EKA ISE: EDE
AKOLE ISE: ITESIWAJU LORI EKO IRO EDE
Apejuwe iro konsonanti
Iro konsonanti ni iro ti idiwo maa n wa fun eemi ti a fi gbe won jade.
A le pin iro konsonanti si ona wonyi;
- Ibi isenupe
- Ona isenupe
- Ipo alafo tan-an-na
Ibi isenupe: Eyi ni ogangan ibi ti a ti pe iro konsonanti ni enu. O le je afipe asunsi tabi akanmole.
Alaye lori ibi isenupe
IBI ISENUPE | KONSONANTI TI A PE | ISESI AFIPE |
Afeji-ete-pe | B, m | Ete oke ati ate isale pade-apipe akanmole ati asunsi pade |
Afeyin fetepe | F | Ete isale ati eyin oke pade afipe asunsi ati akanmole pade |
Aferigipe | T, d,s,n,r,l | Iwaju ahon sun lo ba erigi oke . afipe asunsi ati afipe akanmole |
Afaja ferigipe | J,s | Iwaju ahon sun kan erigi ati aarin aja enu. afipe ati afipe |
Afajape | Y | Aarin ahon sun lo ba aja enu. afipe asunsi ati akanmole |
Afafasepe | K, g | Eyin ahon sun lo kan afase .afipe asunsi ati akanmole |
Afafasefetepe | Kp, gb,w | Ete mejeji papo pelu eyin ahon kan afase . afipe asunsi ati afipe akanmole |
Afitan – an-na – pe | H | Inu alafo tan-an na ni a fi pe e |
Ona isenupe: Eyi toke si iru idiwo ti awon afipe n se fun eemi ti a fi pe konsonanti, ipo ti afase wa ati iru eemi ti afi gbe konsonanti jade.
Alaye lori ona isenupe
ONA ISENUPE | KONSONANTI TI A PE | IRU IDIWO TI AFIPE SE FUN EEMI |
Asenupe | B,t,d,k,g,p,gb | Konsonanti ti a gbe jade pelu idiwo ti o po julo fun eemi afase gbe soke di ona si imu awon afipe pade lati so eemi, asenu ba kan na ni eemi inu enu ro jade nigba ti a si |
Afunnupe | F,s,s,h | Awon afipe sun mo ara debi pe ona eemi di tooro, eemi si gba ibe jade pelu ariwo bi igba ti taya n yo jo |
Asesi | J | A se afipe po, eemi to gbarajo ni enu jade yee bi awon afipe se si sile |
Aranmu | M,n | Awon afipe pade lati di ona eemi, afase wale, ona si imu le, eemi gba kaa imu jade |
Arehon | R | Ahon kako soke ati seyin, abe iwaju ahon fere lu erigi, eemi koja lori igori ahon |
Afegbe-enu-pe | I | Ona eemi se patapata ni aarin enu, eemi gbe egbe enu jade |
Aseesetan | W,y | Awon afipe sun to ara, won fi alafo sile ni aarin enu fun eemi lati jade laisi idiwo |
Ipo tan-an-na: ibi alafo tan-an-na ni a fi n mo awon iro konsonanti akunyun ati aikunyun.
Alaye ni kikun
IRO KONSONANTI | ALAYE | |
Konsonanti akunyun | D,j,gb,m,n,r,l,y,w | Awon konsonanti ti a gbe jade nigba ti alafo tan-an-na wa ni ipo ikun, eemi kori Aaye koja,eyi fa ki tan-an-na gbon riri |
Konsonanti aikunyun | P,k,f,s,s,h,t | Eyi ni awon konsonanti ti a gbe jade nigba ti alafo tan-an-na wa ni ipo imi eemi ri aaye gba inu alafo yii koja woo rowo |
ATE IRO KONSONANTI
Ona isenupe | Afeji- Etepe | Efeyin- fetepe | Aferi-gipe | Afaja- ferigipe | Afaja-pe | Afafa- sepe | Afafaseu Fetepe | Afitan-an-na pe | |
Asenupe | Akunyun | B | D | G | Gb | ||||
Aikunyun | T | K | Kp | ||||||
Afunnupe | Aikunyun | F | S | S | H | ||||
Asesi | Akinyun | Dz | |||||||
Aranmu | Akinyun | M | N | ||||||
Arehon | Akinyun | R | |||||||
Afegbe- Enupe | Akunyun | I I | |||||||
Aseesetan | Akunyun | J | W |
EKA ISE: ASA
AKOLE ISE: SISE OUNJE AWUJO YORUBA
Ouje ni awon ohun ti eniyan ati aranko n je tabi mu ti o fun ara wa ni okun ati agbara.
Won ni “Bi ebi ba kuro ninu ise, ise buse. Ouje ni oogun ebi.
Ise Agbe ni ise ti o gbajumo julo ni ile Yoruba, awon agbe yii ni on pese ire-oko ti eniyan ati eranko n je bii isu, ewa, agbado, gbaguda, eso lorisirisi bii, igba, ope, oyinbo, orogbo, asala, agbalumo, oronbo, obi abbl.
Ire oko ati bi a se n se won
- Iyan: Isu
A o be isu le na, ti isu ba jina, a o tu si odo. A o gun, bee ni a o ma ta omi sii titi yoo fi fele bi eti ti a o ko sinu abo fun jije pelu obe to gbamuse bii, efo riro tabi isapa.
- Amala: Ogede
Bi ogede ba ti gbe, won yoo lo o kuna . Elubo yii ni won yoo dasi omi hiho, ti a o fi omorogun ro o titi ti yoo fi dan. Leyin eyi ni a o fa sinu abo tabi inu ora iponmola. Obe gbegiri dara lati fi je amala ogede
- Aadun: Agbado
Ti a ba ti yan agbado, a o loo kuna. A o wa egeere epo ati eree ti a ti se, ti a si din, won yoo ro epo ati eree yii mo agbado ti a lo. Aadun de niyen
Read our disclaimer.
AD: Take Free online baptism course: Preachi.com