Categories
Yoruba

ITESIWAJU LORI EKO IRO EDE YORUBA

EKA ISE: EDE

AKOLE ISE: ITESIWAJU LORI EKO IRO EDE YORUBA

Apejuwe iro faweli

A le sapejuwe iro faweli ni ona merin wonyi;

  1. Ipo ti afase wa
  2. Apa kan ara ahon to gbe soke ju lo ninu enu
  3. Bi apa to ga soke naa se ga to ninu enu
  4. Ipo ti ete wa
  5. Ipo ti afase wa: Afase le gbera soke di ona si imu la.

Iro faweli airanmupe ni a pe nigba ti afase gbe soke – a e e I o o u

Iro faweli aranmupe ni a pe nigba ti afase wa sile – an en in on un

  • Ipo ahon: ti a ba pe faweli, apa kan ara ahon maa n gba soke ti yoo su ike mu eny. Bi apa
  • Bi apa to ga soke naa se to ninu enu: Eyi ni iwon bi ahon se ga to ninu enu
  • Ipo ete: Ipo meji ni ete maa n we ti a ba n pe iro faweli.

Ete le ri perese: Ti ete bari perese awon faweli ti a n pe jade ni, a e e I an en in

Ete le ri roboto: Ti ete ba ri roboto awon iro faweli ti a n pe jade ni, o, u, o, un, on

Apejuwe iro faweli airanmupe

  1. Faweli airanmupe ayanupe (odo), aarin, perese

e-    Faweli airanmupe ahanu diepe (ebake) iwaju, perese

e-    Faweli airanmupe ayanu diepe (ebado) iwaju, perese

  1. Faweli airanmupe hanupe (oke) iwaju, perese

o-    Faweli airanmupe ahanu diepe (ebake) eyin roboto

o-    Faweli airanmupe ayanu diepe (ebado) eyin roboto

u-    Faweli airanmupe ahanupe (oke) eyin roboto

Apejuwe iro faweli aranmupe

An- Faweli aranmupe ayanupe (odo) aarin perese

En- Faweli aranmupe ayanu diepe (ebado) iwaju perese

In-  Faweli aranmupe ahanupe (oke) iwaju perese

On- Faweli aranmupe ayanu diepe (ebado) eyin roboto

Un- Faweli aranmupe ahanupe (oke) eyin roboto

EKA ISE: ASA

AKOLE ISE: OWE

Owe ni afo to kun fun imo ijinle ogbon ati iriir awon agba.

Owe lesin oro, oro lesin owe, bi oro ba sonu owe ni a fi n wa.

Awon agba n lo owe lati yaju oro to takoko.

Orisi owe

Isori marun-un ni a le pin owe Yoruba si. Awon niyi,

  • OWE FUN IBAWI:
  • Bi omode ba n se bi omode, agba a si maa sibi agba.

ITUNMO: Iwa ogbon lo ye ki a ba lowo agba

  • Agba ku wa loja ki ori omo tuntun wo

ITUNMO: Agba je olutona iwa rere fun awon omode ni awujo

  • A n gba oromodie lowo iku, o ni won o je ki oun lo ori aatan lo je

ITUNMO: a n pa owe yii fun eni to ba wa ninu ewu kan  ti a si s fun-un to sin fe se ife inu ara re.

  • OWE FUN IKILO:
  • Aguntan to ba ba aja rin a je igbe

ITUNMO: Ti awon agba ba se akiyesi pe enikan n ba eniyan buburu kan rin, won yoo fi owe kilo fun pe ki o yera ki o ma ba a ti ibe ko iwa buburu.

