Categories
Notes Yoruba

ASA:- Asa oyun ninu (Itoju oyun ait omo bibi)

Ipo alailegbe ni awon yoruba fi omo si nitori won gbagbo pe laisi omo, idile ko lee gboro bee si ni itesiwaju ko le si ni awujo.

Awon ohun to le fa airi oyun obinrin

  1. Bi nnkan osu obinri ko ba dara tabi to ba n se segesege
  2. Asilo oogun tabi oyun sisee to ti se akoba fun ile omo
  3. Aisan inu gbigbona
  4. Aisan atosi tabi jerijeri olojo pipe lara oko
  5. Ti obinrin ba ya akiriboto tabi ti oko je akura.

Awon ami pe obinrin ti ni oyin ni wonyi ;

  1. Tuto sere-sere kiri ile
  2. Aya rin-rin tabi ki obinrin maa bi
  3. Ki obinrin maa too gbe ni gbogbo igba
  4. Ki o maa re obinrin lati inu wa.

Oniruru aajo ti won n se fun aboyun

  1. Oyun dide :-  Itoju aboyun bere ni kete ti won ba ti fi yesi pe oyun naa ti duro.  Oko tabi agba obinrin ile yoo mu alaboyun lo sodo anisegun agbebi tabi babalwo, onisegun yii yoo de oyun naa ki o maa ba wale tabi baje titi di akoko ti yoo fi bi omo naa.
  2. Sise orisi aseje fun aboyun :-  Awon aseje yii lo maa n dena aisan bii oyi oju, ori fifo, inu rirun, ooru inu abbl, ti yoo si mu ki omo naa maa dagba ninu ki o si le gbo daradara
  3. Wiwe ati mimu awon agbo igi :-  Eyi yoo fun aboyun ati omo inu re lokun.

Oniruuru Idarulekoo ti aon eleto iilara n se fun awon alaboyun lode-oui

  1. Lilo si ile iwosan fun ayewo to peye
  2. Gbigba abere ajesara lati le daan bo boo mo inu
  3. Jije awon ounje asara lore bu, ewa, eja, era, wara abbl.
  4. Mimu omi daradara
  5. Jije eso ati ewebe
  6. Sise ore idaraya ni asiko ti o wo
  7. Sise imototo ara ati ayika.

Igbelewon:-

  1. Ki ni awon ohun to le fa airi oyun obinrin
  2. Ko awon aimi ti o fihan pe obinrin ti ni oyun merin
  3. Ko oniruru aajo ti won ni se fun aboyun ni ile yoruba meta
  4. Lode oni oniruuru idanilekoo wo ni awo eleto ilara maa n se fun awon aboyun ?

Ise Asetilewa :-  se afiwe itoju oyun ti ibile ati ti ode oni

LITIRESO :-          

Itan oloro geere gege bi orisun itan isedale ati asa Yoruba.

ONA TI ITAN ATENUDENU GBA JE ORISUN ITAN ISEDALE ATI ASA YORUBA

  1. Itan fi ye wa pe omo iya ni ode ondo ati iwoye je.  Oba alaafin Ajuwon ti apele re n je ajaka ni baba won.  A gbo pe ibeji ni awon mejeeji omo oba si ni won.  Laye atijo apeere buruku ni  omo ibeji je ati pe pipa ni a maa n pa won ki won to dagba rara.  Sugbon baba won ko fe pa awon omo yii kia lo wi fun iyawo re ki o gbe won jinna rere si ilu ti won wa o si fun aya re ni opolopo owo, ounje, ohun eso ati erubinrin ati erukunrin.

Ilu ti iyawo ajaka tedo si ni ode ondo.

Itan fi ye wa pe okan ninu awon omo ibeji yii tedo si ode ondo ekeji si tedo si iwoye ni ago iwoye ni ile ijebu.  Akooni ati ode ni awon omo Ajaka.  Oruko oye awon ilu mejeji yii fi ajosepo han pe omo iya ni won oye oba ondo ni « osemawe », oye oba iwoye ni « ebumawe ».

  • Itan miran fi ye wa pe omo omo olofin oba ife ni igba kan ni owa ajaka.  Lara awon omo iya re ni orangun oba ila ati Alara oba ara.  Itan fi ye w ape oba olofin ko le riran daada mo ni gba ti o darugbo.  Ko da oju re mejeeji fo awon onisegun si ti gbin yanju lati woo san sugbon pabo lo jasi.  Omo omo re se ileri lati lo bu omi okun gege bii oogun iwosan fun olofin gege bi onisegun se so, iyalenu lo je pe ni geere ti o lo bu omi ji awon egbon re ti ko gbogbo ogun baba won patapata lai ku kan, okgun ko siri ohun ka pato fun omo omo re ayafi ida ajasegun re.

Omi okun ti owa bu yii ni a fi n pee ni « owa oboku » ba kan naa, ida Ajasegun ti olofin fun un lati maaja kiri ni a fi n pee ni « Ajaka »».  idi ni yi ti a fi n pe e ni « owa obokun Ajaka » titi di oni.  Ile ijeba ni osi fi se ibujoko

Igbelewo :-

  1. So itan isedale ilu ondo ati iwoye
  2. So itan isedale ilu ijesa

Ise Asetilewa:-  Ko aroko lori okan ninu awon akoni wonyi:-

  1. Ogunmola
  2. Sodeke
  3. Afonja

Exit mobile version