“Eya ara ifo ni awon orisirisii eya ara ti a maa n lo fun pipe iro ede”.
Abuda kan pataki ti o ya awa eniyan soto si awon eda yooku ni ebun oro-siso. Bi apeere, ti a ba so wi pe ‘Bawo ni nnkan’, awon eya ara kan wa ninu ara wa lati ori de ikun ti won jumo sise papo lati gba gbolohun ibeere yii jade. Awon eya ara bee ni a n pe ni eya-ara ifo. Aworan eye-ara ifo naa niyi:
AWORAN EYA-ARA IFO
ISORI EYA-ARA IFO
A le pin awon eya-ara ifo si eya meji. Awon ni:
(i) AWON EYA-ARA IFO AFOJURI: Awon wonyi ni eya-ara ifo ti a le fi oju ri nipa lilo digi tabi nnkan miiran. Awon naa ni:
Afase, Olele, Iho imu Ita gogongo, Ete oke, Ete isale, Eyin oke, Eyin isale, Iwaju ahon, Aarin ahon, Eyin ahon, Erigi, Ajaa enu.
(ii) AWON EYA-ARA IFO AIFOJURI: Awon wonyi ni awon eya-ara ifo ti won wa lati inu ikun si inu ofun ti a ko le fi oju ri rara. Awon ni:
Kaa ofun, inu gogongo, Tan-an-na ofun, komookun, Eka komookun, Edo-foro.
S/N | EYA-ARA IFO | APEJUWE ILO WON |
1.
2. | Komookun
Edo foro | Edo-foro: Inu edo-foro ni eemi ti a n lo fun opo iro ede ti n tu jade sita. Eyi ni a n pe ni eemi edo-foro. Eran ara edo-foro maa n fe lati pese eemi amisinu tabi amisode fun oro siso.
Komookun ati Eka komookun: inu eka komookun mejeeji ati komookun ni eemi edo-foro n gba koja si inu gogongo ati enu. |
3. | Gogongo | Ori komookun tente ni gogongo dabuu le ni ofun. A le ri ita gogongo ni ofun wa. |
4. | Tan-an-na ati Alafo Tan-an-na | Inu gogongo ni tan-an-na wa. Inu alafo tan-an-na yii ni eemi edo-foro n gba jade si ona ofun. |
5. | Kaa Ofun, Kaa Enu ati Kaa Imu | Oke tan-an-na ni awon kaa meteeta wonyi wa. Ona ikoja ni won je fun eemi yala eemi amisinu tabi amisode |
6. | Ahon | Ahon je eya ara lo n kopa julo pipe iro ifo nitori pe o se e gbe si orisiirisii ipo. A le pin ahon si apa meta wonyi: (i) Iwaju ahon (ii) Aarin ahon (iii) Eyin ahon |
7. | Ete | A le paete po pekipeki; ete le fe seyin perese, tabi ki a su won po roboto. Idi niyi ti a fi n ni iro faweli perese tabi roboto. |
8. | Afase | Ni enu, afasa le gbera soke tabi wale fun eemi lati ri aaye gba kaa imu tabi enu jade. Idi niyi ti a fi n ni iro aranmupe tabi iro airanmupe. |
9. | Eyin oke, Erigi, Aja-enu | Afipe akanmole ni won. A n lo won po mo afipe asunsi lati pe iro. A n lo eyin-oke papo mo ete isale tabi iwaju ahon pelu arigi ati aja-enu. |
AFIPE: Afipe ni eya ara yoowu ti o ba n kopa ninu iro pipe.
Afipe ni gbogbo awon eya ara-ifo ti won wa lati oke alafo tan-an-na ofun de enu ati imu. Aarin yii ni a n pe ni opona ajemohun.
A le pin awon eya-ara ifo ti eon je afipe si meji. Awon ni:
AFIPE ASUNSI: Afipe asunsi ni awon eya ara isale enu ti won le gbera soke tabi sodo lati sun kan afipe akanmole ti a ba n pe iro. Awon ni: Olele, Ete isale, Iwaju ahon, Aarin ahon, Eyin ahon.
AFIPE AKANMOLE: Afipe akanmole ni awon eya ara oke enu ti won n duro gbari si oju kan ti a ba n pe iro. Awon ni: Ete oke, Ogiri ofun, Eyin oke, Afase, Aja-enu, Erigi, Kaa imu.
Awon eya-ara ifo miiran ti won wa ni opona ajemohun tun ni awon ise miiran ti won n se to yato si oro siso. Bi apeere, imu wa fun oorun gbigbo tabi mimi; eyin wa fun ounje wiwe, bee ni ahon wa fun tito nnkanwo. Opona ajemohun bere lati aarin oke alafo tan-an-na titi de enu ati imu.
AKORI EKO: AWON ORISA ATI BI A SE NBO WON
IPO OLODUMARE ATI ORISA
Awon Yoruba gba wi pe enikan wa ti o ni ogbon, agbara, to si ga ju gbogbo orisa ati eda aye lo. Eyi ni won n pe ni Olorun tabi ‘eni ti o ni orun’, ibi ti won gba gege bii ibugbe Re. Won mo, won si gba wi pe Olorun yii ni o tobi julo. Idi niyi ti won fi pe e ni Olodumare. Oniruru oruko ni won fun Olodumare lati fi igbagbo won han. Won ni “F’ija f’Olorun ja, f’owo leran”. Eyi fi Olodumare han bi onidajo ododo.
Alarina tabi alagbawi lasan ni awon orisa je laaarin Olodumare ati awon eda eniyan. Iranse Olodumare ni awon Yoruba ka won si. Olodumare ni o ran won wa si ile aye lati wa tun aye se. Idi niyi ti awon Yoruba se fi won si ipo pataki. Igbagbo Yoruba tun re e.
PATAKI ORISA LAWUJO YORUBA
Ti a ba n soro nipa orisa ile Yoruba, bi eni n soro nipa esin abalaye won ni. Awon orisa wonyi ti di ohun ti won n bo fun awon idi ti a ti menuba. Iwonyi ni pataki awon orisa yii ni awujo Yoruba.
A ki i siwaju Olifa
A ki i siwaju Olorisa korisa
A ki i siwaju Olobatala reri ose;
A ki i siwaju Tisa liborin:
Bi a ba siwaju Tisa liborin
A ko maa gbo ki duuru kun.
ISE AMUTILEWA
Read our disclaimer.
AD: Take Free online baptism course: Preachi.com