Categories
Yoruba

Ise ajorin

Ise ajorin ni awon ti won n sise irin jijo, ti a mo si ‘Weda’ ni ode-oni. Bi a pe won ni alagbede, a ko jayo pa nitori igbe kan naa ni ode won n de. Ise yii lowo lori pupo.

IWULO ISE AJORIN

  • Bi ko si ajorin, awon agbe ko le sise. Awon ni won n jo ada, akoro, aake tabi obe to ba kan, tabi oko ti o bay a.
  • Ni ode-oni, awon ajorin igbalode ni won n jo irin geeti ati ferese ile.
  • Awon naa ni won n jo awon ibi ti o ba je ni ara oko oju omi, oju-irin ati ti ori-ile, tatapupu, omolanke ati bee bee lo.

OHUN ELO WON: Ni aye atijo irinse alagbede ko ju owu, omo owu, iponrin, ewiri, emu ati eesan lo. Awon ajorin ode-oni n lo ina gaasi ati kanbaadi, irin ati bee bee lo.

ILANA IKOSI: Niwo igba to je ise abinibi, kekere ni omo won yoo ti maa fi oju si ise yii. Igba ti o ba dagba ni yoo to da ise ya.

  1. ISE ALAPATA

Ise alapata je ise abinibi awon iran kan ni ile Yoruba. Awon okunrin ni won po nidii ise yii, bi o tile je pea won obinrin naa ko gbeyin ninu owo eran tita. Ise alapata je mo ise eran pipa, eran tita. Maluu pipa ni a mo won mo teleteleeri. Sugbon ni ode-oni won ti n pa ewure ati agbo ta. Won tile ti n ni awon odo-eran ti won ti n pa awon eran wonyi.

PATAKI ISE ALAPATA

  • Nipase awon alapata ni eran se n wo ile Yoruba lati oke oya ni opo yanturu. Awon ni won n seto bi won se n ko Maluu, Agbo ati Ewure wole.
  • Eni to mo oju ogun ni pa obi ni ‘Re’. Awon alapata ni won mo ogbon mimu awon eran wonyi ti won ba ja ni oriso, bi a se n pa won ati kikun won.
  • Ise kekere ko ni eran-jije n se ni ago ara. O n fun ara wa lokun, mu ki ounje wu ni je.

AWON OHUN ELO ALAPATA

  • Obe: Obe to mu sarasara ni won fi n pa eran yoowu ti won ba fe pa. obe naa ni won fi n kun un si iwon esipon ti a fe.
  • Ada: Ibi to le ni ara eran ni won n fi ad age. Bi apeere, ese eran, ori ati beebee lo
  • Aake: Ise kan naa ni alapata n fi aake ati ada se. aake wulo lati fi sa egungun ti ada ko ran tabi to le ba enu ada je. Won le fi aake fo ori Maluu, ese tabi eyin re.

ILANA IKOSE: Awon omo alapata maa n koi se yii lati kekere. Bi omo bas i se n dagbe si ni yoo maa mo apadelude ise siwaju sii. Ise yii yoo gba omode ni odun marun-un si mefa ki o to le gba ominira.

  1. ISE ONISOWO (OWO-SISE)

Okan ninu awon ise abinibi aye atijo ni owo-sise. Awon iran Ijesa ni a ko mob ii onisowo aso. Awon ni a n pen i ‘Osomaalo’ ni aye atijo. Awon onisowo ni won n ra, ti won si n ta oja fun awon eniyan. Awon obinrin ni won po ju lo nidii ise-owo.

Ise owo pin si orisiirisii. Alajapa ni a n pe awon ti won n ra tabi ya nnkan oko bii koko, ogede, isu, elubo, gaari, osan ati bee bee lo. Awon miiran n sowo ate. A n pe won ni ‘alate’. Awon miiran si wa ti won je onisowo aladaa-nla, ti won n ta aso-ofi, bata ati bee bee lo. Bee ni eran-osin bii ewure, agbo, maluu, eja, bee ni awon miiran n sowo re. ise owo ni owo lori pupo.

PATAKI ISE ONISOWO

  • Won n je ki oja da arowoto awon onraja ni asiko
  • O n pese ise asela fun ontaja
  • Ko mu pakanleke lowo, bi eniyan ba se karamasiki oja to ni a yoo se ta si.

