Categories
Notes Yoruba

Ori Oro: Aroko Asarinyanjiyan

Aroko asarinyanjiyan ni aroko eyi wun mi ko wun o
Abuda aroko asariyanjiyan
• Iha meji ni aroko yii maa n ni,iha mejeeji yii ni a si gbodo ye wo finni-finni
• Iha ti a fara mo ni a o soro le lori ni ikadi aroko lekun rere lati fi aridaju han pe loooto ni a fara mo apa kan ninu ori oro aroko naa.
Apeere aroko asariyanjiyan:
OMO DARA JU OWO LO
 Ohun akoko ni ifaara
 Sisoro lori iha mejeeji : (a) omo – anfaani omo ati aleebu
(b)Owo – anfaani ati aleebu
 Ikadi aroko – eyi ni fifi ara mo iha kan ti o wun ni ninu ori oro.
Kiko aroko naa lekun-un rere
OMO DARA JU OWO LO
‘Omo niyi
Omo leye………………..
Bee ni;
‘Owo ni ti oun ko ba si nile,
Ki enikeni ma dabaa kankan leyin oun’
Awon ipede yii fi ipo omo ati owo han ni awujo awa eda. Bi o tile je pe ko se maa ni ni awon mejeeji sibe a ko le sai mop e iha kan se koko ju ekeji lo
Ohun idunnu ati ayo ni omo je. Idi niyi ti alaboyun bar u u re, ti o si so layo, ohun Ayo nla lo je fun ebi ati ara. Won a si mule poti, won a fi ona roka ni ojo ikomojade.
Bee ni aro ni omo je. Oun ni yoo gbeyin obi ni ojo ola. Yoruba Gbagbo pe obi ti ko ba fi omo saye, o wa ile aye asn nitori pe, omo eni lo n gbe ni de ibi giga, oun si ni aso eni.
Ni idakeji, wahala obi ko kere lori omo, lati kekere ni awon obi yoo ti maa nawo nara lori omo sugbo aimoye omo ni kii roju raye toju awon obi won lojo ogbo. Awon omo miiran a si darapomo egbe – kegbe ti won a si tibe ba oruko ebi won je.
Idi niyi ti awon omoran Kan fi so pe “owo dara ju omo lo” nitori ki ni anfaani omo lai si owo? Anfaani owo ko kere rara. Ko si ohun ti eniyan fe se ti ko nilo owo.
Owo a maa gbe eniyan ga ni awujo, owo a maa fun eniyan ni aponle nibi gbogbo. Koda, bi oro kan ba kan olowo ninu ebi, won a ni ki o de ki won to bere ipade.
Sugbon kii dara ko ma ku si ibi kan. Owo a maa fa igberaga ni ipo agba. Yoruba bo won ni “igberaga ni I saaju iparun” bakan naa, ife owo le mu ki eniyan padanu ijoba orun nitori pe opo olowo ni ki I raye sin olorun bo ti to ati bi o ti ye. Oniruuru iwa ibaje bi i; adigunjale, fifi omo soogun owo ati bee bee lo ni awon enyan Gbagbo pe o kun owo awon olowo nitori ife owo aniju
Ni okodoro, owo ki i to olowo.ti a ba si fi oju inu inu wo o daadaa,a o o ri I pe oto lowo,oto lomo. Ojo ti olowo ba ku ni owo re ku, ojo ti olowo ba ku ni ola re wooku, gbogbo ohun ini olowo ti ko bi omo a di teni eleni. Awon agba bo won ni “ina ku o fi eeru boju, ogede ku o fi omo re ropo”.
Idi niyi ti mo fi fara mo o wi pe omo dara ju owo lo.
Igbelewon:

  1. Fun aroko asariyanjiyan loriki
  2. Ko abuda aroko asariyanjiyan meji
  3. Ko apeere ori oro aroko asariyanjiyan meta
    Ise asetilewa:
    Ko aroko lori “Ise owo dara ju eto eko lo” OSE KESAN-AN EKA ISE : ASA
    ORI ORO : ASA ISINKU NI ILE YORUBA
    Isinku ni eye ikeyin ti a se fun oku logan ti o ku titi di akoko ti a fi sin in
    Yoruba gbagbo pe “eni sinku lo pale oku mo, eni sunkun ariwo lasan lo pa”
    Igbese isinku ni ile Yoruba
    (1) Itufo : eyi ni kikede iku oloogbe fun awon ebi ,ana ati gbogbo eniyan. Ilu liu, ariwo, ekun sisun, ibon yinyin ni a fi n tufo oku.
    (2) Ile oku gbigbe : awon ana tabi omo okunrin ile oku ni yoo gbe ile iwon ese mefa lati sin oku
    (3) Oku wiwe : won ni lati fa irun ori oku ti o ba je okunrin, won a si di irun ori oku ti o ba je obinrin. Gbogbo eekanna owo ati ese oku ni won yoo ge leyin naa ni won yoo fi ose ati kanin-kain pelu omi to loworo we e. leyin eyi ni won yoo wo aso to dara fun oku.
    (4) Oku tite : inu yara tabi odede ti won se losoo ni won n te oku si ni ori ibusun pelu aso funfun ati lofinda olooorun bee ni won yoo fi owu di iho imu ati eti re mejeeji. Ni asiko yii, awon obinrin ile yoo maa ki I ni mesa-an mewaa.
    (5) Alejo sise : Awon omo ati ebi oku yoo peae jije ati mimu fun awon okunrin ile, awon ana ti o gbele oku ati gbogbo alejo patapata.
    (6) Isinku : eyi ni ayeye “fifi erupe fun erupe”. Won yoo gbe oku sinu posi pelu oniruuru nnkan bii; owo, ounje,ileke,aso,bata, opa itile ati nnkan meremere miiran lati lo ni iri ajo naa nitori Yoruba Gbagbo pe iye wa leyin iku ati pe irin ajo ni oku n rin lo si orun. Ni geere ti won ba ti gbe oku sinu koto, awon omo oloku ati ebi re yoo bu eeru si oku naa lara.
    Igbelewon:
  4. Kin ni asa isinku?
  5. Ko igbese asa isinku mefa pelu alaye kikun
    Ise asetilewa:
    Salaye bi a se n se isinku ni ilana esin re.

