Ki ni Aroko?
Ko se e ma ni ni aroko kiko (essay writing), idi abajo si ni pe o maa n fi han bi iriri ati ogbon atinuda akekoo se rinle si. Yato si eyi, aroko kiko tun maa n je ki a mo bi akekoo se ni oye to nipa kiko ero okan re sinu iwe.
Igbese to yanranti fun aroko to danto niyi:
- Akekoo gbodo yan ori-oro (topic) kan ti o ni imo nipa re daadaa.
- Akekoo gbodo se ilapa-ero (essay plan) nipa sise alakale kiko awon koko ti yoo se alaye lori ninu aroko.
- Akekoo gbodo se ipin-afo to gunrege (balanced paragraphing) fun aroko re.
- Akekoo gbodo ko ipin-afo fun ifaara (introduction), awon ipin-afo fun awon koko-aroko (essay points) ati ipin-afo fun igunle (conclusion).
- Akekoo gbodo fi awon pontueson sibi to ba ye ninu aroko. Die lara awon pontueson ni ami idanuduro (full-stop), ami idanuduro die (comma), ami ibeere (question mark), ami iyanu (exclamation mark), ami kolonu (colon), ami adamodi-kolonu (semi-colon).
6.Akekoo gbodo se amulo ona-ede (figures of speech) nibi ti o ba ti wa ni ibamu pelu isele inu aroko. Die lara ona-ede ti akekoo le se amulo ni akanlo ede, owe, afiwe, ifohunpeniyan, ati bee lo.
7.Akekoo gbodo tun aroko re ka lati se atunse ti o ye si awon asise to le waye nigba ti o n ko ero-okan re sile.
Orisirisi Aroko
Orisirisi aroko ni o wa ninu eko imo ede Yoruba. Lara won ni a ti ri aroko oniroyin, aroko alariyanjiyan, aroko onisorongbesi, aroko asapejuwe, aroko alalaye ajemo-isipaya, aroko leta kiko.
- Aroko leta kiko pin si gbefe (leta ti a le ko si eni mimo, eyi si maa n ni adiresi kan) ati aigbefe (leta ti a le ko si ile-ise tabi egbe, eyi si maa n ni adiresi meji).
Apeere Ori-Oro Fun Leta Kiko:
- Ko leta si egbon re ni oke oya ki o si so nipa abewo re si awon ile itaja ti igbalode nla ti ijoba ipinle re ko. (neco jun/jul 2015)
- Ko leta si ore re ni ile-eko miiran lati se alaye fun un ohun ti o ro pe o fa aibowo fun oluko mo ni ile-eko wa. (wascce may/jun 2005 & 2016)
- Ko leta si olotuu iwe iroyin nipa bi eto eko se n doju ru lo. (wascce may/jun 2002)
- Ko leta si egbon baba re ti o wa ni ipinle miiran lori isoro to n doju ko ilu abinibi re. (wascce may/jun 2003)
- Ko leta si ore re ti o wa ni ile okeere ki o salaye akitiyan ijoba lori ina eletiiriki ni orile-ede re. (wassce may/jun 2013)
- Aroko oniroyin, gege bi oruko re, maa n da le iroyin isele ti o soju eni tabi ti eniyan feti gbo. Iru aroko bayi ko faye sile fun asodun tabi asoregee nitori pe ohun ti o sele gan-an ni o ye ki o wa ni kiko sile.
Apeere Ori-Oro Fun Aroko Oniroyin:
- Ere kan ti o wo lori telifisan (wascce may/jun 2003)
- Ijanba oko ni awon oju ona wa (wascce may/jun 2004)
- Ijanba kan ti o sele loju mi (ssce may/jun 2011)
- Ayeye iwuye oba ilu mi (wascce nov/dec 2001)
- Aroko alariyanjiyan je eyi ti o fun akekoo ni anfaani lati se afiwe ori-oro meji lati fi han eyi ti o fara mo ni pato. O se Pataki fun akekoo lati ma fari apa kan dakan si.
Apeere Ori-Oro Fun Aroko Alariyanjiyan:
- Ile-eko adani san ju ile-eko ijoba (wascce may/jun 2003)
- Ise adani lowo lori ju ise ijoba lo. (wascce may/jun 2005)
- Omi wulo ju ina monamona lo. (ssce may/jun 2011)
- Owo ni a fi n saye. (wascce nov/dec 2001)
- Esin ti dowo lorile-ede yii. (wassce may/jun 2013)
- Aroko asapejuwe maa n ya aworan si okan eniyan to n ka iru aroko bee bi igba pe iru eni bee fi oju ri ohun ti akekoo n ko nipa re. Irufe aroko yii maa n faye sile fun asodun, afiwe ati orisirisi oro-apejuwe.
Apeere Ori-Oro Fun Aroko Asapejuwe:
- Igi agbon (wascce nov/dec 2001)
- Ebi mi (wascce nov/dec 2001)
- Ayeye ojo awon ewe ti o koja (wascce may/jun 2004)
- Ipo awon oba lawujo ode-oni (wascce may/jun 2003)
- Ile itaja igbalode kan ti ijoba ibile sese ko si agbegbe re. (wascce may/jun 2005)
- Aafin oba ilu kan ti mo mo (ssce may/jun 2011)
- Ayeye iwuye oba ilu mi (wascce nov/dec 2001)
Source: https://olukoni.blogspot.com/2020/01/aroko-yoruba-essay-writing.html
- Aroko Alalaye Ajemo-Isipaya je aroko ti o wa fun idanilekoo ti ko ni abula. Akekoo ti yoo ko irufe aroko bee gbodo ni ekunrere imo lori ori-oro ti o ba yan.
Apeere Ori-Oro Fun Aroko Alalaye Ajemo-Isipaya:
- Imele sise (wascce may/jun 2003)
- Ife (wascce may/jun 2005)
- Okunfa iku odo (ssce may/jun 2011)
- Agbe eleran osin (wascce nov/dec 2001)
- Isale oro ni egbin (wassce may/jun 2013)
Nje O Ti Ka:
- Ibeere Lori Girama
- Oyun Nini Laye Atijo (Ancient Yoruba Midwifery)
- Itan Oranmiyan Omo Oduduwa
- Koseegbe lati Owo Akinwumi Isola
Bawo ni asele ko bere aroko kiko ti a o si pari pelu oro to ni tumo ti ko si ju oju ewe meji lo