  • Alaso ala kii ba elepo sore

ITUNMO: Oniwa rere kii ba eniyan buruku rin

  • Ise ni oogun ise

ITUNMO: Eni ba fe segun osi a tepa (mura) mo se

  • OWE FUN IMORAN
  • Agba to ba je ajeeweyin ni yoo ru igba re de ile koko

ITUNMO: Agba to ba hawo ko ni ri omode jise fun oun

  • Igi ganganran ma gun ni loju ati okere ni a ti n yee

ITUNMO: Ohun ti o le se akoba fun eniyan ko gbodo ja fara lori re

  • Bi ara ile eni ba n je kokoro arinya, bi a ko ba so fun un, here-huru re ko ni je ki a sun loru

ITUNMO: Bi ara ile eni ba n huwa ibaje ti a ko ba so fun un, nigba ti wahala tabi ijiya re ba de yio ta ba ni

  • OWE FUN ALAYE
  • A ni ka je ekuru ko tan ni abo, n se ni a tun n gbon owo re sinu awo tan- n- ganran

ITUNMO:  awon agba maa n pa owe yii bi wahala tabi ede aiyede kan ba sele ti won si n gbiyanju lati yanju re, ti won tun wa se akiyesi pe awon kan fe hu u sita ( awon kan ko fe ki o tan )

  • Agba to n sare ninu oja ni, bi nnkan o le, a je pe o n le nnkan

ITUNMO: Eni to n sise karakara mo idi ti oun fi n se loju mejeeji

  • OWE FUN ISIRI
  • Bi ori ba pe nile yoo dire

ITUNMO: Bi iya ba n je eniyan de ibi lo pe o fe bohun, won a maa pa owe yii lati fun un ni isiri pe ojo ola yoo dara

  • Pipe ni yoo pe, akololo yoo pe baba

ITUNMO: Ko si ipenija ti eniyan le maa la koja, o le dabi eni pe ko sona abayo sugbon ni ikeyin ireti wa.

IWULO OWE

  1. Owe maa n je ki a fi ododo oro gun eniyan lara lai ni binu
  2. Awon agba n lo owe  lati so oro to ba wuwo lati so
  3. Owe n gbe ogo ede yo
  4. A n lo owe lati fi ba ni wi fun iwa ti ko dara
  5. A n lo owe lati kilo iwa ibaje
  6. A n lo owe lati fi gbani ni yaju
  7. Awon agba n lo owe lati fi yaju oro to ta koko.

EKA ISE: LITIRESO

AKoLE ISE: EKO LORI IGBADUN TI O WA NINU LITIRESO ALOHUN

Ere – onise –  ese/iwi egungun , ijala

  1. Oriki itan isedele tabi eyi to n so idi abajo litireso atenudenu Yoruba ni eyi, awon ohun ti o n suyo nibe ni oriki itan isedale ati awon asa ajogunba Yoruba.
  2. Kiki ati kike je okan lara igbadun litireso atenudenu. Awon itan isedala ti a maa n ba pade ninu litireso atenudenu maa ran ni leti orirun ibi ti awon eniyan kan ti se, ti o si n je ki a ni ife sii daadaa.
  3. Ba kan naa, awon itan idi abajo , bi ori igun se pa, idi ti oju orun fi jinna si ile , idi ti a fi n bo oku mole abbl ni a maa n ba pade ninu litireso atenudenu.
  4. Eko ati ogbon: onirunru eko ni a maa n ba pade ninu litireso atenudenu , o maa n fi oye awon ohun ti o ye  ki a maa se ati eyi ti ko ye ki a hu niwa han ni.
  5. Ikorajopo, idaraya, ipanilerin ati tita-opolo ji po jatirere ninu litireso atenudenu lati gbe asa Yoruba laruge.

Igbelewon:

  • Sapejuwe iro faweeli ni ona merin
  • Fun owe ni oriki
  • Salaye orisi owe pelu apeere
  • Ko igbadun ti o wa ninu litireso alohun ere onise

Ise asetilewa:    1. salaye awon owe wonyi  gege bi o ti ye o si pelu apeere irufe owe bee meji meji

  1. owe imoran
  2. Owe ibawi
  3. Owe ikilo

Read our disclaimer.

AD: Take Free online baptism course: Preachi.com

Discover more from StopLearn

Subscribe now to keep reading and get access to the full archive.

Continue reading

Exit mobile version