EKA ISE: ASA
ORI ORO: ASA ISINKU NI ILE YORUBA – OKU ABAMI
Awon iku ti o ba ni leru ti o si buru ju ni iku abami ni ile Yoruba.
Iku yii buru to bee gee to fi je pe Yoruba ki I sokun won, ibaa je oku omode tabi ti agbalagba nitori pe ohun ti o sele ti koja ekun.
Oniruuru oku abami
 Oku oba
 Oku alaboyun
 Oku abuke
 Oku adete
 Oku aro
 Oku afin
 Oku eni to ku si odo
 Oku eni ti igi ya lu
 Oku eni ti sango pa
 Oku eni ti o pokunso
• Oku oba : bi oba ba ku ohun ti a naa n so nip e “ oba waja “ tabi “ ile baje” . ilu gbedu, koso ati fere eyin erin ni a fi n tufo oku oba ni afemojumo laafin. Awon olorisa ati ogboni yoo sim aa se oniruuru etutu ni afin oba,opolopo nnkan oro ni won yoo gba lowo Daodu oba. Akoko etutu yii ni as gbo pewon yoo yo okan oba, ti won a si yan an gbe de oba miiran ti yoo joba,ni gba ti won ba si n se etutu oba tunun,won yoo fun un ni okan oba to awja,won a si bi I lere pe ki lo n je,yoo dahun pe “oun n joba”. Abobaku Alaafin yoo ma jo kiri ile ati ilu pe oun ti setan lati ba oluwa oun ku. Ki I se oun nikan , opo eru, Aayo oba, opo ayaba ati Aremo oba ni yoo maa jo kaakiri ilu pelu lati fi iyanda won han gbogbo ilu lati ku pelu oba. Leyin eyi ni inawo oku fun ogberi yoo bere.
• Oku alaboyun: eyi ni oku ti o buru ju lo.Yoruba a ni eni ti o ku yi I’subu lu owo’ tabi o lo ni ‘ilokulo’. Gbara rti o ba ti ku enikeni ko gbodo wo inu ile naa mo titi ti awon oloro yoo fi de. Ko si ohun tie nu nje ti awon oloro ko ni gba lowo oko ati ebi oloku naa. Eyi le mu ki oko sa kuro ninu ilu patapata nitori pe inawo kekere ko ni isinku naa. Awon aworo yoo gba gbogbo ohun ini oku patapata lai ku abere , awon oloro yii pelu yoo se isinku oku yii pelu omo inu re lotooto. Won yoo sim aa kede kiri ilu pe enikeni ti o ba je oku lowo tabi ohunkohun ki o da pada ki won to sin in bi oun naa ko ba fe ku iru iku bayii. Igbo oro ni won maa n sin irufe oku bee si ni ile Yoruba.
• Oku abuke : Yoruba Gbagbo pe o wu Orunmila (Obatala) lati moa buke bee ati pe ‘eni orisa’ ni won maa n pe won.igale awon olrisa ni a maa n sin iru oku bee si i. opolopo ohun etutu ni awon olorisa yoo si gba lowo awon ebi oku naa.
• Oku afin : abore ti o ba fe se etutu fun oku afin ko gbodo je iyo, ko gbodo sun mo obinrin, ko si gbodo so fun eni Kankan titi etutu naa yoo fi pari
Igbelewon:

  1. Fun oku abami loriki
  2. Ko oniruuru oku abami meje
  3. Salaye meji pere ninu awon oku abami wonyi
    Ise asetilewa:
    Sango je okan lara awon orisa ile Yoruba ti o si ni I se pelu ara ati ina.kin ni awon ohun ti o le fa ti sango fi le pa eniyan kan ni ile Yoruba?
Exit mobile version