ORI ORO: ASA ISOMOLORUKO NI ILE YORUBA
Asa isomoloruko je ona ti a n gba fun omo tuntun ni oruko ti yoo maa je titi lae ni ile Yoruba
Gbogbo ohun ti Olodumaare da saye ni o ni oruko, ibaa se ohun abemi tabi ohun ti ko ni eemi. Idi niyi ti awon agba fi n so pe, “ile la n wo ki a to so omo ni oruko”
Orisirisi oruko ti awon eniyan n so omo tuntun
- Oruko amutorunwa
- Oruko abiso
- Oruko idile
- Oruko abiku
- Oruko inagije
- Oriki
- Oruko Amutorunwa: Eyi ni oruko ti a n so awon omo ti o gba ona ara waye tabi ti won mu nnkan ara waye lara won ni ile Yoruba. Apeere oruko bee ni; Ibeji,Oke,Dada,Olugbodi,Ige
- Oruko Abiso: Yoruba a maa wo ile,igba,asiko,ipo ti obi wa,ibi ti a bi omo si lati fun omo tuntun ni oruko.apeere;
- Oruko ajinde– Babajide,Babatunde,Iyejide,Iyetunde,Iyabode
- Oruko asiko odun: Abiodun,Bodunde, Bodunrin
- Oruko omo ti a bi si oke okun: Tokunbo
- Oruko omo ti a bi si ona: Abiona
- Oruko Abiku: Oruko yii pin si ona meji;
- Oruko ebe:Dorojaye, Omolanbe, Matanmi, Akisatan, Duroriike
- Oruko abuku: Aja , Kilanko, Omitanloju
- Oruko idile: Omoboola, Oladoye, Oyekunle, oyekanmi, Adebiyi
- Oruko inagije: Eyi ni oruko ti eniyan n fun ara re lati buyi kun iwa omoluabi re tabi eyi ti won fun eniyan kan nitori iwa ipanle. Apeere;
Olowomojuore, Olowojebutu, Owonifaari, Ekun, dudumaadan
- Oriki: oriki je oruko miiran ti Yoriba n so omo lati fi mo orile tabi idile ti o ti jade ati lati se koriya fun omo.Apeere; Alamu, Asake, Akanni, Asunle, Adufe, Awele, Apeke
Igbelewon:
- Fun asa isomoloruko loriki
- salaye orisi oruko ti yoruba n so omo tuntun pelu apeere meji meji.
Ise asetilewa:
- ko oruko inagije marun-un pelu itumo.
EKA ISE: LITIRESO
ORI ORO: ITUPALE EWI APILEKO TI IJOBA YAN
ORI ORO: IPOLOWO OJA
Ipolowo oja ni orisirisi ona ti a n gba se aponle oja nipa kike gbajare re si etigbo awon eniyan ati lat fa won mora.
Ipolowo oja ni agunmu owo.
Iwulo ati Pataki ipolowo oja
- Ipolowo oja ma n je ki oja ti oloja n ta di mimo fun ogooro eniyan yala ni tosi tabi ni ona jinjin
- O maa n je ki awon onraja ri nnkan ra ni arowoto won
- O maa n je ki awon onraja ni anfaani lati ye oja ti won f era wo
- O maa n je ki oja ti ontaja n ta ki o ya ni kiakia
Orisirisi ona ipolowo oja ti abinibi
- Ipate: ni aye atijo awon oloja a maa pate oja si oja,ikorita,iwaju ile,ni ori eni,ori kanta tabi konker,ona oko.apeere irufe oja ti won maa n pate ni; ire oko bii; isu,agbado,ogede,oronbo. Bakan naa, won a maa so eran osin mole ni ori iso lati ta
- Ikiri: Awon oloja a maar u oja le ori kiri lati ta,bee ni won a maa se aponle oja naa nipa kike gbajare si etigbo awon eniyan.apeere oja bee ni; epa atio guguru, nnkan iserun lorisirisi, eko gbigbona aso abbl
- Ohun enu: Eyi ni lilo ohun enu lati so oja di mimo fun onraja
Igbelewon:
- Kin ni ipolowo oja?
- Ko Pataki/iwulo ipolowo oja marun-un
- Salaye ona ipolowo oja abinibi.
Ise asetilewa: Salaye ona ipolowo oja ode oni meji lekun- un rere
Read our disclaimer.
AD: Take Free online baptism course: Preachi.com