Categories
Notes Yoruba

Akole Ise: Ede-Sise Aayan Ogbufo

Ayan ogbufo ni ti tumo ede kan si ede miiran.

Aayan ogbufo ti wa lati odun pipe alufaa Samuel Ajayi Crowther ni eni ti o tumo iwe mimo bibeli ede oyibo si ede yoruba ni odun 1844-1856

Ilana ti tumo Ede

  1. A gbodo ni imo pipe lori ede ti a fe tumo
  2. Ba kan naa, a gbodo ni imo pipe lori ede ti a fe tumo re si

Orisi itumo

  1. Ojulowo itumo : Eyi ni ti tumo oro ni ikookan bi won se wa ninu ede ti a fe tumo si ede keji
  2. Itumo afarajora : Eyi ni ki a mu gbolohun oro inu ede ti a fe tumo ki a lo oro ti o bamu regi ninu ede ti a n tumo re si Ni kukuru, itumo afarajora ni fifi oye ede ti wa gbe itumo kale

Aayan ogbufo eleyo oro

 EDE GEE SI EDE YORUBA
 AudienceOn woran
 CompetitionIdije
 JokeApare
 OverlapWonu ara
 ResearchIwadii
 TransferIsinipo
 MotivateMoriya
 PatternBatani
 StageOri itage
 IdeaOye

Igbelewon: (i) kin ni aayan ogbufo (ii) ko ilana ti tumo ede kan si omiran meji (iii) orisi itumo ede meloo ni o wa? (iv) tunmo awon oro wonyi si ede Yoruba (a) Yes (b) Tale (d) Method

Ise Asetilewa: Tumo awon eyo oro ede geesi wonyi si ede Yoruba (i)Accident (ii)Boundary (iii)Yeletide (iv)Knowledge (v)Lack (vi)Race (vii)Seperation

Asa: Igbeyawo ibile

Asa Yoruba je okan lara awon asa to se pataki ni awujo Yoruba o je ase ti Olodumare fun awa eda lati maa bi si ki a si maa re si.

Yoruba bo won ni “bi omode ba to loko ni a n fun loko” Omokurin ni o maa n gbe iyawo ti a si n fomo obnirin foko ni ile Yoruba

Ilana asa igbeyawo ibile

  1. Eto ifoju sode: ohun akoko ti obi omokunrin to ti balaga yoo se ni fifi oju sode lati wa omobinrin ti o rewa fun omo won okunrin
  2. Alarina: Eyi ni eni ti yoo maa sotun sosin laaarin awon omokunrin ati omobinrin leyin ti a bati se iwadi idile ati iru ebi ti omobinrin naa ti wa
  3. Ijohan/isihun:- Ni geere ti omobinrin ba ti gba lati fe omokunrin ni a n pe ni ijohen.  Owo akoko ti omokunrin n fun omobinrin ni geere ti o ba ti gba lati fe e ni “owo ijohen”
  4. Itoro:-  Awon obi ati ebi omokunrin ni yoo lo si ile awon omobinrin lati lo toro re gege bi iyawo afesona fun omo won.
  5. Idana:-  Oniruuru ohun ti enu nje bii, igo oyin, ogoji isu, obi, orogbo, apo iyo kan, igo oti, aadun, eso loriisirisi aso iro meji, owo idana, abbl. Ni ebi omokunrin naa yoo ko lo si ile obi omobinrin ti won fe fi se aya fun omo won leyin naa won a mu ojo igbeyawo.
  6. Ipalemo:-  Eyi ni sisi eto lori bi ojo igbeyawo yoo se yori si ayo
  7. Igbeyawo :-  Ojo yii gan-an ni eto igbeyawo lekun-un rere sise si so yoo wa nile iyawo ati oko, iyawo yoo maa gba ebun lorisiirisi ati owo.  Ojo yii gan-an ni iyawo yoo fi ayo, orin ati ekun gba adura lodo awon obi re.

Igbelewon :-

  1. Ni kukuru salaye asa igbeyawo
  2. Ko ilena igbeyawo ibile ni sisentele

Ise astilewa :-  Nje loooto ni pe awon ilana asa igbeyawo ibile wonyii si fi ese mule ni ile Yoruba titi di oni ? salaye bi o se ye o si

LITIRESO :-  Kika iwe litireso ti ijoba yan.

Exit mobile version