Categories
Notes Yoruba

Akori Eko: Aroko Oni-Soro-N-Gbesi

Aroko ti a ko to da lori itakuroso laaarin eniyan meji tabi ju bee lo ni a n pen i aroko oni-soro-n-gbesi.
Abuda Aroko Onisoro-n-gbesi
(i) O maa n ni akopa bii ere ori itage
(ii) Oro enu akopa kookan maa n han ni iwaju oruko won
(iii) Iso bee ko gbodo gun ju, ko si se regi
(iv) Oro erin ati awada kii gbeyin, a si gbodo year fun awada ako
(v) Isesi won ni a maa n fi sinu ami akamo olofo ( ).
E je ki a ka aroko oni-soro-n-gbesi yii wo, bi apeere:
(Won sese gbe oga titun kan de si ile-iwe re, ko iforo-jomi-tooro oro to waye laarin akekoo meji lori oga titun yii sile).
OGA TITUN
(Ranti ati Yemisi wa ni Kilaasi S.S.2. Won pade ni ikorita meta ni eba ile ounje. Yemisi fe lo kawe, Ranti fe lo pon omi)
Ranti: (o sunmo Yemisi) E ma si ku amojuba t’Oga titun
Yemisi: Baa se ki ni naa nu un. N o kuku tii ri won soju
Ranti: Ma je k’aye o gbo. Iya to wa si ipade apejopo akekooati oluko ni aaro ana
Yemisi: (o mo’ju tai) Se won ni mow a n’be ni? Mo pe de. Kilaasi ni mo gba lo taara
Ranti: Eyin isa-n-sa. Oju yin re e. ipade ohun ma larinrin
Yemisi: Ki lo sele? Won fun yin lo’oyin la? Gbee si mi leti, joo
Ranti: Oyin ko, ado ni. Won kan fi oga han wa ni. Oun alara si gba wan i iyanju pe ki a tepa mose.
Yemisi: Eyuun lo wa mu ipade dun? Osise ni wan i?
Ranti: Ki lo fe ki iya-oniyaa so? Oro iyanju ni akekoo n fe. Abi lo fe ko so. O kuku ti se’pade pelu awon oluko ati awon pirifeeti.
Yemisi: (O tewo pe e) Igba wow a ni ‘pade tiwa? Abi?
Ranti: Ipade wo ni o fe ki Alaaja tun ba wa se?
Yemisi: Wa na, se Musulumi ni?
Ranti: Musulumi ponbele ma ni. O kirun ju awo lo. Oro po. Iya naa le soro lataaro dale!
Yemisi: Awon akekoo Musulumi bo saye nu un. Logan ni yoo ko Mosalasi ti won ti ko pati lati bi odun merin.
Ranti: O ma ni oun ko boroesin wa. O ni bi esi idanwo asejade wa yoo se gbe peeli soke sii ni o je oun logun.
Yemisi: Too. Olorun a fun un se. Awon alale a tii leyin
Ranti: Ti awon alale ti se wa je ninu oro ile iwe?
Yemisi: Ki lo fe n so? Se bi, won ni ‘Isese lagba’?
Ranti: Ooto ma kuku ni. Obatala a ba a f’ase sii
Yemisi: Ase o
(won pinya)
ALAYE
Iwontunwonsi afo enikookan se regi. Ede won lo taara, bee ni awada ibe mo niwon. Akekoo
meji pere ni a lo. Ko dara ki akopa po repete.

ISE AMUTILEWA

  1. Ko abuda aroko oni-soro-n-gbesi marun-un ti o mo
  2. Ro o lokan ara re pe iwo (Femi) ati ore re (Bayo) lo woran are Boolu afesegba to waye laarin Super Eagles ati iko agbaboolu Argentina. Super Eagles feyin won bale ni amin ayo merin si ookan. Eyin mejeeji wa n foro jomi-tooro or obo wa si ile. Bi oro naa se lo re e:
    AARE BOOLU
    Femi: Boolu ale yii ko yoyo, o dun yato. Abi?
    Bayo: Bee ni. Mo gbadun re gan an ni. Ki lo ri si ayo ti Kola gba wole ti Refiri fagi le un?
    Femi: Mo rii. O dun mi wonu eegun. O dabi eni pe Refiri ti fon fere ki Kola to gba boolu naa s’awon.
    Pari iforowero yii. Lo awon gbolohun ibeere ati ede iepri to je mo are boolu afesegba.

