Aranmo ni agbara ti iro kan ni lori iro miiran eyi ti o le f ape ki iro mejeeji yi pada di iru kan naa tabi ki won fi abuda jo ara won lona miiran a le pe aranmo ni agbara ti iro kan ni lori miiran lati so di ni ara re. ki aranmo to le waye, oro meji gbodo fe gbe kegbe. Faweli yoo pari oro akoko faweli yoo si beere oro keji. Bi apeere.
Ku + ile = kuule
F1 F2
Iye ohun tabi silebu oro mejeeji ni o gbodo wa ninu ayo risi (oro aranmo). Apeere yii fihan pe faweli ‘I’ to bere oro keji ni gbogbo abuda faweli ‘u’ eyi si so faweli ‘I’ ati ‘y’.
IPO AFARANMO ATI IRO AGBARANMO
Iro afaranmo: eyi ni oro ti o ni agbara lati yi abudaa iro tabi die lara abuda iro miiran pada si tire.
Iro agbaranmo: iron i o yi pada ti o gba abudu iro miiran. Apeere:
Ile + iwe = ileewe
Ara + ile = araale
Iro faweli apeere oke ti o bere oro keji ninu apeere oke yii ni iro agbaranmo.
ORISII ARANMO
- Aranmo iwaju
- Aranmo eyin
- Aranmo alaiforu
- Aranmo aforo
- Aranmo kikun
- ARANMO IWAJU: Eyi ni igba ti iro faweli ti o pari oro akoko ti o je iru afaranmo ba ran mo nro faweli ti o bere oro keyi ti ale to ka si gege bi iro agbaranmo. Bi apeere:
Iro afaranmo Iro agberanmo Aranmo iwaju
Ara + ile araale
Apo + iyo apooyo
Owo + ise owoose
Etu + ibon etunbon
Ile + iwe ileewe
- ARANMO EYIN: Ni igba ti I n faweli ti o bere oro keyi ba ranmo iro faweli ti o pari oro akole. Apeere:
Iro afaranmo Iro agbaranmo Aranmo eyin
Ara + oko araooko
Ku + ale kaale
Omo + oko omooko
- ARANMO ALAIFORO: Eyi ni igba ti iro afaranmo ati iro agbaranmo ba tele ara won taa ra laije pe iro miiran jeyo laarin won. Bi apeere:
Iya ile ====== iyaale
Agba etu ====== agbeetu
Ara eko ====== areeko
- ARANMO AFORO: Ni igba ti iru miiran ba jeyo laarin iro faweli afaranmo ati iro faweli agbaranmo. Eyi wopo ninu ihun afomo ibere “ori” ati oro-oruko ninu eyi ti faweli ‘o’ ninu ‘oni’ ti maa n gbaranmo lara faweli ti o bere oro oruko konsonanti ‘n’ gbodo di ‘l’.
AKORI EKO: APOLA NINU EDE YORUBA
Apola je okan ninu awon abala ihun gbolohun ede Yoruba. Gbolohun re je eyo oro kan tabi akojopo. Ihun ede Yoruba da bi igba ti a bat i hun eni, a ni idi ti awon oro wonyi jo lona ti yoo fi le e mu itumo ti o gbamuse lowo, atun le fi we, tilo awon ohun elo ikole jo lorisirisi lona ti yoo le fi gbele ti o dara ti o si lewa jade.
Lara awon isori oro ti a to jo lati hun gbolohun ede Yoruba ni.
- Oro – oruko
- Oro aropo – oruko
- Oro – ise
- Oro apejuwe
- Oro aponle
- Oro asopo abbl.
AWON APOLA INU EDE YORUBA
- Apola Oro – oruko (Noun Phrase): Eyi le je oro kan tabi akojopo oro ti a maa n lo gege bi oluwa ati abo ninu gbolohun yala pelu eyan tabi laisi eyan. Ihunapola oruko leje:
- Oro – oruko kan soro pere. Apeere: Ojo ro
- Oro – aropo oruko. Apeere: Mo sun
- Oro – aropo afarajoruko. Apeere: Eyin ni mo ri
- Apola oro – oruko pelu eyan. Apeere:
Okunrin yen ni o mu
Ewure merin ni won pa bo ifa
Bola aburo Kemi ti wolu de
Ounje die niki ose
- Apapo oro – oruko ati awe gbolohun. Apeere:
Oro ti Kemi so dun won
Aso ti a ra ti gbo
- Apola Oro – ise (Verb phrase): Apola oro ise le je eyo oro tabi akojo po awon eye. Oro ti o n so ohun ti oluwa se ninu awe gbolohun ati ninu odidi gbolohun o le je oro –ise ponbele, oro – ise agbabo ati asaaju oro – ise. Oun ni on sise opomulero ninu ihun gbolohun ede Yoruba. Apeere: jokoo, sare, jade, dide abb.
