Aruko oniroyin je mo itan tabi isele kan to sele ti a wa n royin re fun elemiran.
Iroyin bee le je isele atinuda alarako tabi ojumilose
AWON IGBESE AROKO
- Ori Oro :- Ila akoko ni a n ko o si.
Apeere ori aroko oniroyin ni wonyi ;
- Iroyin odun osun osogbo ti mo wo
- Isomoloruko kan ti won se ni ile wa laipe yii
- Irinajo ojumito si ago olopaa
- Ere akonilekoo kan ti mo wo
- Ilapa eto:- Aroko gbodo wa ni sise-n-tel ni ipin afo.
- Ifaara :- eyi ni ipin afo to bere aroko ko gbodo gun ju
- Koko:- eyi ni koko ti a fe soro le lori
- Ikadii :- ikadii ni a o ti fi iho ti a ko si koko aroko wa han. So ki ni obe oge ni ikadii wa gbodo je
- Ede :- Ojulowo ede yoruba ati ona ede to jiire ni a gbodo fi ko aroko wa ki a si yera fun lilo ede adugbo tabi eka ede.
Igelewon :-
- Kin ni aroko oniroyin
- Salaye igbese aroko oniroyin meta
Ise Asetilewa :- ko aroko ti ko din ni 250 eyo oro lori okan ninu aroko wonyi. Lo ede yoruba ode oni ati ede iperi to jiire.
- Rogbodiyan akekoo ti o soju mi
- Ere akonilogbon kan ti mo wo
- Ijanba ina kan ti o sele ni oju re.
ASA:- ASA ISOMOLORUKO
Asa isomoloruko je ona ti a n gba fun omo tuntun ni oruko ti yoo maa je titi lai ni ile Yoruba.
Gbogbo ohun ti Olodumare da saye lo ni oruko. Oniruuru ohun elo tabi eronja ni Yoruba si maa n lo nigba ikomojade. Ojo kefa ni Yoruba n so omo loruko iba se omokunrin tabi omobinrin tabi ibeji. Sugbon ni ibo miiran ni ile Yoruba, ojo kesan-an ni won n so omokunrin loruko, ojo keje ni ti obinrin, ti awon ibeji ni ojo kejo.
DIE LARA OHUN ELO ISOMOLORUKO NIYI;
OHUN ELO IWURE
Obi bibi lobi n biku danu, bibi lobi ni baarun danu, obi a bi ibi aye re danu
Orogbo orogbo maa n gbo saye o o gboo, wa a to, wa gbo kegekege, o koo ni gbo igbo iya
Oyin a kii foyin senu ka roju koko, oro bi oyin bi adun ko ni dagbere fun o ko ni je koro laye
Oti oti kii ti, o ko ni ti laye bee ni oti kii te, o ko ni te
Epo pupa epo ni iroju obe aye re a roju
Iyo iyo nii mu obe dun, iwo ni o maa mu un awon obi re dun
Atare ataare ki bimo tire laabo, fofo ni le ataare n kun. Ile re a kun fomo
Igbelewon :-
- Fun asa isomoloruko loriki
- Ko ohun elo ismomoloruko maru-un ki o si fi se iwure
Ise Asetilewa :- N je lilo awon ohun elo isomoloruko ibile wonyii ni ile yoruba si fi ese mule bi ?
LITIRESO :- Alo Apomo ati Apagbe
Alo ni oro elo ti o je afiwe ti o si maa n so nnkan ti ko se e se nigba miiran.
Alo maa n so nnkan ti ko ni eemi di ohun elemii.
ORISI ALO
- Alo apamo
- Alo apagbe/onitan
ALO APAMO
Eyi ni alo ibeere ait idahun.
Apeere ;
Ibeere :- Awon agba marun-un sin olu-ife lo si ogun, agba marun-un pada wale, olu-ife ko wale.
Idahun :- Okele eba ni olu-ife, ika owo marun-un ni agba marun-un
Akiyesi :- Ohun ti ko ni eemi ni aso di ohun elemii
AAFAANI ALO APAMO
- O wa fun itaniji
- O n da ni le koo
- O wa fun idaraya
- O n ko omode nipa ilo ede
- O n je ki omode ronu jinle
- O n je ki omode ni igboya lati le soro ni awujo
ALEEBU
- O n je ki omode yo ise ile sile
- O n ko omode ni isokuso
- Ki n je ki omode tete su lale
ALO APAGBE/ONITAN
Alo apagbe ni alo orin ati ijo.
Itan aroso laisan ni.
ANFAANI ALO APAGBE
- O n ko ni lekoo
- O n bu neu ate lu iwa ibaje bii ole jija, okanjua sise, iro pipa, eke sise, igberaga abbl.
KOKO INU ALO ONITAN
- Itan ti o n ko ni lekoo
- Itan ijapa
- Itan ti o n os idi abajo
Igbelewon :-
- Kin ni alo
- Orisi alo meloo ni o wa
- Salaye orisirisi alo won yi lekun-un rere
Ise Asetilewa :- pa alo apagbe kan ti o mu ogbon dani
Read our disclaimer.
AD: Take Free online baptism course: Preachi.com