AKORI EKO: ONA IBANISORO
Ibanisoro ni ona ti eniyan meji tabi ju bee lo n gba fi ero inu won han si ara lona ti o fi ye won yekeyeke. Ona yii ni a n pen i ede. Ede ni o n fun ohun ti a n so ni itumo. Bi eni meji ti won ko gbo ede ara ba n soro, bi ariwo lasan no ohun ti won n so.
Ni aye atijo, awon baba-nla wa kii fi gbogbo enu soro. Won gba wi pe ‘gbogbo aso ko la n sa loorun’. Awon ona kan wa ti won n gba ba eni to sun mo won, to wa nitosi tabi ona jijin soro lai lo enu. Se “Asoku oro ni je omo mi gb’ena”. Won a maa lo eya ara tabi fi nnkan miiran paroko ranse si won, ti itumo ohun ti won soyoo si ye won.
Ni ode-oni ewe, irufe ona ibanisoro yii wa, bi o tile je wi pe ona igbalode ni won n gbe e gba. Gbogbo nnkan wonyi ni a o yewo finnifinni.
A. ONA IBANISORO NI AYE ATIJO

  1. Lilo Eya Ara fun Ibanisoro: Eya ara ti a n lo fun Ibanisoro je awon eya ara ti a le gbe soke-sodo, ti eni ti a n fii ba soro le ri. Eni bee le wan i egbe eni tabi wa nibi ti ko jinna. Apeere awon eya ara naa niwonyi:
    (i) Oju: Oju se pataki ninu eya ara ifo. Bi apeere, a le fi oju fa ‘ni mora’, kilo fun eniyan bee ni a le fi na eniyan lailo pasan. Eni ti o ba kuna lati mo eyi ni won n bun i alaimojumora. Bi apeere,
    AMI ITUMO/ALAYE
    Ti a ba n soro, ti a wa se oju si eni naa Ki o joo, gbe si mi leyin
    Ki o dake, pe enikan n bo
    Ti a bam o eniyan loju N ko gba tire. Ami ija ni eyi
    N ko fara mo oro ti o n so
    Fe oju mo omode A fi n deru ba a ni
    Ti a ba fi odo oju tabi oju isale wo eniyan Ami ife ni. Okunrin le fi oju isale wo obinrin.

(ii) Ori: Ipa pataki ni ori n ko bii ona Ibanisoro. Igba miiran, eniyan le so ori ko, won a ni oluware n ronu. Bi o ba n fi owo ja ori, to n fi ese jale, ajalu laabi kan ni o sele sii. Bi apeere:
AMI ITUMO/ALAYE
Ti awon eniyan bag be ori so si nnkan ti a n se O dara. Maa se lo
Ti won ba gbon ori Ami ikaaanu ni naa tabi ilodi si nnkan to n se.
Ori gbigbon Rara o. lati fi ilodi si han
Ti won ba bi wa leere oro, ti a mi ori Tooto ni. Bee ni, tabi bee ko
Ti a ba mi ori si isale A pe eniyan pe ki o wa
Ori mimi sotun-un, sosi Rara o tabi bee ko

(iii) Imu: Yoruba kii dede yin imu ti ko bas i ija tabi ikunsinu. Bi apeere:
AMI ITUMO/ALAYE
Ti a ba yinmu si eniyan A n fi eni naa sefe ni, wi pe a ko ka oro ti eni naa n so si rara

(iv) Enu: A le lo enu lai ya a tabi sii raa. Bi apeere:
AMI ITUMO/ALAYE
Ti a ba yo suti tabi yege enu si eniyan A n fi eni naa se yeye ni tabi pe oro eni naa ko mu ogbon wa
A le fi enu sufee Ko si oro ti a ko le fi so

