Mofiimu ni ege tabi fonran ti o kere julo ti o si ni ise ti o n se (tabi ihimo kikun) ninu ihunoro. Apeere eya moffimu ni oju, omo, owo, alaafia, eemi, egbon ati, ai, a, i, on. A ko le se atunge awon ege mofiimu oke wonyi mo ti a ba ge e, won yoo so itumo won nu.
Eya Mofiimu
A le pon mofiimu si orisii meji. Awon ni:
- Mofiimu Ipile (adaduro)
- Mofiimu afarahe
MOFIIMU IPILE TABI ADADURO: eyi je ege ti o le da duro lai i ni afikun fonran (afomo) miiran pelu re.
Mofiimu ipile maa n da itumo ni
A ko le fo mofiimu ipile si wewe mo. Mofiimu ipile le je:
1. ORO – ORUKO: oro oruko bayii kii gba afomo mora, bee ni a kole pinwon si meji tabi ki a seda won. Apeere: Adebisi, Igbokoda, Adaye, Omi, Ile, Ori abbl.
2. ORO – AROPO AFARAJORUKO: awa, eyin, awon, emi, iwo.
3. ORO – ISE: lo, gbe, wa, de abbl
4. ORO – APEJUWE: pupa, dudu, funfun
5. ORO APONLE: banku, roboto
A le lo mofiimu afarahen moa won isori (ii – iv) oke lati seda ororuko titun. Bi apeere
ti + eyin ==== teyin
Awon oro – oruko kan wa ti a le se apehinpe won seda oruko tuntun. Bi apeere
Irun + agbon ====== irungbon
Mofiimu Afarahe
Mofiimu afarahe tabi afomo je awon iro (leta) inu ede ti ko le duro bi oro kan lai je pe a kan mofiimu ipile mo won. A le pin mofiimu afarahe sei meji:
1. Afomo afarahe ibere (iwaju) mofiimu ipile ni an fi afomo kun ni ibere lati seda oro-oruko miiran. Afomo ibere le je ……
i. Eyo faweli airanmupe bii: a, e, ȩ, i, o, ǫ, u ki a wa fi kun mofiimu ‘ipile’. Apeere
I + fe
I + gbagbo
A + de
E + to
E + ko
O + sere
Ǫ + muti
ii. Akanpo iro onisilebu meji bii ai, on, oni, ati, sai, abbl. Apeere
ai + sun
on + te
oni + isu
ati + je
sai + gboran
2. Afomo afarahe aarin. Afomo aarin maa n waye ni aarin oro-oruko mofiimu adaduro ti a se apetunpe re. wunren afomo aarin ni; de, ki, je, ku, ni, si, ri, abbl. Apeere
Oro Oruko Afomo aarin Oro Oruko Abajade
Ile ki ile
Iran de iran
Ije ku ije
Emi ri emi
Agba ni agba
Opo ni opo
Ebi si ebi
Read our disclaimer.
AD: Take Free online baptism course: Preachi.com