Isori oro ninu ede Yoruba
Isori oro ninu ede Yoruba ni wonyii
- Oro-oruko
- Oro Aropo oruko
- Oro Aropo Afarajooruko
- Oro Eyan / Apejuwe
- Oro Ise
- Oro Aponle
- Oro Atokun
- Oro Asopo
Oro-oruko: Eyi ni awon oro ti won le da duro ni ipo Oluwa, abo tabi eyan ninu gbolohun.
Ipo meta ni oro oruko le ti jeyo ninu gbolohun. Awon ni ;
- Ipo Oluwa :- Eyi ni oro oruko ti o jeyo ni ibere gbolohun tabi ti o je oluse isele inu gbolohun. Apeere ;
Sola lo si iwo
Ade jeun yo
Alaafia to oyo
- Ipo Abo :- Eyi ni olu faragba nnkan ti oluwa se ninu gbolohun. Aarin tabi ipari gbolohun ni o maa n wa. Apeere ;
Oluko ra oko ni ona
Jide gun iyan
- Ipo Eyan :- Ti oro oruko meji ba tele ara ninu apola oruko, oro oruko keji ni yoo yan oro oruko kin-in-ni. Apeere ;
Olumide oluko ti de
Iwe iroyin dara lati maa ka
Eja alaran-an ni mo fe ra.
Oro oropo-oruko :- Orisi ipo meta ni oro oropo-oruko ti le je yo ninu ihun gbolohun ede Yoruba.
O le je yo saaju oro-ise nipo oluwa. Apeere ;
Eni | Eyo | Opo |
Kini | Mo sun | A sun |
Keji | O sun | E sun |
Keta | O sun | Won sun |
- O le jao saaju erun ‘n’ ninu apola ise. Apeere;
Eni Eyo OPo
Kiini Mo n sun A n sun
Keji O n sun E n sun Keta O n sun Won n sun
- O le je yo saaju awon wunren bii ko/o ki, iba, ibaa. Sugbon oro aropo eniketa ko le wo iru ihun yii. Apeere;
Eni Eyo Opo
Kiini N o sun A o sun
Keji o ko sun E baa sun
Keta
- Ipo abo
Eni Eyo Opo
Kiini Mi Wa
Keji O/e Yin
Keta Afagin faweli to gbeyin oro-ise won
Akiyesi:-
- Ti oro-aropo oruko ba wa leyin oro ise olohun oke, ohun aarin ni oro aropo oruko ba yoo ni. Apeere;
Eni Eyo Opo
Kiini O ki mi O ki wa
Keji O ki o/e O ki yan
Keta O ki I O ki won
- Ti oro aropo oruko ba wa leyin oro ise olohun aarin, ohun oke ni oro aropo oruko bee yoo ni. Apeere;
Eni Eyo Opo
Kiini O bi mi o bi wa
Keji o bi ole o bi yin
Keta o bi i o bi won
- Ti oro aropo oruko ba wa leyin oro ise olohun isale, ohun oke ni oro arop oruko bee yoo ni. Apeere;
Eni Eyo Opo
Kiini o ti mi o ti wa
Keji o ti o/e o ti yin
Keta o ti I o ti won
- Ipo eyan
Eni Eyo Opo
Kiini mi wa
Keji re yin
Keta re won
Apeere,
Eni eyo opo
Kiini ile mi niyi ile wa niyi
Keji ile re niyi ile yin niyi
Keta ile re niyi ile won niyi
Oro-oruko Afarajoruko:- Eyi je oro ti a n lo dipo oro-oruko. Awon ni,
Eni Eyo Opo
Kiini Emi Ewa
Keji Iwo Eyin
Keta Oun Awon
Oro-eyan:- Eyi ni awon oro ti won n yan oro-oruko ninu apole-oruko
Orisi oro-eyan
- Eyan Asapejuwe:- O maa n sapejuwe oro-oruko ni ona ti yoo fi ye ni yekeyeke. Apeere;
Oruko rere wu mi
Ounje kekere ko yo mi
Eja yiyan dun n mu gaari
ii. Eyan Ajoruko :- Eyi ni oro oruko tabi oropo-oruko ti a n lo lati yan oro-oruko miran. Apeere ;
Aja ode pa okete
Adisa tisa ra oko
iii. Eyan Asafihan :- O maa n toka si ohun ti a n soro nipa re gan-an. Apeere ;
(a) Oro ohun ti su mi
(b) Ise wonyi le ju fun wa
- Eyan asonka :- O maa n toka si iye ninu gbolohun. Apeere ;
- Ile meta ni oga ni
- Iyawo kan ni baba mi fe
- Eyan alawe gbolohun asapejuwe :- O maa n fi itumo kun oro oroko ninu gbolohun. “ti » ni wunren atoka eyan yii. Apeere ;
- Aso ti a ri ni oja ko dara to
Ile ti o n san fun wara ati fun oyin ni ile Naijiria
Oro ise: Eyi ni koko fonran to n toke isele tabi nnkan ti oluwa se ninu gbolohun. Apeere orisi oro ise.