Ta iyan, je efo sese de ijankon, gbinododo
- Apola Aponle (Adverb phrase): Eyi ni oro ti o n se ise epon/eyan fun oro – ise ninu gbolohun ede Yoruba apola aponle maa n fi itumo ti o kun fun oro – ise, inu apola ise ni apola aponle ti maa n jeyo. Fun apeere:
Ori tan yeri yeri
O n rin kemokemo
Aso funfun balau
Ise Asetilewa
Ko apola ede Yoruba ti okookan gbolohun isale ti a fa ila si nidi je.
- Bisi Adepegba lo si oja
- Omo ti a n soro re ti de
- Eran dindin ni mo je lanaa
- Adebayo mu oti yo
- Badejo pa eran oya
- Iginaa ga fiofio
- Soja yan jaujau
- Emi ati eyin ni won pe
- Dokita oyinbo gun abere mefa
AKORI EKO: AWON OHUN ELO IFA DIDA
- IKIN: Orisiirisi ni awon ohun elo ifa dida ti o wa. Awon ti o se pataki julo ninu won ni ikin, opele, ibo, iroke, opon ifa, agere ifa, apo ifa, ilu ifa (orisiirisi) opa orere. Ikin lo se pataki julo ninu awon nnkan wonyi nitori pe oun gan-an ni Orunmila fi ropo araa re leyin igba ti o ti pada lo si ode orun ti ko si wa sile aye mo. Ninu agere ifa tabi awo ifa ni a maa n ko ikin si nibe ni a si ti maa n bo o gege bi oosa.
- OPELE: Nnkan meji pataki ti a fi n da ifa ni opele, omo ni opele je fun ikin sugbon o wulo pupo nitori pe o rorun lati da ifa. Omo mejo ni opele bi, merin ni apa otun, merin ni apa osi. Okookan ninu awon omo wonyii ni o ni inu ati eyin.
- IBA: Bi a ba ti da ifa kale tan ti a si ti mo odu ti o jade, a maa lo iba lati wa idi odu yii dele kodoro. A le fii mo eni gan-an ti odu yii jade si, bi eni ti o waa dafa gan-an ni o tabi eeyan re kan. A tun maa n lo ibo lati yan ebo ati lati beere lowo ifa ibi ti a o gbe ebo naa si. Orisiirisi ibo lo wa. Pataki julo nibe ni egungun ati owo eyo. Egungun duro fun bee ko owo eyo duro fun bee ni.
- IROKE: Iroke je ohun elo ifa dida ti a fi n pe Orunmila bi a bat i n da ifa lo. A tun maa n pee ni irofa. Eyin erin ni a fi n gbe iroke sugbon a le fi ide tabi igi lasan gbee.
- OPON IFA: Orisii opon ifa lo wa, omiran ri roboto, omiiran ni igun merin. Bi babalawo ba fi ikin da ifa, dandan ni ki won o ni opon ifa ninu eyi ti won o maa tee si. Iyerosun ni a maa n ko sinu opon yii, ninu re si ni a ma ate ifa si.
- AGERE IFA TABI AWO IFA: Ninu awo yii ni awon babalawo maa n ko ifa si. Won maa n fi igi gbe agere ifa pelu ideri re, nitori pe ibe ni a n ko ikin ti o duro fun Orunmila si, awon gbenagbena ni lati fara bale gbee ki won o si se ona ti o jojunigbese sii lara.
- APO IFA: Ona pataki kan ti a fi le da babalawo mo ni nipa apo ti won maa n fi ko si ejika. Ninu apo yii ni won maa n ko gbogbo ohun elo ifa dida si. Babalawo kii rin ko san wo ifa. Aso ni a fi se apo yii sugbon maa fi kikada ileke, olowo iyebiye hun apo ifa miiran.
- ILU IFA: Oroorun tabi nigbakugba ti won ba fe se ariya, bibo ifa tabi se etutu. Ilu ifa ti won maa n lo ni aran tabi ipese.