Categories
Notes Yoruba

ATUNYEWO IHUN ORO

Iro konsonanti ati iro faweli pelu ami ohun ni a n hun po di oro. Orisi oro meji ni o wa ninu ede Yoruba. Awon ni:

  • Oro ipinle; ati
  • Oro ti a seda

1. ORO IPINLE: Oro ipinle ni awon oro ti a ko le seda won. Apeere:

Adie, eedu, omi, ori, oju, imu, eti, apa, ese, owo, ile, oba, odo, ojo, agbara, omo, iya ati bee bee lo.

Abuda Oro Ipinle

  • Oro-ipinle maa n ni itumo kikun
  • A ko le seda won. Bi apeere:

Iya:                  a ko le so pe        *i+ya   lo di       ‘iya’

      Ori:                  a ko le so pe        *o+ri    lo di       ‘ori’

      Omo:               a ko le so pe        *o+mo lo di      ‘omo’

      Oba:                a ko le so pe        *o+ba  lo di       ‘oba’

Oro ti a seda ati oro-ipinle awon oke yii ko ni ijora itumo. Idi niyi ti a fi pe won ni oro ipinle ti a ko le seda rara.

2. ORO ASEDA: Eyi ni awon oro-oruko ti a seda nipa lilo afomo tabi oro miiran.

Abuda oro ti a seda

  • Oro aseda maa n ni oro ipinle ati afomo tabi oro miiran ti a fi kun un. Apeere:

Afomo ibeere                    Oro-Ipinle                    Oro ti a seda

      a                      +                      de        =          ade

      o                      +                      re         =          ore

(ii)        Oro ipinle ati oro-oruko ti a seda gbodo ni ijora itumo. Apeere:

                                    Oro-Ipinle                    Oro ti a seda

                        a          +          de        =          ade

                        o          +          re         =          ore

(‘de’ ati ‘ade’ ni itumo ti o jade. ‘de’ tumo si ki a fi nnkan bo nnkan ni ori; ‘ade’ ohun ti a de. ‘re’ ati ‘ore’ ni ijora itumo)

ORISII ONA TI A N GBA SEDA ORO-ORUKO

A le seda oro-oruko nipa awon ona wonyii:

  • Lilo Afomo
  • Akanpo Afomo Ibeere ati Oro Ipinle. Akanpo bee yoo di oro-oruko. Bi apeere:
Afomo IbeereOro Ipinle/Oro-IseOro-oruko ti a seda
A a o o ϙ ϙ ai ai on on atiYo se sise ku gbon re sun gbagbo te kawe jeayo ase osise oku ogbon ore aisun aigbagbo onte onkawe atije
  • Akanpo afomo Ibeere ati ipinle to je oro-oruko tabi aropo afarjoruko. Apeere:
Afomo IbeereMofiimu IpinleOro-oruko ti a seda
oni oni oni ti tiIranu eja aso emi eyinoniranu eleja alaso temi teyin
  • Akanpo afomo ibeere ati oro ipinle to je oro-oruko tabi aropo afarajoruko. Apeere:
Afomo IbeereOro-IseOro-IseOro-oruko ti a seda
A i iDa tan gbako je laadako itanje igbala
  • Lilo Afomo Aarin: ‘ki’, ‘de’, ‘ku’, ‘si’ ni aarin apetunpe oro ipinle to je oro-oruko. Apeere:
Mofiimu IpinleAfomo aarinMofiimu ipinleOro-oruko ti a seda
Ile owo iran oro iwa eniyanSi de de ki ki kiile owo iran oro iwa eniyanilesile owodowo irandiran orokoro iwakiwa eniyankeniyan

(ii) Sise Apetunpe Kikun. Eyi le waye nipa:

  • Apetunpe Oro-Oruko
Oro-OrukoOro-OrukoOro-oruko ti a seda
iya ose odun osu ogorun-uniya ose odun osu ogorun-unIyaaya Osoose Odoodun Osoosu Ogoogorun-un
  • Apetunpe Apola-Ise
Apola – IseApola – IseOro-oruko ti a seda
jaye gbomo wole panajaye gbomo wole panajayejaye gbomogbomo wolewole panapana