Igbelewon :-
- Ko isori oro yoruba mejo
- Salaye pelu apeere meji meji ni kukuru
Ise Asetilewa :-
ko apeere meji meji fun isori oro kookan ti a se ayewo re yii
ASA:- Asa Elegbejegbe tabi iro-siro
Eyi ni awon eniyanti ojo ori won baara wonmu.Bibeli wi pe, nigba ti mo wa ni ewe, emi a maa huwa bi ewe, emi o maa soro bi ewe, sugbon nigba ti mo di okunrin tan mo fi iwa ewe sile”. Oro inu bibeli yii fi idi re mule pe otooto ni ihuwasi elegbejegbe to wa.
Ojo ori ni eda eniyan kookan fi n pin eniyan si elegbejegbe tabi iro isiro .Yoruba bo won ni “egbe eye leye n fo to, egbe eja ni eja sii we to”. Iwa ti awon iro kan ba n hu ni gbogbo awon to ba wa ninu iro naa yoo maa hu”
Pipin Eda Eniyan Si Elegbejegbe/Iro Siro
- Omo omu, omo owo, ikoko, arobo ati omo irinse ( omo oojo titi de omo odun meta)
- Majesin (omo odun meta si marun-un)
- Omode (omo odun mefa si metala)
- Agunbaniro (odun merinla si ogun odun)
- Gende/igiripa (odun mokanlelogun titi de ogoji odun)
- Agba (ogoji odun si aadorin odun)
- Arungbo (aadorin odun lo soke)
Ede Ti Irosiro Maa N Lo
Ede abykun ni ki iro ti o kere lo iwo fun agbalagba. Ede bii; e, eyin, yin, won ni iro ti o kere ni lati lo fun iro ti o dagba ju ni lo. Bi o ti le je pe awon eya miran ta pa si eyi. Ede arifin ko ye omoluabi gege bi asa ajumolo ile Yoruba.
Iranlowo Ti Iro Siro N Se Fun Ara Won
- Awon ogunbaniro maa n ba ara won se aaro lati fi se ise oko
- Won maa n ran ara won lowo nipa oro to ba jemo owo nipa ajo tabi esusu
- Ba kan naa, awon agunbaniro, igiripe ati awon agbe lokunrin lobinrin laye atijo maa n be ara won ni owe lati fi se ise ti won ba fe se.
Igbelewon:-
- Salaye elegbejegbe tabi iro siro
- Pin ede eniyan si elegbejegbe
- Iranlowo wo ni iro sire lo se fun ara won?
- Irufe ede wo ni o ye ki iro siro maa lo fun ara won?
Ise Asetilewa:Salaye ojuse awon agunbaniro ninu idagbasoke orile ede Nigeria
LITRESO:- Itupale iwe asayan ti a n ka.
Read our disclaimer.
AD: Take Free online baptism course: Preachi.com