Oro – ise ni oro tabi akojopo oro to n toka si isele tabi nkan ti oluwa se ninu gbolohun. Bi apeere:
Ade ra iwe ede Yoruba
Tuned gun igi osan
“ra” ati “gun” ni opomulero to je oro – ise ti a fi mo nkan ti oluwa se ninu iso oke wonyii:
Abuda oro – ise
i. Oro – ise ni o maa n je yo leyin oluwa. Apeere:
Ade je moinmoin
Nike feran ese
ii. Oro ti o ba tele atoka iyisodi ko lo gbodo je oro –ise. Apeere:
Bola ko je iyan
Sunkanmi o wa
Eya/ orisii oro – ise
1. ORO – ISE KIKUN: Oro – ise ti o le da duro ti o sin i itumo kikun lai sip e a fi oro – ise miiran kun un. Bi apeere:
Sade lo
Bisi sun
Kolade rerin-in
Oro – ise kikun le je
a. Oro – ise agbabo
oro – ise agbabo ni awon oro – ise ti won ko le sai gbabo ninu gbolohun. Bi apeere:
mo de ikoko
bisi ra iyo
kikelomo je eja
Read our disclaimer.
AD: Take Free online baptism course: Preachi.com