Categories
Yoruba

Asa isinku nile yoruba

Isinku je eye ikeyin ti a n se fun oku lati dagbere fun kuro lori ile aye Yoruba gbagbe pe gbese ni iku je fun gbogbo eda alaye, sugbon won maa n gbadura pe ki eniyan dagba ki o si dogbo ki o to dagbere fun aye. Igbese isinku yato lati ilu tabi eya kan si omiiran. Paapaa julo ona ti a n gba sinku arugbo tabi odo yato si bi a se n sinku alaboyun, afin, eni ti o pokunsi, eni ti o ku sinu odo abule abbl.

IGBESE ISINKU

  1. ITUFO: Eyi ni kikede fun gbogbo ebi ibatan o re, ojulumo alaabagbe pe ‘lagbaja ti fi ile se aso bora’. Eyi tunje ona ti a fin n so di mi mo fun awon eniyan pe enikan ti dagbere fun aye. An se eyi lan le se ipalemo sisnku eni ti oku ati lati le fun awon omo, ebi, ore ati ojulumo ni aaye lati wa ati kopa ninu eto isinku.
  2. OKU WIWE: A maa n se eyi lati toju oku nipa fifi kan-in-kan-in ati ose we fun oku, rire ekannaa oku, gige tabi didi irun ori won, fifi atike ati lofinda oloorun didun kun ara won leyin eyi, won yoo wo aso oke tabi funfun pelu gele tabi fila fun won.
  3. ILE OKU GBIGBE: Ni awujo awon Yoruba awon ara oku ni won maa n gbe saa re oku. Ni aye atijo mo ayika ile oku ni won maa n sun oku si.
  4. OKU TITE: Eyi ni sise afihan oku fun igba ikeyin lati je ki awon omo ebi ore, ara ati ojulumo ki won losoo. Awon eniyan yoo maa woni okookan won yio si yipo re.
  5. ALEJO SISE: Awon omo ati ebi oku yoo pese jije, mimu fun awon okunrin ilea won ti won gbele oku ati awon alejo won gbogbo.
  6. ISINKU: Eyi ni ayeye fifi erupe fun erupe, won yio gbe oku sinu posi pelu oniruru nkan bi eko funfun, obi abata, aso, bata opaitile, ileke ati oniruru ajo re, won yoo fi owo eyo kan, won yoo gbe adiye tele koto, bi won ba ti gbe sinku koto awon omo olooku ati yio bu erupe.
  7. OKU SISE: Leyin ifo-dogun (15 days) awon iyawo oku yoo bere opo sise fun odindin osu meta gbako, won koni fi oju kan ita. Aso dudu ni won yio ma wo, leyin osu keta won yoo se aye ye ijade – oko won yoo si bere si ma wo aso to ba wu won.
  8. OPO SISU: Awon ebi oko ti won n ye okunrin yio mu awon iyawo oku ti won ba si wan i omo bi aya. Eyi ni a ma n pe ni won su won lopo.

Click here to ask a question and get an answer published in the forum. Read our disclaimer.

Get paid for every topic you create in: Shoutam.com Forum!MAKE-MONEY