- Gbolohun alalaye
- Gbolohun ibeere
- Gbolohun ase
- Gbolohun ebe
- Gbolhun ayisodi
Gbolohun Alalaye:- Eyi ni a fi n se iroyin bi isele tabi nnkan se ri fun elomiran lati gbo. Apeere.
- Ebi n pa mi
- Tisa lo gba iwee mi
Gbolohun Ibeere :- Eyi ni ona ti a n gba se ibeere nipa lilo atoka asebeere bii, tani, ki ni, ba wo me loo, igba loo, n je, sebi, abi abbl. Apeere ;
- N je won gba ?
- Se Ade wa ?
Gbolohun Ase :- Eyi ni gbolohun ti a fi n pase fun eni ti a n ba soro.
Apeere ;
- Dide duro
- E dake jeje
Gbolohun Ebe :- A n lo gbolohun ebe lati fi bebe fun ohun kan. Apeere;
- Fun mi ni omi mu
- Jowo maa bu mi mo
Gbolohun Ayisodi:- Gbolohun yii ma n fihan pe isele kan ko waye. Itumo re ni bee ko. Awon oro, atoka gbolohun ayisodi ni; ko, kii, ko I, le. Apeere;
- Olu o le lo
- Oluko ko I ti lole
- Jide kii se akoigba
Igbelewon:-
- Ko awon eya gbolohun nipa ise won
- Salaye ni kukuru pelu apeere meji meji
Ise Asetilewa :- Ko eya gbolohun wonyi si le ;
- A ti ri gbogbo won
- Ta ni o jale
- E dake jeje
- Ba mi toju re daadaa
- Olu ko wa ni ona.
ASA :- Asa iranra-eni lowo II
Awon egbe iranra-eni lowo ode oni je eyi ti o ni ase ati atileyin ijoba ninu. Die lara won ni yi ;
- Egbe Iranlowo :- Iru egbe yii ni a ti n ri odomokunrin ati odomobinrin ni odugbo tabi ilu kan naa ti a o o si yan akikanju laarin egbe gege bii oloye. Ni opo igba, egbe yii ni o n dagba pelu awon to da a sile ti yoo si di egbe agba ati egbe arugbo.
Ajosepo ti o dan moran maa n wa laarin awon omo egbe, won a maa dide si ohun inawo bii, igbeyewo, isomoloruko. Egbe yii ba kan naa a maa gbon iya nu fun omo egbe, ebun lorisirisi ko lo n ka ti awon omo egbe maa n je latari ibasepo won pelu egbe.
- Egbe oselu :- A n da egbe yi sile lati fi se ilu, a fi n tun iluse. Tokunrin tobinrin ni o n wa ninu egbe yii. Egbe oselu ni a fi n tun ilu se lode-oni.
Pupo omo egbe lo n dibo si ipo asoju ninu eto ijoba sugbon wobia at onijekuje, onimotaara-eni nikan lo po ju ninu awon oloselu orile ede Naijiria. Kaka ki won tun ilu se ni se ni won n ba ilu je si.
- Egbe Agbe :- Egbe yii lo n wa itesiwaju fun awon agbe ni orile ede Naijira.
Erongba egbe yii ni lati wa ounje ati awon nnkan ti a n lo n i ayika wa ni opo yanturu fun ilo gbogbo eniyan. Ba kan naa, lati mu ki ise naa rorun fun awon to n se e.
A da egbe yii sile ki awon omo egbe le fi ohun sokan lati lepa ona ti won yoo fi mu erangba won se. lode-oni, ijoba ti n ya awon egbe low lati fi se ise agbe, oogun igbinre (igbin ire) ati eyi ti yoo mu ki ile loraa si ni ijoba n pese fun awon agbe latari egbe yii.
Awon Egbe Igba Lode Miiran Ni Wonyi;
Egbe alasowopo
Egbe ogboni
Egbe olowo
Egbe oloogun
Egbe alaanu abbl.
Igbelewon:
- Ko egbe iranra-eni low ode-oni marun-un
- Salaye meta père.
Ise Asetilewa :- mu okan père lara awon egbe iranra-eni lowo igbalode wonyii ki o si salaye lekun un rereLITIRESO :- Kika iwe litireso ti ijoba yan.
Read our disclaimer.
AD: Take Free online baptism course: Preachi.com