Aroko je ohun ti aro ti a si se akosile re.
Aroko asapejuwe ni aroko ti a fi n se apejuwe bi eniyan, nnkan tabi ayeye kan se ri gan-an.
Apeere ori oro aroko asapejuwe
- Ile iwe mi
- Oja ilu mi
- Ounje ti mo feran
- Ijamba oko kan ti o sele loju mi
Igbese Aroko Asapejuwe
- Yiyan ori oro
- Sise apejuwe ero le see se sinu iwe ni ipu afo (paragraph) kookan.
Igbelewon :-
- Kin ni aroko
- Fun aroko asapejuwe ni oriki
- Ko igbese kiko aroko asapejuwe
Ise Asetilewa :- ko aroko ti o kun fofo lori ori oro yii “Oja Ilu Mi”
ASA:- Oge SiseI
Oge sise je asa aso wiwo ati itoju ara lati irun ori titi de eekana ese.
Tokunrin tobinrin lo n soge ni ile Yoruba sugbon aarin awon obinrin ni o wopo ju si.
Oge Sise Lorisirisi
- Aso wiwo
- Ila kiko
- Osun kikun
- Laali lile
- Tiroo lile
- Eti lilu
- Itoju irun ori
- Iwe wiwe abbl.
- Ila kiko :- Idi pataki ti awon Yoruba fi n ko ila oju ni aye atijo ni lait da ara won mo ati lati bukun ewa ara.
Orisi Ila Oju
- Abaja :- Eyi ni ila meta tabi merin ti a fa nibuu lori ara won. O wopo ni agbegbe oyo
- Pele :- Eyi ni ila meta ooro ti a fa si ereke. O wopo ni agbegbe ijebu, ekiti, ijesa, ila orangun ati eko
- Baamu :- Eyi ni ila to dabuu ori imu wa si ereke apa osi. Idile oba n i o maa n ko ila yii ni ilu ogbomoso
- Yagba :- Eyi ni ila meta teere ti o pa enu po ni eba enu. O je ila awon eya igbonuna ati yagba abbl.
- Osun Kikun :- Eyi da bu atike lebulebu, o pupa foo. Awon obinrin maa n kun si oju, apa, ese, ati ara won ki won le maa dan ni awo. Abiyamo tooto maa n kun osun si ara omo tuntun bee ni iyawo tuntun maa n kun si egbegbe ese re lati bukun ewa re.
- Tiroo Lile :- Eyi maa n bukun ewa oju obinrin ni penpe oju won. Awon okunrin miran naa n kan un lati bukun ewa.
- Laali lile :- Ile tapa ni awon elesin musulumi ti mu wa si ile yoruba
- Irun ori :- Okunrin – (a) ori fifa (b) Ori Gige
Obinrin – (a) Irun kiko (b) irun didi bii, suku, patewo, panumo, kolese, ipako elede, koroba abbl.
- Aso wiwo :- Yoruba gbagbo pe aso ni iyi eniyan. Idi niyi ti won fi n so pe “bi a ti n rin ni aa ko ni”. Orisiri aso asiko.
- Aso Ise :- Oniruru ise ti a n se ni o ni aso ise. Awon agbe a maa wo ewu penpe ti ko ni apa ati sokoto kookun. Ni kukuru, bi ise ba ti ri ni aso ti a fi n se won maa n ri.
- Aso iwole/iyile :- Eyi ni aso ti a nlo ninu ile. Aso iyile awon obinrin ni tabi, tabi yeri ti awon okunrin ni gberi ati sokoto kookun
- As imurode :- Yoruba bo won ni « aso igba ni aa da fun igba ». bi olodumare ba se ke eniyan to ni yoo se da aso po to
- Aso imorode obinrin:- iro, buba, gele, iborun tabi pele, yeri
- Aso imurode okunrin:- dandogo, agbada, sapara, gbariye, dansiki, buba ati jalaabu, sokoto sooro.
Igbelewon:-
- Fun oge sise ni oriki
- Ko ona oge sise marun-un ni ile yoruba
- Salaye ni kukuru
Ise Asetilewa :- ‘Aseju oge, ete ati abunkun ni o n mu dani’ Tu keke oro
LITIRESO :- Kika iwe litireso ti ijoba yan.
Read our disclaimer.
AD: Take Free online baptism course: Preachi.com