(2000-10,000)
Onka ni ona ti Yoruba n gba lati ka nnkan ni ona ti o rorun.
Eyi ni bi a se n se isiro nnkan ni ilana Yoruba.
Yoruba ni oniruuru ona ti won n gba lati kai ye nnkan ni aye atijo nitori won Gbagbo pe ko si nnkan ti a ki n ka bi o tile je pe “a kii ka omo fun olomo bee ni a kii toju onika- mesan-an kaa”. Yoruba a ma aka ile , oko, ebe, ika owo ati awon eya Ara gbogbo. Won a maa se amulo ilana aropo (+), ayokuro (-) ati isodipupo (*) ninu isiro won
Ilana onka lati egbaa titi de egbbrun-run
2000(200*10) – igba mewaa – egbewa/egbaa
2200(200*11) – igba mokanla- egbokanla
2400(200*12) – igbamejila – egbejila
2600(200*13) – igba metala – egbetala
2800(200*14) – igba merinla – egberinla
3000(200*15) – igba meedogun – egbeedogun
3200(200*16) -igba merindinlogun – egberindinlogun
3400(200*17) -igba metadinlogun – egbatadinlogun
3600(200*18) -igbamejidinlogun – egbejidinlogun
3800(200*19) -igba mokandinlogun – egbokandinlogun
4000(200*20) -ogun igba – egbaaji
4200(200*21) -igbamokanlelogun – egbokanlelogun
4400(200*22) -igba mejilelogun – egbejilelogun
4600(200*23) -igba metalelogun – egbetalelogun
4800 (200*24) – igba merinlelogun – egberinlelogun
5000 (200*25) -igba meedogbon – egbeedogbon
6000 (2000*3) -egbaa Meta – egbaata
8000 (2000*4) -egbaa merin – egbaarin
10000(2000*5) – egbaa marun-un – egbaarun-un
Igbelewon:
- Fun onka loriki
- Ko onka Yoruba lati egbaa de egbaarun-un
Ise asetilewa:
- Salaye ni kukuru bi awon baba nla wa se n ka nnkan laye atijo pelu irorun ki imo mooko-mooka to de ile wa.
EKA ISE: ASA
ORI ORO: ERE IDARAYA
OFIN ERE IDARAYA KOOKAN
ERE AYO TITA:
- Eniyan meji pere lo n tayo
- Apa otun ni a n ta ayo si ninu iho kookan
- A ko le je ninu iho ti omo ayo ba ti ni ju meta lo
- Iran ni awon osefe maa n wo,won ko gbodo da si ayo
- A kii ta ayo ni owuro
Ere ekun meran
- Eni kan ni o gbodo se ekun tabi eran
- Osere ko gbodo po ju loju agbo ere
- Ekun ko gbodo mu eran ninu agbo ayafi leyin agbo
- Awon osere ni apapo ko gbodo ja rara
Kin ni n leje
- A ko gbodo so pe nnkan ti ko ni eje ni eje
- Itiju nla gbaa ni fun eni ti o ba so pe nnkan ti ko ni eje leje gege bii ijiya ese re,awon elegbe re yoo ho hee lee lori
Ohun elo, anfaani ati ewu ti o wa ninu ere kookan
Ayo tita: opon Ayo, omo Ayo
Anfaani
- Ayo tita n mu ni ronu jinle
- O n je ki a mo nipa oro ati itan atijo
- Erin ati awada maa n waye ni idi ere ayo
- Diduro ni idi ere ayo maa n yo ni kuro ninu ewu ti eniyan le ba pade latari rinrin kiri
Ewu
- Orisi iwosi maa n waye ni idi ayo
- O maa n gba ni lakoko
Ere ekun meran: agbo ere, eniyan meji ti yoo se ekun ati eran, awon omo agbo
Anfaani
- n fun eniyan ni okun ati agbara
- n fi isora ati iyara ko ni
- O n ko omode ni ogbon inu lati le bo lowo ewu ati ota
- O n ko omode lati le da aabo bo egbe won to wa ninu ewu ati lowo ota
- O maa n mu ki emi ife ati isokan gbooro si lokan awon omode
Ewu: awon osere le subu ki won si farapa loju ere
Igbelewon:
- Fun ere idaraya loriki
- Ko ofin ti o de ere ibile kookan
Ise asetilewa:
- Awon ofin wo lo de ere boolu afesegba ti ode oni? Ko ofin marun-un