Onka Yoruba je ona ti a n gba lati ka nnkan ni ona ti yoo rorun.
Nonba
1 ookan
2 Eeji
3 eeta
4 eerin
5 aarun-un
6 eefa
7 eeje
8 eejo
9 eesan-an
10 eewaa
20 ogun
30 ogbon
40 ogoji
50 aadota
60 ogota
70 aadorin
80 ogorin
90 aadorun-un
100 ogorun-un
110 aadofa
120 ogofa
130 aadoje
140 ogoje
150 aadojo
160 ogojo
170 aadosan-an
180 ogosan-an
190 aadowa (igba o din mewaa)
200 igba
300 oodunrun
400 irinwo
600 egbeta
800 egberin
1000 egberun
1200 egbefa
1400 egboje
1600 egbejo
1800 egbesan
2000 egbewa (egbaa)
Igbelewa:-
- Fun onka ni ori ki
- Ka onka lati ookan de egbaa
Ise Asetilewa : ko onka Yoruba lati igba de egbaa
ASA:- Asa Igbeyawo
Eto Igbeyawo Soosi
- Baba iyawo yoo mu iyawo wo inu soosi
- Alufaa yoo gba toko-taya ni imoran bi won se le gbe igbe aye alaafia ninu Jesu
- Ikede:- Alufaa yoo bere lowo ijo boya a ri enikeni ti o ni idi kan ti ko fi ye ki a so toko-taya po ki o wi tabi ki o pa enu mo titi Jesu yoo fi de.
- Alufaa yoo sip e tokotaya siwaju lati so won po pelu eje pe iku nikan ni yoo ya won
- Alufa yoo fun won ni oruka gege bi edidi igbeyawo
- Alufaa yoo fi won han gbogbo ijo gege bi oko ati aya
- Ifowo si iwe eri oko ati aya pelu awon ebi mejeeji pelu ijo ati ayo
- Leyin eyi ni gbogbo ijo yoo lo si yara igbalejo fun jije, mimu, bibu akara oyinbo, gbigba ebun igbeyawo lorisirisi pelu ijo ati ayo.
ETO IGBEYAWO MOSALASI/YIGI SISO
- Adura ibeere
- Aafaa yoo bere lowo obi oko ati aya boya won gba lati je ki awon omo won fe ara won
- Aafa yoo kewu bee ni yoo gba oko ati iyawo ni imoran lati gbe igbe aye alaafia gege bi loko laya
- Awon obi mejeeji yoo sadura fun awon omo won pelu owo adura
- Aafa yoo fi oruka so oko ati iyawo po gege bii edidi ife won
- Ba kan naa, aafa yoo se ifilo pe aaye wa fun oko lati fe iyawo miiran le iyawo to fe ati pe won le fi ara won sile ti won ba rii pe ko si ife mo laarin won.
ETO IGBEYAO KOOTU
- Okurin ati obinrin yoo koko lo fi oruko sile lodo akowe kootu
- Leyin eyi ni won a gbe ohun jije ati mimu bii, bisikiti eso lorisiri, oti elerindodo abbl, lo si kootu loju ti won ti da fun won.
- Adajo ile ejo yoo kede boya ariwisi wa si isopo awon mejeeji
- Ni ojo igbeyawo, oko, iyawo ati awon asoju won yoo lo si ile ejo lati bura gege bi esin won
- Oko, iyawo, awon ebi, asoju ati awon eleri meji yoo fi owo si iwe eri igbeyawo
- Ba kan naa, oko ati iywao yoo fi oruka si ara won lowo gege bii edidi ife
- Leyin eyi, akowe kootu yoo se ifilo pe oko ko le fe iyawo miiran laise pe o jawe ikosile fun iyawo re ni abe ofin.
Igbelewon:- ko ilana igbeyawo ode oni ni sise n tele
Ise asetilewa:- nje igbeyawo ibile dara ju igbeyawo ode oni lo bi? Tu keke oro
LITIRESO:- Kika iwe litireso ti ijoba yan.
Read our disclaimer.
AD: Take Free online baptism course: Preachi.com