Ere idaraya ni awon ere ti tewe tagba n se lati mu ki ara won ji pepe ni ile Yoruba. Bi akoko ise se wa bee ni won ni akoko fun ere idaraya. Akoko ti owo ba dile ni won maa n se ere idaraya. Tomode – tagba ni ere idaraya wa fun ni ile Yoruba
Isori Ere Idaraya Laaarin Awon Yoruba
- Ere ojoojumo
- Ere osupa(ere ale)
Ere ojojumo: eyi ni ere ti tomode tagba maa n se ni owo osan si irole. O pin si ona meji;
- Ere Abele: apeere ere yii ni: ere ayo tita,mo-ni-ni –mo-ni – ni , booko-booko
- Ere itagbangba: apeere ere yii ni; ere ijakadi, ere aarin, ere ayo tita
Ere osupa: eyi ni ere ti awon omode maa n se ti ile ba tis u ni akoko ere osupa nitori aisi ina monamona ni aye atijo. Apeere irufe awon ere yii ni; ere bojuboju, ekun meran, isa- n-saalubo, eye meta tolongo waye, kin ni n leje?, alo lorisirisi abbl
Ni kukuru,ere sise wopo laaarin Yoruba paapaa julo nigba ti owo ba dile. Ere ayo tita je ere awon agba to kun fun ogbon ati opolopo iriri,omode ti o ba si mo ayo ta awon agba Gbagbo pe ologbon omo ni.
Apeere orin ere idaraya;
Ekun meran
Lile: ekun meran Egbe: meee
O tori bogbo meee
O torun bogba meee
Oju ekun pon meee
Iru ekun n le meee
O fe mu o meee
Ko ma le mu o meee
Ekun meran meee
Ekun meran meee
Ekun meran meee
Kin ni n leje
Lile: kin ni n leje Egbe: lenjelenje
Ewure n leje lenjelenje
Aguntan n leje lenjelenje
Obuko n leje lenjelenje
Adiye n leje lenjelenje
Okuta n leje iro n la
Akiti lo le ja:
Ele: Akiti lo le ja o
Egbe: ija lo le ja o
Ele: o gbe para o fi da
Egbe: ija lo le ja o
Ele: O ro ki bii ibon
Egbe: ija lo le ja o
Igbelewon:
- Fun ere idaraya loriki
- Salaye isori ere idaraya laaarin awon Yoruba pelu apeere orin ere naa.
Ise asetilewa:
- N je ere idaraya ode oni dara ju ere idaraya abinibi? Tu keke oro.
Read our disclaimer.
AD: Take Free online baptism course: Preachi.com