Leta kiko je ona ti a n gba gbe ero okan wa kale lori pepa ranse si elomiiran.
Isori leta
- Leta gbefe
- Leta aigbefe
LETA GBEFE
Leta gbefe nil eta ti a maa n ko si eni ti o sunmo wa; o le je molebi, ore, tabi alajose.
Leta gbefe fi aaye gba eniyan lati fi ero inu re han elomiiran. O le je baba, iya, egbo, aburo, ore ati ojulumo eni gbogbo.
Igbese kiko leta gbefe
- Adiresi akoleta : Apa otun ni oke tente ni adireesi akoleta maa n wa. Nonba ojule, opopona tabi apoti ile ifiwe ranse si (p.o. Box) , oruko ilu ati ipinle eni ti a n ko leta si ni yoo wa ninu adireesi yii.
- Deeti : ojo, osu, ati odun ti akoleta n kowe re yoo wa ninu adireesi yii.
- Ikini ibere : apa osin ni ibere ila ti o tele deeti ni a n ko eyi si pelu ami idanuduro die ni ipari re.
- Koko leta : eredi ti akoleta fi n ko leta re ni yoo so di mimo ninu ipin afo yii.
- Ipari/ikadi leta : owo otun ni akoleta yoo sun owo si ni ori pepa, oruko akoleta nikan ni yoo han ni opin leta yii pelu ami idanuduro die.
Igbelewon:
- Kin ni leta kiko?
- Ko orisi leta meji
- Salaye okookan ni kikun
- Ko igbese leta kiko marun-un pelu alaye kikun
Ise asetilewa:
Ko leta si ore re nipa awon aseyori ti o ni lenu eto eko re ni saa yii.
EKA ISE: ASA
ORI ORO: ASA ISINKU – OKU ABAMI
- Oku eni ti igi yalu pa :eedi lo maa n mu ki igi ya lu eniyan pa, ki I se oju lasan, ija ogun to le ni. Ni geere ti isele yii ba sele ni awon molebi oku yoo ti ranse pea won oloro. Gbogbo dukia oku patapata ni won yoo gba, won a si se etutu nidi igi ti o ya pa iru oku bee,idi igi naa ni won yoo si si in si nitori pe won ko gbodo gbe iru oku bee wo ilu.
- Oku eni ti o pokunso : bi eniyan ba pokunso, ki ba se lori igi tabiaja ilea won molebi yoo ra ohun etutu pelu owo repete ni won yoo ko fun awon oloro. Awon oloro yoo se etutu, leyin naa ni won yoo ge okun ti oku naa fi pokunso . Idi igi naa ni won maa n sin iru oku bee si.gbogbo dukia oku yii ni awon molebi yoo ko fun awon oloro.
- Oku odo: agba inawo ni oku eni to ku si odo.inawo pajawiri yii klo ni je ki awon molebi oku ranti ekun nitori pe gbogbo ohun tie nu n je ni awon oloro yoo gba lowo won lati fi se etutu oku fun orisa odo (yemoja). Eti odo naa ni won yoo sin iru oku bee si nitori eni ku si odo ti di ‘olu – odo ‘Omo eni ti o ku si odo ko gbodo mo oju oori baba tabi iya re ti isele yii sele si laelae.
Igbelewon:
- Fun asa isinku loriki
- Ko oku abami marun- un ki o si salaye meji pere
Ise asetilewa:
Gege bi I iwoye tire, irufe oku wo lo bani leru ju? salaye
EKA ISE: LITIRESO
ORI ORO: ITUPALE ASAYAN IWE EWI TI AJO WAEC/NECO YAN FUN TAAMU YII.