Oro ise ni koko fonran ti o n toka isele tabi nnkan ti oluwa se ninu gbolohun.
Oro ise ni opomulero gbolohun, lai si oro ise ninu gbolohun, ko le ni itumo.
Oro ise ni o maa n fun wa ni imo kikun nipa ohun ti oluwa se ninu gbolohun.
Orisi oro ise
- Oro ise kikun
- Oro ise agbabo
- Oro ise alaigbabo
- Oro ise asodidi gbolohun
- Oro ise eleyo oro ise(ponbele)
- Oro ise alakanpo
- Oro ise elela
- Oro ise alailela
Bi a se le lo awon oro ise wonyi ninu gbolohun ati bi a se le da won mo
- Oro ise kikun: Eyi ni eyo oro ise eyokan ti o ni itumo ninu gbolohun.apeere;
- Yemi sun
- Adufe jeun
- Folake korin
- Oro ise agbabo: Eyi ni oro ise ti won ko le sai gba abo(oro orruko) ninu gbolohun.apeere;
- Mo ra oko
- Anike ta ile
- Kilanko fe iyawo
- Oro ise alaigbabo: A kii lo oro abo pelu oro ise yii.apeere;
- Olodumare dara
- Igbeyawo dun
- Alamu jo
- Oro ise asodidi gbolohun(oro apase):Awon oro yii maa n waye bii gbolohun ase bakan naa won le duro bii gbolohun.apeere;
Wa, jokoo, dide, jade
- Oro ise alakanpo: A le pe oro ise yiii ni ‘Asinpo’. Eyi ni ki oro ise to bii meji tabi ju bee lo ninu gbolohun.apeere;
- Ole ko obe je
- Ologbo pa eku je
- Ige je ewa yo
- oro ise elela:Eyi ni awon oro onisilebu meji sugbon ti a le la sim meji lati fi oro miiran bo o ni aarin ti a sit un le lo won ti a ko ba fi oro miiran bo o ni aarin.apeere;
- Mo gba Oluwa gbo (Gbagbo) – mo gbagbo
- Jesu gba baba naa la (gbala) – Jesu gbala
- Esu tan Eefa je (tanje) – Esu tanje
- Oro ise alailela: a ko le la awon oro ise wonyii si meji,odidi ni won maa n wa ninu gbolohun.apeere;
- Fola subu lule
- Oyindamola siwo ise
- Bisola feran owo
Igbelewon:
- Fun oro ise loriki
- Ko orisi oro ti o wa ninu ede Yoruba
- Salaye pelu apeere bi a se le lo awon oro ise wonyi ninu gbolohun.
Ise asetilewa:
- Ko apeere oro ise alailela marun-un.