EKA ISE: EDE
AKOLE ISE: AKOTO EDE YORUBA
Akoto ni sipeli tuntun ti awon onimo ede Yoruba fi enu ko le lori ni odun 1974 lati fi maa ko ede Yoruba sile.
Awon ayipada ti o de ba kiko ede Yoruba sile ni wonyi
SIPELI ATIJO | SIPELI TUNTUN | IFIYESI |
Aiya Aiye Eiye | Aya Aye Eye | A gbodo yo faweli “I” nitori a ko pe e |
Otta Oshogbo Ogbomosho Ebute-Meta | Ota Osogbo Ogbomoso Ebute-Meta | Konsonanti meji kii tele ara ninu ihun ede Yoruba |
Olopa Alanu Lailai Na Papa Miran Yi | Olopaa Alaaanu Laelae Naa Paapaa Miiran Yii | Iye iro faweli ti a ba pe ni ki a ko sile |
On Enia Okorin Obirin Nkan Onje | Oun Eniyan Okunrin Obinrin Nnkan Ounje | |
Tani Kini Gegebi Gbagbo Nitoripe Lehina Biotilejepe | Ta ni Kin ni Wi pe Gege bi Gba gbo Nitori pe Leyin naa Bi o tile jepe | A ni lati ya awon oro yii soto |
EKA ISE: ASA
AKOLE ISE: IWA OMOLUABI ATI ANFAANI RE
Omoluabi ni omo ti a bi ti a si ko ti o gba eko rere.
Ile ni a ti n ko eso rode. ise ati iwa omoluabi bere lati inu ile ti a ti bii.
Lara awon iwa omoluabi ni,
- Iwa ikini
- Bibowo ati titeriba fun agba
- Hihuwa pele lawujo
- Ooto sise
- Iwa irele ati suuru
- Iwa igboran
- Sise oyaye
- Iwa iran-ra-eni lowo.
Igbelewon:
- Kin ni akoto?
- Ko sipeli atijo mewaa ki o si ko akoto re gege bii awon onimo se so
- Fun iwa omoluabi loriki
- Ko iwa omoluabi marun-un ki o si salaye
Ise asetilewa: ko sipeli atijo mewaa ki o si salaye awon ayipada ti o de ba okookan won gege bi awon onimo se fi enu ko ni odun 1974
Read our disclaimer.
AD: Take Free online baptism course: Preachi.com