(d) Apetunpe Elebe: Eyi n waye ti a ba fe dunrun mooro-ise. A o so oro-ise to je mofiimu ipinle di meji, ki a way o faweli ara oro-ise akoko sonu, a o wa fi faweli ‘i’ olohun oke ropo re. bi apeere:

Oro – IseKonsonanti to bere oro – iseMofiimu ‘i’Oro-oruko ti a seda
Ra ka bi weR k b wi i i irira kika bibi wiwe

(iii) Sise Akanpo Oro – Oruko. eyi le waye nipa:

  • Akanpo oro-oruko meji inu eyi ti aranmo yoo ti han
Oro – orukoOro – orukoOro-oruko ti a seda
owo ona agbo eweile ile ile obeowoole onaale agboole ewebe
  • Abranpo Oro-oruko meji inu eyi ti aranmoyoo ti han
Oro – orukoOro – orukoOro-oruko ti a seda
ara enu irunIwaju ona agbonaraawaju enuuna irungbon

(d) Akanpo Afomo Ibeere ati Apetunpe Oro-Oruko. Apeere:

Afomo IbeereOro – OrukoOro – OrukoOro-oruko ti a seda
oni oniojumo osuojumo osuolojoojumo olosoosu

(e) Akanpo Afomo Ibeere ‘oni’ mo oro-oruko meji. apeere

Afomo IbeereOro – orukoOro – OrukoOro-oruko ti a seda
oni oniori ayaire obaoloriire alayaa

(iv) Sise asunki odidi gbolohun di oro-oruko. apeere

GbolohunOro-oruko ti a seda
Oluwa to sin A kuru yejoOluwatosin Akuruyejo

(v) Siso oro-oruko onigbolohun po. Apeere:

            Ifa ni eti                       –                       Faleti

            Oye ba mi ji                 –                       Oyebamiji

            Aje wo ile                    –                       Ajewole

(vi) Lilo ami asoropo oro onigbolohun. Apeere

            a-duro-sigidi-koogun-o-je

            a-losoo-gongo-je’su-eba-ona.

ISE AMUTILEWA

  1. Se itupale akojopo oro-oruko eniyan ti a seda wonyii:
  2. Faleti
  3. Omolola
  4. Ifeolu
  5. Titilayo
  6. Ilesanmi
  7. Iluyomade
  8. Adeoti
  9. Olukoyejo
  10. Adeyemi
  11. Oladiran
  12. Pin awon oro-oruko wonyi si eyi ti a seda ati eyi ti a ko seda
  13. Igunpa
  14. Imu
  15. Aso
  16. Oguntoye
  17. Oko
  18. Ese
  19. Oju
  20. Inufele
  21. Erupe
  22. Eti

AKORI EKO: ITESIWAJU EKO LORI ONA IBANISORO

Ibanisoro ni ona ti eniyan meji tabi ju bee lo n gba fi ero inu won han si ara lona ti o fi ye won yekeyeke. Ona yii ni a n pen i ede. Ede ni o n fun ohun ti a n so ni itumo. Bi eni meji ti won ko gbo ede ara ba n soro, bi ariwo lasan no ohun ti won n so.

Ni aye atijo, awon baba-nla wa kii fi gbogbo enu soro. Won gba wi pe ‘gbogbo aso ko la n sa loorun’. Awon ona kan wa ti won n gba ba eni to sun mo won, to wa nitosi tabi ona jijin soro lai lo enu. Se “Asoku oro ni je omo mi gb’ena”. Won a maa lo eya ara tabi fi nnkan miiran paroko ranse si won, ti itumo ohun ti won soyoo si ye won.

Ni ode-oni ewe, irufe ona ibanisoro yii wa, bi o tile je wi pe ona igbalode ni won n gbe e gba. Gbogbo nnkan wonyi ni a o yewo finnifinni.

IBANISORO AYE ODE ONI

Ni ode-oni, ede ni opomulero ona ibanisoro. Ede ni a fi n se amulo agbara lati ronu ti a o si so ero inu wa jade fun agboye: ti a fi n salaye ohunkohun. Ohn ni a fi n ba ni kedun, ti a n fi n ban i yo, ohun ni a fi n ko ni lekoo ni ile ati ile-iwe. Ede ni a fi n gbani ni iyanju, ti a tun fi n danilaraya. Pataki ede ni awujo ko kere.

