Categories
Notes Yoruba

Ori Oro: Ere Idaraya Igbalode

Ere idaraya je ere ti tewe tagba maa n se lati mu ki ara won ji pepe.

Gbogbo ere idaraya abinibi ile Yoruba lo je ere ti a fi n naju, ti o n da ni laraya ti o si n ko ni lekoo.

Awon ti ara won ya, ti ara won pe lo maa n se ere idaraya ni ile Yoruba nitori awon ere wonyii ko si fun abirun tabi alaipe ara rara.

Ni ode – oni, opolopo awon ere idaraya abinibi ni a ti pati si egbe kan ti a ko se mo.awon ere idaraya ti awon oyinbo alawo funfun ko wa si ile wa ni a ti fi dipo awon ere abinibi wonyi ti ko si ye ki o ri bee

Awon ere igbalode ni wonyi:

  1. Draft    –   ere ayo
  2. Football   –  ere afesegba
  3. Wrestling  –  ere ijakadi
  4. Boxing  –  ese kikan
  5. Taekwondo  –   eke mimu
  6. Athletic :
  7. Running – ere sisa
  8. Walking  –  irin rinrin
  9. Jumping –  fifo soke
  10. Throwing –  shotput,discuss, hammer throw, javelin throw- nnkan jiju
  11. Tack and field – ere sisa lori ila

AYIPADA TO DE BA ERE ABINIBI

Nitori awon Yoruba nife si ohun ti o wa lati odo awon alawo funfun ju ohun ti o je ti ile wa lo,opo ti pa awon ere abinibi ile wa ti si apa kan ti won si room ti igbalode. Iwadii fi han pe ko si iyato kan gboogi laaarin ere abinibi ati ti igbalode ti awo oyinbo mu wa si ile wa. Ki adiye to ma je agbado, nnkan Kan ni o ti n je tele ni awon ere igbalode je ni ile wa.

Awon ohun elo ti awon oyinbo n lo ninu ere yii ni o yato si ti abinibi ati ona ti a n gba se e.

Ni kukuru, ere idaraya abinibi ati ere idaraya igblode ni o n koni; logbon, ete, o n muni ronu jinle, o n je ki ara wa da sakasaka, o n mu wa mo nipa oro ati itan atijo, o n je ki a ni ife si omonikeji wa, o n pani lerin, o n je ki a di alagbara ki a si ni aya lati koju isoro.

Igbelewon:

  • Fun ere idaraya loriki
  • Ko awon ere idaraya ode-oni pelu oruko ti a mo won mo ninu ere idaraya abinibi
  • Salaye ayipada ti o de ba ere idaraya abinibi

Ise asetilewa:

  • Ni tire, salaye awon ayipada ti o ro wi pe o de ba ere idaraya abinibi
Exit mobile version