Categories
Notes Yoruba

AKOOLE ISE:- Ede:- SIse Aayan Ogbufo

Oye oro ti o wa ninu gbolohun ni a n se itumo kii se eyo oro nitori pe ehun gbolohun oro Yoruba yato si ti gbolohun oro geesi

Apeere ese ewi geesi si ede Yoruba;

Time was

When I could hardly sleep

For the noise

They made

All the girls

Had companions

An old woman never lacked

Strong and willing arms

To split her wood.

Ogbufo.

Asiko kan wa to je pe agbara kaka ni mo fi n ri oorun sun nitori pe won n pariwo.  Gbogbo awon omobinrin lo ni alabaarin, iya arugbo gan-an kii se alairi giripe eniyan ti o setan lati baa la igi re.

A o ri i daju pe ninu apeere yii, bi a ba ni ki a tele eto ilana ewi geesi ati itumo awon eyeo oro kookan n I sise-n-tele a ko ni le gbe itumo to ye kooro jade.

Igelewon:-  Tumo ede geesi won yi si ede Yoruba

  1. His body is cold as snow
  2. The room is hooter than fire

Ise asetilewa:-  se ogbufo ede geesi wonyi;

  1. Where are all the gories?
  2. We shall serve no master, king or slave
  3. Deceive yourself not, accept your fate
  4. The room is hotter than fire
  5. His body is cold as snow.

ASA:-  Asa igbeyawo ni ile Yoruba – Igbeyawo Ode Oni

A le pin igbeyawo ode oni si ona meta.  Awon niyi ;

  1. Igbeyawo soosi
  2. Igbeyawo mosalesi/yigi siso
  3. Igbeyawo kootu

IGBEYAWO SOOSI

Igbeyawo yii wopo laarin awon elesin kirisiti.  Alufaa ijo ni o maa n so okunrin ati obinrin po pelu Bibeli ti elerii lati inu ebi mejeeji yoo si fowo si iwe eri.  Inu soosi ni igbeyawo yii ti n waye.  Ko si aaye fun ikosile tabi ki okunrin ni ju aya kan lo ninu igbeyawo soosi.

IGBEYAWO MOSALASI/YIGI SISO

Eyi ni igbeyawo laarin okunrin ati obinrin ni mosalasi tabi ibudo miiran ki oko ati aya ba fe.  Aafaa ni yoo so okunrin ati obinrin po pelu oruka ife gege bii edidi ife.  Aaye wa fun oko lati fe iyawo miiran le iyawo tuntun ati pe won le fi ara won sile ti won ba ri i pe ife ko si ni aarin won mo.

IGBEYAWO KOOTU

Eyi ni isopo laarin okunrin ati obinrin ni kootu ijoba pelu ofin.  A tun le pe e ni igbeyawo alarede.  Adajo ile ejo ni yoo so okunrin ati obinrin po pelu ofin.  Oko ati iyawo ko ni eto lati fi ara won si le laise pe won jawe iko sile fun ara won ni abe ofin.

Igbelewon:-

  1. Ona meloo ni a le pin igbeyawo ode oni si
  2. Salaye igbeyawo ode oni lekun-un rere

Ise Asetilewa : Salaye Pataki alarinna ninu eto igbeyawo ni ile Yoruba

LITIRESO- Kika iwe litireso ti ijoba yan

Exit mobile version