Categories
Notes Yoruba Yoruba JSSCE

Akole ise: atunyewo awon asa ninu ise olodun kin-in – ni

Asa ni iwa ajumolo awon eniyan ati isesi won. Yoruba ka asa si lopolopo, orisirisi asa si ni awon Yoruba le mu yangan lawujo. Lara awon asa naa niyi

  1. Asa iranra-eni-lowo
  2. Asa ikini
  3. Asa ogun jije abbl.

ASA IKINI

Asa ikini je okan lara iwa omoluabi ti a gbodo ba lowo omo ti a bi, ti a ko ti o si gba eko rere.

Yoruba bo won ni “ka ri ni lokeere, ka sayesi, o yoni, o ju ounje lo” ni ile Yoruba omokunrin maa n do bale gbalaja ti awon omobinrin yo si lo lori ikunle ti won ba n ki obi tabi awon ti o ju won lo.

Omo ti o ba ka asa ikini si ti o si n bowo fun agba, Yoruba ka iru omo bee si omo gidi, to gbon ti o si ni eko ile.

ASA OGUN JIJE.

Ti eru kan ba ku ni ile Yoruba, gbogbo dukia tabi eni ti o ba fi sile ni a n pe ni ogun.

Eto wa lori bi a se n pin ogun ni ile Yoruba. leyin ti won ba ti sofo eni ti o ku tan ni won maa n pin ogun re ki dukia re maa ba da ija sile.

Eni ti o ba dagbe ju ninu agboole kan ni o maa n seto ogun pinpin ni ile Yoruba, awon agba yii yoo se iwadii bii oloogbe se se ilana pinpin ogun re sile ko to jade laye, ti eyi ba wa, won yoo lo o,  sugbon ti ko ba si , awon agba ile yoo lo laakaya won lati se iwadii lori gbogbo ohun ti oloogbe fi saye won yoo si pin bi o ti to laaarin awon omo, iyawo ati aburo oloogbe.

Lara awon ohun ti a le pin gege bii ogun ni ile, ile, aso, oko, iyawo, omo oku to kere, oso ara, gbese abbl.

ASA IRANRA-ENI LOWO

Asa iranra-eni lowo je okan lara ona ti Yoruba n gba lati ran ara won lowo nibi ise won gbogbo.

Orisi ona ti Yoruba n gba ran ara won lowo laaye atijo niyi,

  1.  Esusu: Iye owo ti eniyan ba da ni yoo gba
  2. Ajo: Eniyan le gba ju iye ti o ba da lo
  3. Owe: Omokunrin ti o ni iyawo ni o maa n be awon ore re lowe
  4. Aaro: Sisise ni oko awon ti o sun mora titi yoo fi kari
  5. Aroko doko: Eyi ni sisise ni oko eni-kookan titi yoo fi kari sugbon kii se oko awon ti o sun mora nikan.

Lode-oni: Egbe alafowosowopo je ona ti a n gba ran ara eni lowo.

Egbe yii n bo asiri nipa yiya ni lowo , o si fi aaye sile lati daa pada ni diedie.

Read our disclaimer.

AD: Take Free online baptism course: Preachi.com MAKE-MONEY

Discover more from StopLearn

Subscribe now to keep reading and get access to the full archive.

Continue reading