Categories
Notes Yoruba JSSCE

ORI ORO: AWON IGBESE TI AGBE YOO GBE KI IRE OKO TO JADE

Awon to n fi ise oko riro se ise ati bi a se n toju ohun osin ni a n pen i “Agbe”

Awon igbese naa leseese ni yi:

  • Awon agbe ni lati se itoju oko won loore-koore nipa lilo ero irole,katakataata,iko ebe
  • Won gbodo se amulo oogun ajile(fertilizer)
  • Rira irugbin ti o ba asiko ogbin mu
  • Awon agbe olohun osin gbodo koi le fun ohun osin won
  • Ayika ohun osin gbodo mo toni-toni
  • Ounje amaradan ati amara-dagba lore-koore fun awon ohun osin
  • Ayewo ara ni gbogbo igba fun awon ohun osin

PATAKI /ANFAANI ISE AGBE LAWUJO

  • Awon agbe lo n pese ounje lawujo
  • Ise agbe n pese ise fun ogunlogo eniyan lawujo
  • O n pese ohun elo ise fun awon ile ise gbogbo bii;awon to n se iwe, won ile ise ona igi abbl
  • Ise agbe n pese owo si apo ijoba nitori pupo awon ohun ogbin ni ile yii ni a n fi sowo si oke okun bii; koko

IGBELEWON:

  • Awon won ni Agbe?
  • Ona meloo ni a le pin awon agbe si?
  • So igbese ti agbe ni lati gbe ki ire oko to jade
  • Ko Pataki ise agbe merin ni awujo wa

ISE ASETILEWA:

  • N je loooto nipe awon agbe se Pataki ni awujo? Ko koko marun un lati gbe idahun re lese.
Exit mobile version