Categories
Notes Yoruba Yoruba JSSCE

AKOLE ISE: ONKA YORUBA LATI OOKAN DE AADOTA (1-50)

Onka Yoruba je ona ti a n gba lati ka nnkan ni ona ti yoo rorun.

Nonba

1Ookan 
2Eeji 
3Eeta 
4Eerin 
5Aarun-un 
6Eefa 
7Eeje 
8Eejo 
9Eesan-an 
10Eewaa 
11Ookanla10+1=11
12Eejila10+2=12
13Eetala10+3=13
14Eerinla10+4=14
15Aarun din logun20-5=15
16Eerin din logun20-4=16
17Eeta din logun20-3=17
18Eeji din logun20-2=18
19Ooka din logun20-1=19
20Ogun20
21Ookan le logun20+1=21
22Eeji le logun20+2=22
23Eeta le logun20+3=23
24Eerin le logun20+4=24
25Aarun din logbon30-5=25
26Eerin dni logbon30-4=26
27Eeta din logbon30-3=27
28Eeji din logbon30-2=28
29Ookan din logbon30-1=29
30Ogbon30
31Ookan le logbon30+1=31
32Eeji le logbon30+2=32
33Eeta le logbon30+3=33
34Eerin le logbon30+4=34
35Aarun din logoji40-5=35
36Eerin din logoji40-4=36
37Eeta din logoji40-3=37
38Eeji din logoji40-2=38
39Ookan din logoji40-1=39
40Ogoji40
41Ookan le logoji40+1=41
42Eeji le logoji40+2=42
43Eeta le logoji40+3=43
44Eerin le logoji40+4=44
45Aarun din laadota50-5=45
46Eerin din laadota50-4=46
47Eeta din laadota50-3=47
48Eeji din laadota50-2=48
49Ookan din laadota50-1=49
50Aadota50

EKA ISE: ASA

AKOLE ISE: BI ASA SE JEYO NINU EDE YORUBA

Asa jeyo ninu Ede Yoruba ninu ipede bii owe, akanlo-ede, ewi ,ise sise abbl.

Apeere

               OWEASA TI O JEYOEKO TI AWON ASA YII KO WA
1N o le waa ku ko le ri oye ile baba re je  Oye jijeA gbodo ni igboya
2Faari aseju oko olowo ni mu ni loOge siseKi a maa se koja agbara wa, ki a maa ba te
3Aroba sa kii SojoEru jeje ni awon oba alaye (oye jije)Ki a maa bu ola fun awon alase
4Obe ti bale ile kii je iyaale ile kii seeIgbeyawoAgbodo maa gbe igbe aye alaaafia pelu eni ti ajo n gbe, a ko gbodo se ohun ti enikeji ko fe
 Apeere akanlo-ede  
5Baba ti sunAsa IsinkuBaba ti ku
6O ta teru ni pa aAsa IsinkuO ti  ku                abbl.

EKA ISE: LITIRESO

AKOLE ISE: LITIRESO APILEKO

Eyi ni litireso ti a se akosile ni gba ti imo mooko – mooka de si ile wa.

Litireso apileko pin si ona meta,

i               Ewi

ii              Ere-Onitan
iii             Itan aroso

Litireso Apileko – Itan aroso

koko ti a gbodo tele ti a ba n ka litireso apileko itan aroso.

  1. Onkawe gbodo le salaye itan ni soki
  2. O gbodo le salaye ihuwasi awon eda itan inu iwe itan aroso
  3. O gbodo le mo koko oro itan naa
  4. Onkawe gbodo ko awon eko ti o ri ko jade
  5. O gbodo le fa awon isowolo ede jade bii owe, akanlo ede, abbl
  6. Onkawe gbodo le fa awon asa Yoruba ti o suyo jade
  7. Ba ka naa, O gbodo le mo ibudo itan aroso naa.

Igbelewon:

  • Kin ni litireso apileko?
  • Ona meloo ni o pin si?
  • Ko awon koko to onkawe gbodo tele ti a ba n ka litireso apileko
  • Ko onka lati ookan de aadota

Ise asetilewa: Ko owe ati akanlo ede meji meji ki o si fa asa ti o jeyo ninu okookan ati eko ti o ri ko jade

Read our disclaimer.

AD: Take Free online baptism course: Preachi.com MAKE-MONEY

Discover more from StopLearn

Subscribe now to keep reading and get access to the full archive.

Continue reading