(v) Ejika:
AMI ITUMO/ALAYE
Bi a ba n ban ii soro ti a gbun tabi so ejika Mo gba oro naa wole bii otito
Mo lodi si oro naa

(vi) Ese:
AMI ITUMO/ALAYE
Bi a ba fi ese janle Ami ilodi si nnkan kan ni eyi je
Tite eniyan lese mole A n kilo fun un pe ki o ma se nnkan kan tabi ki o dake
A le fi pe akiyesi re si nnkan kan
Fi ese mole A fi n han pe a ko nifee si ohun ti enikan n so.

(vii) Eekanna
AMI ITUMO/ALAYE
Sise ni leekanna Ikilo nip e ki o dake oro tabi fi pe akiyesi re si nnkan kan

(viii) Owo: Ilo owo bi ona ibanisoro po. A le ju owo si eniyan pe ki o wa, bee ni o le ya owo kan naa yii lati bun i.
AMI ITUMO/ALAYE
Bi a ba sewo si eniyan Ki o wa tabi ki o duro de wa
Ti a ba juwo si eniyan A n kii ni
A n dagbere fun un pe ‘O digba o se’
A n le eni naa siwaju
Ti a bay a owo si eniyan A n bu iya eni naa ni
(ix) Ete: Orisiirisii ona ni a le gba lo ete lati soro. Apeere.
AMI ITUMO/ALAYE
A le yo suti ete Lati fi saata tabi bun i
A le yo ete si enikan Lati juwe tabi so ibi ti nnkan wa

IPAROKO
Aroko je ona kan ti an gba ba ara eni soro ni aye atijo. Bi awon agba ba fe soro asiri ti eni ti won fe so o fun ko si nitosi, tabi ti won ba fe ranse sile ni asiri, aroko ni won n lo. Aroko pipa ranse si ni ko gba sise alaye repete. Aroko ni yoo tumo ara re fun eni ti a ba ran an si.
Die ninu egbaagboje ona ti awon baba-nle wa n gba paroko ranse si eniyan ni wonyii:
(i) Ilu Lilu: Ni ile Yoruba, ilu n koi pa pataki ninu ona ibanisoro ni aye atijo. Ko si ohun ti won ko le fi wi. Ilu ni awon baba-nla wa fi maa n ranse si oju ogun. Bi ogun bag bona janjan, ilu ni won n ki awon asaaju.
(ii) Edan Ogboni: Edan je orisii opa Ogboni kan ti o maa n ni ere ni ori re. bi enikan ba je gbese, ti won wa fi edan Ogboni ranse sii, eni naa ko gbodo jafara bi o bat i rii gba. O ni lati wa owo na san kiakia. Eyi je asa larin awon Egba.
(iii) Opa Ase: Oba nikan ni o n fi opa ase paroko. Nitori pe kii se gbogbo ode ni Oba le e lo, opa ase yii ni Oba maa n gbe ranse lati fi han wi pe oun wa nibe. Bi Oba bas i fe ri enikan ni kiakia, opa ase ni yoo fi ranse sii.
(iv) Irukere: Oba, Baale, Ijoye ati agba-awo ni won n fi irukere paroko. Ti won bay o eyo irun irukere kan, ki won ta ni koko si inu aso pupa, ti won ba fi ranse si enikan, apeere ija tabi wiwa pipon onu eni tabi pe ija n bo niyi.
(vi) Awo Edun
(vii) Sigidi
(viii) Iye Adie
(ix) Ebiti ati Awo Ehoro
(x) Owo-Eyo Meta
(xi) Aso Ibora
(xii) Igbale
(xiii) Eepo igi ose ati aso pupa
(xiv) Idaji agbe emu tabi ajadii agbe
(xv) Esun-isu
(xvi) Igi sisa loge
(xvii) Morinwo tabi Aso Pupa
(xviii) Eni
(xix) Eeru
Awon aroko to je mo Onka: Iwonyi ni awon ami aroko to je mo onka Yoruba. Apeere:
AMI ITUMO/ALAYE
Eeta Ti a ba fi nnkan meta ranse si eniyan, o tumo si pe a ta onitohun danu.
Aarun-un Awon onifa ni won n lo lati so fun eni naa ki o se kankan lori ohun ti o mu ni paroko naa ki ojo marun-un to pe
Eefa Ami ife ni eyi n toka si. Okunrin le fi ranse si obinrin pe ki awon fi ara mora.
Eeje Ojo ije egungun ati oro. O tun le tumo sip e ki eni ti a paroko ranse si ri ni ki ojo meje to pe
Eejo Bi a ba fi nnkan mejo paroko ranse sin i, to ba je owo-eyo, o tumo si pe ko si ewu loro eni naa nitori ile jo
Eesan-an Ami ki eniyan so ewe agbeje mowo niyi, paapaa si eni to n du oye. A fi so fun un pe “Ilesanmi dun ju oye lo”.
Eewaa Ti a ba fi owo-eyo mewaa ranse si eeyan, o tumo sip e ki o wa. Won ni “Eewaa kii wa eni tire ti.”

