Ninu oro ‘baba’ ege meji ni a ni: ‘ba-ba’. Ege kookan ni o ni iro faweli ati ami ohun. Ege kookan yii ni a n pe ni silebu.
ABUDA SILEBU
(i) Silebu le je iro faweli kan tabi iro konsonanti ati faweli. Apeere:
i – ya
ba – ba
ko – bo
e – gbon
(ii) Iye ibi ti ohun ba ti je yo ninu oro kan ni yoo fi iye silebu ti oro naa ni han. Bi apeere:
Ife – Ibi meji ni ohun ti je yo (Silebu meji)
Omuti – Ibi meta ni ohun ti je yo (Silebu meta)
Ikadii – Ibi merin ni ohun ti je yo (Silebu merin)
IHUN SILEBU
Apa meji ni silebu pin si. Awon ni:
(i) Odo Silebu: Odo silebu ni ipin ti a maa n gbo ketekete ti a ba pe ege silebu kan. Ori re ni ami ohun n wa. Iro faweli tabi konsonanti aranmu asesilebu ‘n’ ni won le je odo silebu. Odo silebu ni a fala si nidii wonyi:
i-wa
i-gba-la
o-ro–n-bo
(ii) Apaala Silebu: Awon iro ti a ki i gbo ketekete ti a ba pe oro sita. Konsonanti inu silebu ni o maa n duro bii apaala silebu. Apaala silebu ni a fala si nidii wonyi:
i-wa
o-san
du-n-du
EYA IHUN SILEBU
(i) Silebu Onifaweli Kan (F): Eyi le je eyo faweli kan soso. Apeere iro faweli bee ni a fala si nidii wonyi:
A ti lo
Mo ri o
Mo ka a
Gbogbo iro faweli wonyi le da duro bii silebu:
a, e, ҿ, i, o, ϙ, u,
a, e, ҿ, i, o, ϙ, u,
a, e, ҿ, i, o, ϙ, u,
(ii) Silebu Alahunpo Konsonanti ati Faweli (KF). Apeere iru silebu bee ni wonyi:
wa, ba, bϙ, bҿ, ri, ra, mo, kϙ
gbϙn, ran, tan, rin, kun, wϙn
(iii) Konsonanti aranmupe asesilebu (N). Apeere iru silebu bee niyi:
n lϙ
o-ro-n-bo
i-sa-n-sa
PINPIN ORO SI SILEBU
Awon oro kan wa ti won ni ju silebu kan lo ninu ihun. Awon oro bee ni a pe ni ‘oro olopo silebu’. Apeere:
(i) Oro Onisilebu Meji
Oro | Ipin | Ihun | Iye silebu |
ҿgbon ifҿ iku Bϙla | Ҿ-gbon i-fҿ i-ku Bϙ-la | f-kf f-kf f-kf kf-kf | meji meji meji meji |
(ii) Oro Onisilebu Meta
Oro | Ipin | Ihun | Iye silebu |
Idoti Agbado Ijangbon Kansu Gbangba Banjo Gende Gbolahan | I-do-ti a-gba-do i-jan=gbon ka-n-su gba-n-gba Ba-n-jo Ge-n-de Gbo-la-han | f-kf-kf f-kf-kf f-kf-kf kf-n-kf kf-n-kf kf-n-kf kf-n-kf kf-kf-kf | meta meta meta meta meta meta meta meta |
(iii) Oro Onisilebu Merin:
Oro | Ipin | Ihun | Iye silebu |
Ekunrere Alangba Opolopo Olatunji Mofiimu Ankoo Laaro | e-kun-re-re a-la-n-gba o-po-lo-po O-la-tun-ji Mo-fi-i-mu a-n-ko-o la-a-a-ro | f-kf-kf-kf f-kf-kf-kf f-kf-kf-kf f-kf-kf-kf kf-kf-f-kf f-n-kf-f kf-f-f-kf | merin merin merin merin merin merin merin |
(iv) Oro Onisilebu Marun-un
Oro | Ipin | Ihun | Iye silebu |
Alaafia Ogunmodede Ogedengbe Alagbalugbu Agbalajobi Nigbakuugba | a-la-a-fi-a o-gun-mo-de-de o-ge-de-n-gbe a-la-gba-lu-gbu a-gba-la-jo-bi ni-gba-ku-u-gba | f-kf-f-kf-f f-kf-kf-kf-kf f-kf-kf-kf-n-kf f-kf-kf-kf-kf f-kf-kf-kf-kf kf-kf-kf-f-kf | marun-un marun-un marun-un marun-un marun-un marun-un |
(v) Oro Onisilebu Mefa
Oro | Ipin | Ihun | Iye silebu |
Gbangbayikita Orogodoganyin Afarajoruko Alapandede Konsonanti Bookubooku | Gba-n-gba-yi-ki-ta o-ro-go-do-gan-yin a-fa-ra-jo-ru-ko a-la-pa-n-de-de ko-n-so-na-n-ti bo-o-ku-bo-o-ku | kf-n-kf-kf-kf-kf f-kf-kf-kf-kf-kf f-kf-kf-kf-kf-kf a-kf-kf-n-kf-kf kf-n-kf-kf-f-kf kf-f-kf-kf-f-kf | mefa mefa mefa mefa mefa mefa |
