Categories
Notes Yoruba Yoruba JSSCE

Eya Gbolohun

Gbolohun Onibo

Eyi ni gbolohun ti a fi gbolohun miiran bo inu re.

Gbolohun onibo pin si;

  1. Gbolohun onibo asaponle
  2. Gbolohun onibo asapejuwe
  3. Gbolohun onibo asodoruko

Gbolohun Onibo asaponle

Eyi ni gbolohun ti a fi n se aponle ninu gbolohun nipa lilo oro atoka “ti” tabi “bi”. Apeere.

  1. Awon ole yoo sa bi awon ode ba fon fere
  2. Ti awon ode ba fon fere awon ole yoo sa.

Akiyesi: A le gbe won funra lai so itumo gbolohun naa nu.

Gbolohun onibo asapejuwe.

Inu apola-Oruko ni gbolohun onibo asapejuwe maa n wa. Oro atoka “ti” ni o n lo.

  1. Ile ti ola n gbe dara
  2. Tunde ra aso ti o ni awo ewe.
  3. Oko ti oluko ra rewa

Gbolohun onibo asodoruko

Atoka gbolohun onibo asodoruko ni “pe”. Atoka yii maa n yipada di oro oruko ninu gbolohun. Apeere;

  1. O dara pe o ri se si ile epo
  2. Pe  o le jale o dun mi pupo.

EKA ISE:                ASA

AKOLE ISE:          ASA IGBEYAWO NI ILE YORUBA – IGBEYAWO ODE -ONI

Ni aye ode –oni omokunrin ati omobinrin ni o n ri ara won ba soro laisi alarina tabi ifojusode obi.

A le pin igbeyawo ode-oni si ona meta. Awon ni yi;

  1. Igbeyawo soosi
  2. Igbeyawo Mosalasi/yigi siso
  3. Igbeyawo Kootu

IGBEYAWO SOOSI

Eyi ni igbeyawo laaarin omokunrin ati omobinrin ninu soosi. Igbeyawo yii wopo laarin elesin kiristi. Alufaa ijo ni o maa n so okunrin ati obinrin po pelu eleri lati inu ebi mejeeji. Ko si aaya fun ikosile tabi ki okunrin ni ju aya kan lo ni igbeyawo soosi.

Eto Igbeyawo Soosi.

  1. Baba iyawo ni yoo mu iyawo wo inu soosi
  2. Alufaa yoo gba tokotaya ni imoran bi won se le gbe igbe aye alaafia ninu Jesu.
  3. Ikede: Alufaa yoo bere lowo ijo boya a ri enikan ti o ni idi kan ti ko fi ye ki a so took taya po ki o wi tabi ki a pa enu mo titi Jesu yoo fi de.
  4. Alufaa yoo so pe ki tokotaya wa si waju, lati so won po pelu eje pe iku nikan ni yoo ya won.
  5. Alufaa yoo fun won ni oruka gege bi edidi igbeyawo.
  6. Alufaa yoo fi won han gbogbo ijo gege bi oko ati aya.
  7. Ifowo si iwe: Oko, Iyawo ati awon obi won yoo fi owo si eri igbeyawo pelu ijo ati ayo.
  8. Leyin eyi ni gbogbo ijo yoo lo si yara igbalejo fun jije, mimu, bibu akara oyinbo, ijo, gbigba ebun abbl.

IGBEYAWO MOSALASI/YIGI SISO

Eyi ni igbeyawo laarin okunrin ati obinrin ti o waye ni mosalasi,tabi ibudo miiran ti oko ati aya ba fe.

Eto Igbeyawo Mosalasi

  1. Adura Ibeere
  2. Aafaa yoo bere lowo obi oko ati aya boya won gba lati je ki awon omo won fe ara won.
  3. Aafaa yoo kewi bee ni yoo gba oko ati iyawo ni imoran lati gbe aye alaafia gege bi loko laya.
  4. Awon obi mejeeji yoo sadura fun awon omo won pelu owo adura lowo
  5. Aafaa yoo fi oruka si oko ati iyawo lowo pe gege  bi edidi ife won
  6. Bakan naa, Aafaa yoo se ifilo pe aaye wa fun oko lati fe iyawo miiran le iyawo to fe ati pe won le fi ara won sile ti won ba ri pe ko si ife mo laarin won.

IGBEYAWO KOOTU

Eyi ni igbeyawo ti okunrin ati obinrin yoo lo si kootu ijoba lati so ara won po pelu ofin.   A tun le pee ni igbe yawo Alarede.

ETO IGBEYAWO KOOTU

  1. Okunrin ati obinrin yoo koko lo fi oruko sile lodo akowe kootu
  2. Leyin naa ni won a gbe ohun jije, ati mimu bii, bisikiti, eso, oti elerin didun abbl. Lo si kootu.
  3. Adajo ile ejo, yoo kede boya ariwisi wa si isopo awon mejeeji
  4. Ni ojo igbeyawo, oko iyawo ati awon asoju won yoo lo si ile ejo lati bura gege bi esin won
  5. Oko, iyawo, awon obi, asoju ati awon eleri meji yoo fi owo si iwe eri igbeyawo.
  6. Ba kan naa, oko ati iyawo yoo fi oruka si ara won lowo.
  7. Leyin eyi, akowe kootu yoo se ifilo pe oko ko le fe iyawo miiran lai se pe o jawe ikosile fun iyawo re ni ilana  ofin.

EKA ISE:                LITIRESO

AKOLE ISE:          Kika Iwe Apileko Oloro Geere Ti Ijoba Yan

Igbelewon :

  • Kin ni gbolohun onibo?
  • Ko isori gbolohun onibo
  • Salaye asa igbeyawo ode-oni lekun-un-rere

Ise asetilewa: Gege bi esin re, salaye ilana igbeyawo ode-oni

Read our disclaimer.

AD: Take Free online baptism course: Preachi.com

Discover more from StopLearn

Subscribe now to keep reading and get access to the full archive.

Continue reading

Exit mobile version