Categories
Notes Yoruba

Ori Oro : Itupale Gbolohun Onipon – On – Na

Pon- on – na ni ki oro tabi ifo ni ju itumo kan lo.
Pupo awon oro tabi apola inu ede Yoruba ni o ni ju itumo kan lo. Awon oro wonyi le je oro orukooro ise tabi akanlo ede. Apeere;

Oro oruko onipon –na

• Tinu : Tinu niyi
Itumo: o le je;
(a)oruko eniyan
( b)nnkan ti o wa ni inu bii; ifun,eje, omi, abbl
• Odi : mo ri odi kan ni ana
Itumo : o le je ;
(a) Eniyan ti ko le soro
(b) Ogiri ti a mo yi ilu ka
(d)odidi paadi eyin
• Ayo : ayo ko si nibe mo
Itumo 😮 le je ;
(a)Oruko eniyan, pe ko si nibe mo
(b)Idunnu, eyi tunmo sip e ko si ayo tabi idunnu ninu ile naa
Oro ise onipon – na
• Pa : awa ko ni pa atewo
Itumo : (a) Awa ko ni pa owo si orin naa
(b) Awa ko ni pa eni ti n je Atewo
• Ta : won ta aso
Itumo : (a) ki a na aso sa si ori okun
(b) ki eniyan gbe aso fun eniyan kan ki o si gba owo re

• Gun : o ti gun
Itumo: o le je;
(a) Pe nnkann ti gun pe ko kuru tabi kere mo
(b) Ki ewure tabi eranko miiran sese ni oyun

AKANLO EDE ONI-PON-NA
Akanlo Ede le ni ju itumo kan lo, itumo bee le je itumo ijinle tabi gberefu (lerefe). Apeere;
• Oba waja
Itumo: (a) oba ilu ku
( b) oba ilu wo inu orile ile
• Eru agba ni
Itumo: (a) isoro to je pe agbalagba ni o le yanju re
( b ) Eru ti omode ko le da ru si ori
• Anike ti wo ileya
Itumo : (a) O ti dagba
(b) O ti wo inu ileya
(d) O ti to pa eran odun ileya
(e) O ti to loko

GBOLOHUN ONIPON-ON-NA
Awon gbolohun miiran ni ju itumo kan lo ti a ba pe won. Apeere;
• Iya aje naa ti de
Itumo: (a) iya ti o bi iya aje ti de
(b) Iya ti o je aje gan – an lo de
• Omo Akin
Itumo : (a) omo ti Akin bi
(b) Akinkanju omo
(d)omo ise Akin
• Ayo wun mi
Itumo : (a) mo feran eni to n je Ayo
(b)mo fe ni ayo tabi idunnu
Igbelewon :

  1. Fun pon-on-na ni oriki
  2. Ko apeere meji meji lori
    a. Oro ise oni-pon-on-na
    b. Akanlo ede oni-pon-on-na
    d.Gbolohun oni-pon-on-na
    Ise asetilewa:
    Se ise sise lori akole ise yii niinu iwe ilewo Yoruba Akayege.ibeere kin- in -ni de ikarun –un (1-5)

EKA ISE: ASA
ORI ORO: ONA TI A N GBA FI SAN GBESE

 Ifibiya : Eyi je ona ti a n gba fi gba gbeselowo onigbese to ko lati san owo pada ni worowo.olowo yoo mu suuru patapata,yoo si dabi eni pe o ti gbagbe owo naa sowo onigbese sugbon yoo maa so onigbese kaakiri gbogbo ibi ti o ba ti n taja,bi olowo bam o ibe,yoo ra oja ti o kaju iye owo ti onigbese je e, yoo si yise pada. Bi onigbese ba pe olowo yii pad ape ko I ti I san owo oja,olowo yoo wa so fun un pe ki o fi owo to je oun di owo oja re.
 Emu : eyi je ona ti a n gba gbese ti o bap o die. Olowo yoo lo be awon elemu –un (agbowo ipa) lati ba oun gba gbese lowo onigbese. Awon elemu yoo lo fi ipa gba ohun ini onigbese fun olowo titi onigbese yoo fi ri owo ti o je san. Bi onigbese ko ba tete wa owo naa san fun olowo, olowo yoo ta nnkan ini onigbese bee yoo si fi di owo re. Eyi ti o ba si ku lara owo bee ni olowo yoo fun awon elemu –un gege bi owo ise won.
 Ologo : Eni ti o ya ni lowo yoo ran ologo lo si ile onigbese lati lo gba owo naa ni tipatipa. Awon abirun tabi alarun bi I; adete,ati awon ti o ni egbo nla yanmokan lara ni o saba maa n se ise ologo. Bakan naa, awon tie nu won mu berebere,ti o mo eniyan bu daadaa,ti o si le fi ajigbese se esin laaarin awujo naa maa n se ise ologo. Ni aye atijo nigba ti wahala olgo bas u awon ara ile onigbese, won le da owo naa jo lati san gbese naa. Lara owo ti ologo ba gba fun olowo ni yoo ti yo tire gege bi oya ise re.
 Eda ogboni : opa ogboni ni edan. A kii dede fi edan yii ranse eni ti kii se omo egbe ogboni ti ko ba ni idi Pataki gege bi I igba ti a ba fe lo o lati fi gba gbese. Gbese ti o bap o pupo ni a maa n lo edan ogboni lati gba. Ako edan ogboni ni a n gbe lo si ile onigbese, enu ona abawole ni won maa n ri I mo. Eni ti a je ni gbese ni yoo lo baa won ogboni ninu ilu pe ki won ba oun gba gbese ti enikan je oun. Ti onigbese ati awon ara ile re ba ko lati san gbese naa ni kia kia, awon ogboni yoo gbe eniyan kan lara awon omo agbo ile re ta gege bi eru lati fi san owo ti ajigbese je.