Bi ko bas i ede, redio, iwe iroyin ko le wulo. Ede ni redio ati telifison fi n danilaraya, ti won fi n ko ni lekoo, ti won fi n royin. Olaju esin ati ti eko imo sayensi ti mu aye lu jara nipa imo ero. Awon ona ibanisoro ode oni niwonyi:

  • Iwe Iroyin: Ipa pataki ni iwe iroyin n ko bii ona ibanisoro. Henry Town send ni o koko te “Iwe Iroyin fun awon Egba ati Yoruba” jade ni ede Yoruba ni odun 1859. Eyi ni iwe iroyin akoko ni ede Yoruba. Leyin re ni “Iwe Irohin Eko” ti A.M. Thomas je olootu re jade ni odun 1888. Odun 1891 ni Eni-owo J. Vernal gbe “Iwe Eko” jade. Eyi fi han wipe ojo iwe iroyin tip e ni ile Yoruba.
  • Telifison: Ile Yoruba naa ni Telifison akoko ni ile eniyan dudu ti bere ni ilu Ibadan. Bi oruko re “Ero-Amohun-Maworan” ni a n pe o. anfaani gbigbo oro ati riri aworan awon eniyan inu re wo je iranlowo ti ko ni afirwe ninu gbigbe ede ati asa Yoruba laruge. Ona kaan naa niyi ti a fi gbe ero eni si ori eto, ti ibanisoro si n waye.
  • Redio: Ojo redie naa tip e ni ile Yoruba. Bii oruko re ‘ero-asoromagbesi’, oro lasan ni a n ti won n so ni ori eto okan-o-jokan won. Anfaani wa fun eniyan lati gbe ero won si ori afefe lati fi danilaraya, ko ni lekoo, ni lekoo ati fi laniloye.
  • Pako Alarimole lebaa Titi ati Ina Adari-Oko: Awon patako alarimole wa kaakiri oju popo ti won n juwe tabi dari eni si opopona laarin ilu-nla-nla. Bee ni ina adari-oko wan i ojuu Popo ti won n dari oko. Awon meta ni awon fi n paroko lilo ati diduro oko ni ikorita. Awo pupa duro fun ‘duro’, ewu wa lona; awo olomi osan ni ki a si ina oko ni imura sile lati lo, bee ni awo ewe ni ki oko maa lo.
  • Ero-Aye-Lu-Jara: (Intaneeti). Ero ayelujara je gbagede agbaye to si sile fun teru-tomo, ti a le lo, to si wan i arowoto gbogbo eniyan.
  • Leta Kiko: Leta kiko je aroko aye atijo ni orisiirisii ona. Gbigbe ni a n gbe leta, gbigbe naa ni a n gbe aroko ti a ba di ni gbinrin, titu ni a n tu apo-iwe lata, titu naa ni an tu gbinrin ti a di, kika la n ka leta, wiwo ni a n ami aroko. Igba ti won bat u u ni won yoo to mo ohun to wa nibe.
  • Foonu: Oro naa ni a n so si inu foonu ti eni to wan i odikeji ti a pe n gbo. Bi oun naa ba fesi awa ti a pe naa yoo gbo. Ona ibanisoro yii di ilumoka ni ile Yoruba. A le wan i Eko, ki a ma takuroso pelu eni to wan i ilu Oyinbo!
  • Agogo: Bi o tile je pe agogo je ohun-elo iparoko aye atijo, won si n lo won bi ona ibanisoro ni ode-oni. Bi apeere:

Agogo ile isin lilu   –           lati pe eeyan wa josin ni soosi

Agogo omo ile wa –           lati fi pea won akekoo wole

Agogo onisowo      –           lati fi fa onibara won mora.

Read our disclaimer.

AD: Take Free online baptism course: Preachi.com MAKE-MONEY

Discover more from StopLearn

Subscribe now to keep reading and get access to the full archive.

Continue reading