OHUN ELO ISOWO

  1. Owo-idokowo: Owo ni a fi n pinle owo. “Bi owo bas i ti mo ni oogun un mo”. Bi owo ti a fi bere wow ba se po to nioja eni yoo se tobi si.
  2. Ibi Isowo: Ibi ti a o ti maa se owo se pataki. O le je inu oja, iwaju ile eni tabi ni irona. Ibe gbodo je ojutaye, ti oja wa yoo ti ta.
  3. Ipolowo Oja: ‘Ipolowo oja ni agunmu owo’. Awon onisowo maa n kiri tabi pate oja won ki a le mo ohun ti won n ta, ki aje le bu igba je.

ONA IKOSE: Omo le koi se-owo ni owo obi bi ise abinibi tabi ki o lo ko o bi awose. Won ni ‘Bi a se n kose ni a ko iyara’. Ijafara se pataki nidii ekose owo.

  1. ISE AKOPE

Ise ohunrin ni ise akope. Okan ninu awon ise ti a ba lowo awon baba-nla wa ni. Tokunrin-tobinrin ni won mo riri ise yii. Awon ni won n ko eyin ope ti a fi n se epo-pupa. Ise elege ni.

Ise yii gba suuru ati aya nini. Eniyan to ban i ooyi oju ko le sise akope. Igba miiran wa ti owo palaba akope le segi, ki igba ja, tabi ki ese ye ni ara igi ope tabi ki ejo nla san won ni ori ope. Gbogbo nnkan wonyi lo le fa ki akope jao. Koko bii irin sin i idi igi ope maa n le. Idi niyi ti o fi je wi pe opo eni ti o ba ja lati ori igi ope ki i fi i ye. Eegun eyin tabi ti ibadii le kan, tabi run yegeyege. Idi igi ope naa ni won n sin oku bee si.

PATAKI ISE AKOPE

  • Ipese epo isebe: Epo ni iroju obe. Bi ko si akope, obe efun ni a ba maa je.
  • Ipese Owo ati Apere: Imo ti akope ge lule lati ori igi open i a fi n fa owo ti a tun n fi ifon re hun apere. Bi owo ko si bi akitan ni ilr ati ayika i ba da. Bi agbon ko bas i ni ahere, owo ni a ba fi ko isu wale.

AWON OHUN ELO AKOPE

  1. Igba: Igba ni okun agba ti won lo pot i akope fi n gun igi ope. Igba yii maa n gbopon, bee ni a maar o.
  2. Aake: Aake ni akope n fi i re imo danu, ki o le ri aaye geo di eyin lule.
  3. Ada: Akope le fi ad age imo ori ope, bakan naa ni o le fi sa odi eyin lule.s

EKOSE: Bi o tile je omode le maa fi oju si bi won se n gun ope, o gbodo di gende ki o le da ko ope. O le bere lati ori opekete. Eyi ni ope kekere ti owo lee to eyin ori re ni ile. Won ni “Opekete n dagbe, inu adamo n baje”.https://googleads.g.doubleclick.net/pagead/ads?guci=2.2.0.0.2.2.0.0&client=ca-pub-1661929042807246&output=html&h=280&slotname=9757662299&adk=1412165949&adf=2692962737&pi=t.ma~as.9757662299&w=700&fwrn=4&fwrnh=100&lmt=1604148193&rafmt=1&psa=1&format=700×280&url=http%3A%2F%2Fstoplearn.com%2Fcourses%2Fsecondary-school%2Fss2-first-term-yoruba-language-senior-secondary-school%2Flessons%2Fise-ajorin%2F&flash=0&fwr=0&fwrattr=true&rpe=1&resp_fmts=3&wgl=1&tt_state=W3siaXNzdWVyT3JpZ2luIjoiaHR0cHM6Ly9hZHNlcnZpY2UuZ29vZ2xlLmNvbSIsInN0YXRlIjowfSx7Imlzc3Vlck9yaWdpbiI6Imh0dHBzOi8vYXR0ZXN0YXRpb24uYW5kcm9pZC5jb20iLCJzdGF0ZSI6MH1d&dt=1604148193299&bpp=7&bdt=149&idt=70&shv=r20201029&cbv=r20190131&ptt=9&saldr=aa&abxe=1&cookie=ID%3D3b5c0a4b352ccd7b-2255262b41a60032%3AT%3D1602230088%3ART%3D1602230088%3AS%3DALNI_MaWUG7yiaaHthyGgrREyU5I0uWdRw&correlator=8121770997029&frm=20&pv=2&ga_vid=629648942.1604148193&ga_sid=1604148193&ga_hid=1771074033&ga_fc=0&iag=0&icsg=12527009791&dssz=56&mdo=0&mso=0&u_tz=60&u_his=37&u_java=0&u_h=768&u_w=1366&u_ah=728&u_aw=1366&u_cd=24&u_nplug=3&u_nmime=4&adx=609&ady=2348&biw=1518&bih=730&scr_x=0&scr_y=0&eid=42530672%2C44730557&oid=3&pvsid=133986667561554&pem=804&ref=http%3A%2F%2Fstoplearn.com%2Fcourses%2Fsecondary-school%2Fss2-first-term-yoruba-language-senior-secondary-school%2Flessons%2Fatunyewo-ihun-oro%2F&rx=0&eae=0&fc=640&brdim=0%2C0%2C0%2C0%2C1366%2C0%2C1366%2C728%2C1517%2C730&vis=1&rsz=%7C%7CfeEbr%7C&abl=CF&pfx=0&fu=8320&bc=31&ifi=1&uci=a!1&btvi=1&fsb=1&xpc=fVqDWNtdW2&p=https%3A//stoplearn.com&dtd=97

