to le pada lo si orun. Iru awon ti won ba fi ojo olojo lo bayii ni a pe akudaaya tabi okutan.

Ona keta, igbagbo awon Yoruba ni pe abiku fi idi iye leyin iku mule. Abiku ni omo ti o ku, ti o tun padawa si aye, o tun le ku, ki osi tun pada waye ni igba ti o ba wuu. Atigbo nipa abiku ti wonge ikaowo reti o si je pe igbati obinrin to bii yio padabimo, ika owo mesan ni omo tuntun ti o bi gbe waye. Eyi fihan pe omo akoko ti won ge ika owo re ni o padawaye. Won a maa so oruko omo bee ni: Kokumo, Igbekoyi, Malomo, Bamitale, Durorike, Kosoko abbl.

Ona kerin, awon Yoruba tun gbagbo pea won ati egbere wa, atipe eniyan ni won to di ebora D. O Faganwa fi igbagbo yii han ninu awon iwe itan aroso. Opo eda inu itan iwe re je oro tabi owin. Inu igi bii igi iroko, igi agbalumo, inu igi ibepe, igi atisa, agbo ogede ni won ngbe. Won a si maa yipada si eniyan nigba ti o ba wunwon. Awon Yoruba tile gba pe won maa n na oja ale. Bakan naa, ni awon ogboju ode maa n royin itu ti awon ebora maa n fi won pa ninu igbo nigba ti won ba n sode ninu igbo.

Ona, karun un, awon Yoruba tun gbagbo pea won ele re omo wa. Awon omo elegbe bi eyi maa n yo obi won lenu. Aimoye won ni won n maa n loagbara won leti se obi won ni ibi. Ipese niwon maa n se fun lati tu won loju. Won ti e maa n ka eewo fun awon obi won ti won ko gbodo lana lati se bii beeko, won yoo yo iya won lenu.

Won tun gbagbo wipe awon eyan to n wo aso egungun o se eniyan lasan pe awo alagbara eyan ni won tabi ole.

AKORI EKO: AWE GBOLOHUN (CLAUSE)

Awe gbolohun ni iso ti o ni oluwa ati ohun ti oluwa se. Bi apeere:

Atoke mu omi

Adepoju ti jeun

Sade gun igi

Awe gbolohun le je ipede ti ko ni ju apola oruko ati apola – ise kookan lo. Apeere

Egbeyemi ri won

Mo gba ebun naa

Awon ni won wa

Awe gbolohun le da duro ki o ni itumo. Bi apeere

Ishola ati Ajani ra aso

Omi ero naa mo

Awe gbolohun miiran le da duro ki o ma ni itumo. Bi apeere

Ti a ba ko ile

Iba ke si mi

Awon eyi ni a mo si awe gbolohun afarahe ti won ko le da duro laisi olori awe gbolohun.

Awe gbolhun le da duro bi odidi gbolohun, iru awe gbolohun bee ni a n pen i olori awe gbolohun. Bi apeere:

Ade mo

Abeke gbon

Bisi rerin-in (Bisi ni oluwa, rerin-in ni koko gbolohun to so nkan ni oluwa)

Awe gbolohun kii ju apola oruko ati apola ise kan lo. Bi apeere:

Apola oruko (Noun Phrase)                            Apola – ise (Verb Phrase)

Bola                                                                 wa lanaa

Joonu igbe hin adun                                        gbe apore si le

ORISII AWE GBOLOHUN (TYPES OF CLAUSE)

  1. Olori Awe Gbolohun (Main Clause): eyi le da duro ti le kuro nibe. Ofi ihun jo gbolohun abode tobi gbolohun eleyo oro – ise. Apeere.

Awon omode feran iresi

Aja ogundeji ku

Ise dara

Gbadamosi gun iya re

  1. Awe Gbolohun Afaiahe: Inu ihun gbolohun opolo oro – ise tabi oniba ni a ti maa n ri awe gbolohun afarahe. Eyi ni awe gbolohun ti ko le da duro ki o si fun wa ni itumo ayafi ti o ba fi ara ti olori awe gbolohun. Ona meta ni awe gbolohun pin si, awon ni:
  2. Awe gbolohun afarahe asapejuwe: Eyi maa n tele oro – oruko tabi apola oruko ‘t’ ni atoka tabi ami je ki a mo nipa apejuwe nkan. Bi apeere:

Apinke ti o sun ti dide

Aso Ankara ti mo ra dara

Omoge ti mon soro re niyi

  1. Awe gbolohun afarahe asodoruko: ‘pe’ ni o maa n be re aye gbolohun yii, o le sise oluwa ati abo. O si maa n sise isodoruko ninu ihun gbolohun won maa n pen. Apeere:

Aja naa ku ni gba ti oko ko luu

Emi yoo lo nisinsinyii ti mo gbo pe won de

Bolaji fa oju ro nitori inu re ko dun

Ole naa ku nigba ti olopaa kolu won

Ise Asetilewa

Exit mobile version