Categories
Notes Yoruba

Akole Ise:- Ede:- Awon isori gbolohun Yoruba gege bi ise won.

  1. Gbolohun alalaye
  2. Gbolohun ibeere
  3. Gbolohun ase
  4. Gbolohun ebe
  5. Gbolhun ayisodi

Gbolohun Alalaye:-  Eyi ni a fi n se iroyin bi isele tabi nnkan se ri fun elomiran lati gbo.  Apeere.

  1. Ebi n pa mi
  2. Tisa lo gba iwee mi

Gbolohun Ibeere :-  Eyi ni ona ti a n gba se ibeere nipa lilo atoka asebeere bii, tani, ki ni, ba wo me loo, igba loo, n je, sebi, abi abbl.  Apeere ;

  1. N je won gba ?
  2. Se Ade wa ?

Gbolohun Ase :-  Eyi ni gbolohun ti a fi n pase fun eni ti a n ba soro.

Apeere ;

  1. Dide duro
  2. E dake jeje

Gbolohun Ebe :-  A n lo gbolohun ebe lati fi bebe fun ohun kan.  Apeere;

  1. Fun mi ni omi mu
  2. Jowo maa bu mi mo

Gbolohun Ayisodi:-  Gbolohun yii ma n fihan pe isele kan ko waye.  Itumo re ni bee ko.  Awon oro, atoka gbolohun ayisodi ni; ko, kii, ko I, le. Apeere;

  1. Olu o le lo
  2. Oluko ko I ti lole
  3. Jide kii se akoigba

Igbelewon:-

  1. Ko awon eya gbolohun nipa ise won
  2. Salaye ni kukuru pelu apeere meji meji

Ise Asetilewa :-  Ko eya gbolohun wonyi si le ;

  1. A ti ri gbogbo won
  2. Ta ni o jale
  3. E dake jeje
  4. Ba mi toju re daadaa
  5. Olu ko wa ni ona.

ASA :-  Asa iranra-eni lowo II

Awon egbe iranra-eni lowo ode oni je eyi ti o ni ase ati atileyin ijoba ninu.  Die lara won ni yi ;

  1. Egbe Iranlowo :-  Iru egbe yii ni a ti n ri odomokunrin ati odomobinrin ni odugbo tabi ilu kan naa ti a o o si yan akikanju laarin egbe gege bii oloye.  Ni opo igba, egbe yii ni o n dagba pelu awon to da a sile ti yoo si di egbe agba ati egbe arugbo.

Ajosepo ti o dan moran maa n wa laarin awon omo egbe, won a maa dide si ohun inawo bii, igbeyewo, isomoloruko.  Egbe yii ba kan naa a maa gbon iya nu fun omo egbe, ebun lorisirisi ko lo n ka ti awon omo egbe maa n je latari ibasepo won pelu egbe.

  • Egbe oselu :-  A n da egbe yi sile lati fi se ilu, a fi n tun iluse.  Tokunrin tobinrin ni o n wa ninu egbe yii.  Egbe oselu ni a fi n tun ilu se lode-oni.

Pupo omo egbe lo n dibo si ipo asoju ninu eto ijoba sugbon wobia at onijekuje, onimotaara-eni nikan lo po ju ninu awon oloselu orile ede Naijiria.  Kaka ki won tun ilu se ni se ni won n ba ilu je si.

  • Egbe Agbe :-  Egbe yii lo n wa itesiwaju fun awon agbe ni orile ede Naijira.

Erongba egbe yii ni lati wa ounje ati awon nnkan ti a n lo n i ayika wa ni opo yanturu fun ilo gbogbo eniyan.  Ba kan naa, lati mu ki ise naa rorun fun awon to n se e.

A da egbe yii sile ki awon omo egbe le fi ohun sokan lati lepa ona ti won yoo fi mu erangba won se.  lode-oni, ijoba ti n ya awon egbe low lati fi se ise agbe, oogun igbinre (igbin ire) ati eyi ti yoo mu ki  ile loraa si ni ijoba n pese fun awon agbe latari egbe yii.

Awon Egbe Igba Lode Miiran Ni Wonyi;

Egbe alasowopo

Egbe ogboni

Egbe olowo

Egbe oloogun

Egbe alaanu abbl.

Igbelewon:

  1. Ko egbe iranra-eni low ode-oni marun-un
  2. Salaye meta père.

Ise Asetilewa :- mu okan père lara awon egbe iranra-eni lowo igbalode wonyii ki o si salaye lekun un rereLITIRESO :-  Kika iwe litireso ti ijoba yan.

Discover more from StopLearn

Subscribe now to keep reading and get access to the full archive.

Continue reading