ISE AMUTILEWA
(i) Akalamagbo (ii) Olododo (iii) Aworerin-in (iv) Akikanju
(v) Osoosu (vi) egbeegberun (vii) ileladewa (viii) igbaradi
(ix) iyaloosa (x) Akerefinusogbon
AKORI EKO: ATUNYEWO ISE ABINIBI
Ise ni oogun ise
Eni ise n se ko ma b’Osun
Oran ko kan t’Osun
I baa b’Orisa
O di’jo to ba sise aje ko to jeun
“Owuro lojo, ise la a fi i se ni Otuu’Fe”. Kaakiri ile Yoruba, ise ni won n fi owuro se. won gbagbo wi pe ‘Ise loogun ise’. Eredi ti won fi mu ise abinibi won ni okunkundun. Se ‘eni mu ise je, ko sai ni mu ise je’. Iran Yoruba lodi si imele, won gbagbo wi pe ‘owo eni ki i tan ni je’. Bi onikaluku ba ti ji idi ise ni won n gba a lo nitori ‘idi ise eni ni aa ti mo ni lole.’ Ibi ti baba bat i n sise ni omo yoo ti maa wo owo re, ti yoo si tibe maa ko o. won ni “Atomode de ibi oro n wo finnifinni, atagba de ibi oro n wo ranran.’ Owe yii fi han wa pe ko si ohun ti a fi omode ko ti a si dagba sinu re ti a ko ni le se daadaa. Eyi ni ise abinibi.
PATAKI ISE ABINIBI
Ise Agbe, ise ode, ise ona ati ise owo. Awon ise abinibi ile Yoruba ti a o yewo siwaju sin i: Ise Agbe, Ise Ajorin, Ise Alapata, Ise Onisowo, Ise Akope ati Ise Gbenagbena.
Ise agbe ni ise ti o gbajumo julo ninu ise ti won n se ni ile Yoruba. Awon agbe ni won n sogbon ounje, ti won n pese ounje fun awa eniyan. Ounje ti a n je ni o n fun ara wan i okun ati agbara lati sise oojo. “Ona ofun, ona orun”. Bee ni ‘bi ebi bat i kuro ninu ise, ise buse’.
PATAKI ATI IWULO ISE AGBE
Agbe pin si orisii meji wonyii:
(i) Agbe Alaroje: Iwonba oko ti won yoo fi bo enu ebi ni agbe alaroje n da. Won n gbin agbado, ege, ogede, ata ati ewedu. Eyi ti won ba je ku ni won n ta ni oja fun ara ilu.
(ii) Agbe Alada-Nla/Oloko-Nla: Awon agbe wonyii ni awon ti n fi ise agbe sise se, ti won n da oko nla, ti won si n kore repete. Bi won se n ta ni oja adugbo, ni won n ko won on koja si ilu miiran. Awon agbe yii maa n gba opolopo osise onise odun. Won le ra eru tabi ki won ya iwofa.
ORISII ILE TI AGBE N DA
ORISII OKO
Orisii oko meji to wa ni:
(i) Oko Egan: Oko egan ni oko titun ti enikan ko ti i da ri. Igbo kijikiji ni. O maa n jinna si ile. Won maa n ni ahere ti won le seun tabi maa gbe, ti won yoo si maa wale ni osoosu, tabi leekan lodun. Awon ni a n pen i ‘Ara-oko’ tabi ‘Agbe-Arokobodunde’.
(ii) Oko Etile: Oko etile ki fi bee jinna si ile. Awon ti n da oko etile ki saaba sun ni oko. Bi won ba lo ni aaro, won le pada si ile ni ale. Opo igba ni oorun tanmode-soko maa n mu won on di orun si oko.
OHUN ELO ISE AGBE: Oko, Ada, Akoko, Aake, Idoje ati Obe
Awon isoro to n doju koi se agbe
Agbe ni Ode-Oni: Ni ode-oni, tabi-tijoye, tokunrin-tobinrin ni won n sise agbe nitori irorun to de ba ise naa.
Awon ero katakata, ero-irole, tabi ikobe wa kaakiri ti won le ya ni owo pooku. Bee ni oogun igbalode buu ajile, korikori, taritari wa fun awon agbe onikoko.
Awon onimo ijinle, egbe alajosepo, ile ifowopamo ati egbe alajaseku wa ti won n ran awon agbe ni owo fun itesiwaju ise won.
Read our disclaimer.
AD: Take Free online baptism course: Preachi.com