  1. ISE GBENAGBENA

Ise gbenagbena je okan pataki ninu ise ti a ba lowo awon baba-nla wa. Awon okunrin ni won n sise yii. Ise yii je ise ti toba-tijoye n karamasiki re. awon ni won n gbe igi opo-ile, ilekun, apoti ijokoo Oba. Won le fi igi gbe Ekun, Ologbo, Odidere, Erin ati orisirisii ere, apeere awonti a n ba pade ni aafin Oba tabi ilea won olola ati awon ijoye. Awon ni won n gbe opon-ayo, opon-ijeun, orisii ere fun ilo awon ara ilu ati awon ti a n ri ni iyara ikohun-isebaye-si bi eyi ti o wa ni Ile-Ife ati Binni. Gbenagbena naa ni won n se eeku ada, igi oko, igi aake ati bee bee lo fun ilo awon agbe. Owo tabuu ni won n pa.

PATAKI ISE GBENAGBENA

  • Ko je ki asa wa lo si okun igbagbe
  • O je ona ipawo wole si apo gbenegbena
  • O je ona ipawo wole fun Ijoba, ti wo ba fi awon ere wonyii sowo si oke okun
  • O pese ise fun awon odo

AWON OHUN ELO WON:

  1. Aake: Aake ni gbenagbena fi n ge igi ti won fi n gbe ere lule, ti won yoo sig e si orisiirisi ike
  2. Ada: Ada ni a n lo dipo aake lati ge igi ti a fe lo si ike-ike. Ohun naa ni a fi n bere ere gbigbe
  3. Obe: Ti ise ba de ibi elege bii ki a fe se oju, imu, eti, enu, oyan-aya, obe ni a n lo. Oun ni won fi n gbe ara nnkan, ki o le dan daadaa. Bi won se ni obe nla ni wo ni kekere ti won fi n dan ara ere tabi opa itile.
  4. Osese: Oseseni a fi n da iho sinu igi ti a fe fi gbe ere tabi ara nnkan miiran ti a fe gbe

Orisii Igi ti won n lo

  1. Igi Iroko tabi Oganwo: Igi wonyi le pupo. Awon ni a fi n gbe odo, opa itile.
  2. Igi Awun: Igi yii ko le koko bii igi iroko tabi oganwo. Oun ni a fi n gbe ere, opon-ayo.

ILANA IKOSE: Awon ti won ba je omo gbenagbena le bere lati kekere. Won yoo si lo to odun mewaa ki won to mo ise naa dunju. Awon ti won wa ko ise yii bi awose yoo lo bii odun marun-un si mefa ki o to gba ominira.

Ni ile Yoruba, ni ojo igbominira, ti o ba je ise awose, oga yoo fi oti ibile tabi oyinbo gba adura fun omo ekose. Awon obi omo-ekose naa yoo gbe ohun jije-mimu kale lati je ki won mu.

ISE AMUTILEWA

  1. So pataki ise isenbaye
  2. So iwulo ise abinibi meta
  3. So orisii ise abinibi meta ki o si daruko ohun elo ise won
  4. So pataki ise agbe marun-un
Exit mobile version