Bi onigbese ba si ku lai san gbese ti o je, won ki I sin iru oku bee bi oku eniyan gidi, won yoo gbe oku re ko igi nla,ibe ni yoo ra si ti awon eye igun yoo fi je eran ara re tan. Gbese jije lai san ki I se iwa omoluabi raras, bi o ti le je pe ko si eni ti oda owo ki I da, sibe dandan ni fun eni ti o bay a owo ki o da a pada gege bi I adehun nitori ojo miiran. Lode – oni, a n ya owo ni ile ifowo – pamo – si , egbe ajeseku ati lowo ore gbogbo.
Igbelewon:

  1. Ko ona merin ti a n gba san gbese laye atijo
  2. Salaye awon ona wonyi ni kikun
    Ise aetilewa:
    Lode oni, salaye ona meji pere ti a le fi gba gbese

EKA ISE: LITIRESO
ORI ORO: EWI ALOHUN GEGE BI ORISUN AGBARA ATI IMO IJINLE
YORUBA
Ewi alohun ni awon ewi ti a jogun lati enu awon baba nla wa.
O je okan Lara litireso ti awon baba nla wa maa n lo lati iwase.
Agbara ti o ya ni lenu ati imo ijinle n be lowo awon Yoruba, idi niyi ti a fi n pe won lolopolo pipe ati alarojinle eda.
Apeere awon ewi alohun ti o fi idi otito mule pe awon Yoruba je alarojinle ati olopolo pipe niyi;
 OFO
Ofo je oro ti a n so tabi fo jade ti a fi n segbe leyin oogon tabi ti a n pe lati mu ero okan wa se.
Apeere ofo awure;
“Itun lo ni ke e fohun rere tun mi se
Ifa lo ni kie e fohun rere fa mi
Abeere lo ni ke e fohun rere beere mi
Tigi tope ni I saanu afomo
Omo araye e maa saanu emi lagbaja
Omo lagbaja loni o “
Itumo ofo yii ni pe, nibi ki bi ti o ba n de ki awon eniyan maa fi ohun rere le e lowo
 AYAJO
Omo iya ofo ni ayajo sugbon inu ese ifa ni oun ti maa n je jade. Oro enu lasan ni ko nilo oogun rara.
Apeere ayajo ti a fi n da inu rerun duro;
“ O-dorita-meta pete isale
O-dorita-meta pero orun oyela
Eyin le yo Olugbon asiri
Ti Oduduwa pa enu re mo
A-ka-woroko-ori-idodo
A-na-le-ori-iwo
Ojo lo de lo mu aganna alaganna gun
Kuro ninu aganna
Ki o wa ibomiiran lo”
 OGEDE
Ohun enu bii ti ayajo ni ogede sugbon ohun enu ti o ni agbara ju ohun enu lo ni. Enikeni ti o ba fe pe ogede gbodo ni ohun ti yoo koko se tabi je gege bii ero ki o to le pe e rara bee ni o gbodo ni ohun ti yoo sare je tabi to la ti o ba tip e e tan ki inira ma ba de ba a. eni ti yoo gbo ogede naa gbodo lo ero tabi ki eni ti yoo pe ogede ti se ohun ti ko ni je ki o se onitoun ba kan.

Igbelewon:

  1. Kin ni ewi alohun?
  2. salaye ewi Yoruba meji ti o fi idi re mule pe Yoruba je alarojinle ati olopolo pipe
    Ise asetilewa: Ni iwoye tire n je awon ewi alohun wonyi si nje bi ti atijo? Salaye ni kikun
Exit mobile version