Categories
Notes Yoruba

Ori Oro: Isori Oro – Oro Aropo- Afarajoruko

Oro aropo afarajoruko je oro ti a n lo dipo oro oruko sugbon ti o fi ara jo oro oruko.
Isesi oro aropo afarajoruko ko yato si ti oro oruko.
Ninu Ede Yoruba mefa pere ni awon oro aropo afarajoruko. Awon niyi

Eni Eyo Opo
Kin- in – ni emi awa
Keji iwo eyin
Keta oun awon

Abuda oro aropo afarajoruko

  1. Oro aropo afarajoruko se e pin si eto eni kin in ni, enikeji ati eni keta. Apeere;
    • Emi ni mo gbee
    • Iwo lo fa a
    • Oun ni o soro
  2. O se e pin si eto iye, eyi eyo tabi opo. Apeere;
    • Emi naa
    • Awon agbaagba
    • Oun yii
    • Awa niyi
  3. O le gba eyan ninu apola oruko.Apeere;
    • Oun naa ti dagba
    • Awon wonyi ko gbawe
    • Eyin yii ko fe ise se
  4. A le lo oro asopo “ati” lati so oro aropo afarajoruko meji po. Apeere;
    • Emi ati oun pa eye owiwi
    • Awa ati eyin feran Olodumare
  5. O le jeyo pelu awon wunren bii; ko , da, ni, nko. Apeere;
    • Iwo da?
    • Awon ko
    • Emi n ko?
    • Awon ni
  6. Oro aropo afarajoruko “oun” se e lo bi oro asopo fun oro oruko meji ninu gbolohun. Apeere;
    • Bola oun Bisi je eba
    • Anike oun Tade pa eran igala
  7. A le gbe oro aropo afarajoruko saaju wunren alatenumo “ni” lati pe akiyesi . Apeere;
    • Eyin ni mo n bawi
    • Oun ni mo feran ju lo
    • Awon ni o na mi
    • Iwo ni mo n ki
  8. A le seda oro miiran lara oro aropo afarajoruko nipa lilo mofiimu “ti” ati “afi”. Apeere ;
    • Ti + emi = temi
    • Ati + eyin = ateyin
    • Afi + awon = afawon
    Akiyesi: ipaje faweli ni o waye ninu apeere oke yii
    Igbelewon:
    • Ko itumo oro aropo afarajoruko
    • Meloo ni oro aropo afarajoruko ede Yoruba? Ya ate re.
    • Ko abuda oro aropo afarajoruko
    Ise asetilewa:
    Ko apeere oro aropo afarajoruko marun-un ki o si fi seda oro oruko ninu gbolohun.

EKA ISE: ASA
ORI ORO: OWO YIYA
Awon agba a maa powe pe “owo ni bi oun ko ba si nile, ki enikeni ma dabaa leyin oun” . Owo se Pataki ninu igbesi aye eda. Owo ni a fi n jeun,oun ni a fi n raso,owo ni a fi n rale,kole,owo ni a fi n fe aya,owo ni a fi n to omo.koda, owo ni a fi n sin oku agba ni ile Yoruba. Idi niyi ti awon Yoruba fi n so pe “ ko si ohun ti eniyan le se leyin owo “
Ko si eni ti oda owo ki n da, bi oda owo ba si da eniyan ti o sip on dandan fun iru eni bee lati lo owo si nnkan kan, ko si ohun ti o le se ju ki o ya owo lo lati fi bo bukata naa.owo yiya maa n bo asiri sugbon airi owo da pada fun olowo je okan lara aleebu owo yiya ni ile Yoruba.

AWON OHUN TI O LE SUN ENIYAN YA OWO
 Inawo ojiji bii isinku baba tabi iya eni, isinku ana eni
 Igbeyawo
 Aisan
 Oran dida
 Oye didu
ORISI ONA TI A N GBA SAN OWO ELE PADA
I. Fifi ara eni, omo ati ohun ini sofa : Ni aye atijo eni ti o bay a owo pupo ni lati maa fi ise sise loko olowo re san ele lori owo to baya. Eni ti o ya owo ti o si n lo sise sin oloko ni a n pe ni “iwofa”. Ise ti iwofa yii n se sin olowo re ni a n pe ni “ Egba tabi ogba sinsin”. Eto yiya ni lowo lon yii ni a n pe ni “iwofa yiya”.
Eni ti o ya owo le fi omo to bi tabi aburo re sodo olowo lati maa sise sin in dipo ara re lati san ele ori owo to ya. Iru igbese bayii ni a n pe ni “fifi omo sofa”. Iru omo bee ni a n pe ni “omode iwofa”.ojo ti iwofa ba san owo ti o je pada ni yoo to bo lowo olowo,ojo naa ni o di ominira patapata lowo olowo ele.
II. Fifi oko sofa : Eni ti o ba ni oko yala oko koko, obi, eyin, abbl le la oko bee si meji ki o si fi apa kan re yawo. Ire apa kan oko yii yoo je ti eni ti o ya ni lowo, eyi je ele ori owo ti o ya oloko. Ire oko apa keji ni oloko yoo ti ri owo ti yoo fi san owo ti o ya pada.o si di igba ti o ba san owo yii tan ki o to gba oko re pada lowo olowo.

Igbelewon:
• Salaye asa owo yiya ni ile Yoruba
• Ko awon ohun ti o le sun eniyan ya owo ni ile Yoruba
• Salaye orisi ona ti a n gba san owo ele pada ni ile Yoruba
Ise asetilewa:
• Salaye ona meta ti eniyan le gba ya owo laye atijo.

EKA ISE: LITIRESO
ORI ORO: EWI ALOHUN GEGE BI ORISUN IRONU YORUBA
ESE IFA
Ese ifa ni amu fun ogbon ati oye awon Yoruba nitori Orunmila ti o je orisa awon onifa ni a n ki bayii;

                             “Akere finu sogbon
                               Eleri ipin
                               Akoniloro bi iyekan eni”

Ese ifa ti wa lati igba iwase ,o ku fun oniruuru akiyesi ati iriri,oun ni orisa amonimola. Bi nnkan ba sir u eniyan loju, ifa ni won yoo bere lowo re.
Apeere ESE ifa lati inu odu iwori oyeku;
Igbo etile tountegbin
Adapo owo tountiya
Iwo o ju mi
Emi o ju o
Lara ile eni fi I fojudi ni “
Alaye: Ese- ifa yii pe akiyesi awon Yoruba si igbo ti o sun mo ile, awon obun a maa da oniruuru idoti si ibe bee ni won yoo ma yagbe sii pelu. Ewi yii tun se atenumo re pe , owo ajosepo laaarin eni meji tabi ju bee lo iya ayi iwosi lo maa n jasi. O tesiwaju pe, ilara ati owu jije maa n waye laaarin alabagbe nipa bee ainfin yoo wa. Gbogbo akiyesi yii kun fun ironu ati imo ijinle nipa ohun ti o n sele ni ayika wa.

Igbelewon:

  1. Salayeewi ese ifa gege bi okan lara ewi alohun yoruba
  2. Ko apeere ese ifa kan pelu alaye re
    Ise asetilewa:
    N je o ni igbagbo pe oro ogbon maa n jeyo ninu ese ifa?ko apeere ese ifa kan lati fi idi oro re mule

Discover more from StopLearn

Subscribe now to keep reading and get access to the full archive.

Continue reading