Awon aroko to je mo awo
Awo Ohun to duro fun
Funfun Nnkan mimo/alaafia
Dudu Nnkan buburu. Obinrin to n sofo maa n wo aso dudu
Pupa Ohun to lewa. Pupo ni aso orisa Sango ati Esu

Awon aroko to je mo iro: Awon ohun elo ibanisoro ni a fi n gbe iro jade niwonyii:
Ohun-elo Alaye ilo won

Fere Fere le je eyi ti a fi irin, igi tabi iwo eran se. orisii fere to wa ni: Pakuta, Anbere, Tioko, Kakaki, Turumagbe, Talaka, Ekuku, Ti-an-ko, Iwo ati bee bee lo.
(i) Awon ode n fon ekutu ati tioko laarin ara won
(ii) Won n lo fere lati pe ara won ni igbe ode
(iii) Won n fon kakaki lati fi ki Oba ni Aafin
Agogo Orisii agogo lo wa:
(i) Alagogo Oba maa n lu u lati fi pe eniyan jo lati jise Oba
(ii) Agogo orun aja ni lati mo ibi ti aja ode wa ninu igbo
(iii) Agogo ifa ati ilu aran tabi ipese ni awon awo n lo ki ohun didun le jade
(iv) Agogo ode asode ni lati kede pea won ti gbode

B. IBANISORO AYE ODE ONI
Ni ode-oni, ede ni opomulero ona ibanisoro. Ede ni a fi n se amulo agbara lati ronu ti a o si so ero inu wa jade fun agboye: ti a fi n salaye ohunkohun. Ohn ni a fi n ba ni kedun, ti a n fi n ban i yo, ohun ni a fi n ko ni lekoo ni ile ati ile-iwe. Ede ni a fi n gbani ni iyanju, ti a tun fi n danilaraya. Pataki ede ni awujo ko kere.
Bi ko bas i ede, redio, iwe iroyin ko le wulo. Ede ni redio ati telifison fi n danilaraya, ti won fi n ko ni lekoo, ti won fi n royin. Olaju esin ati ti eko imo sayensi ti mu aye lu jara nipa imo ero. Awon ona ibanisoro ode oni niwonyi:
(i) Iwe Iroyin: Ipa pataki ni iwe iroyin n ko bii ona ibanisoro. Henry Town send ni o koko te “Iwe Iroyin fun awon Egba ati Yoruba” jade ni ede Yoruba ni odun 1859. Eyi ni iwe iroyin akoko ni ede Yoruba. Leyin re ni “Iwe Irohin Eko” ti A.M. Thomas je olootu re jade ni odun 1888. Odun 1891 ni Eni-owo J. Vernal gbe “Iwe Eko” jade. Eyi fi han wipe ojo iwe iroyin tip e ni ile Yoruba.
(ii) Telifison: Ile Yoruba naa ni Telifison akoko ni ile eniyan dudu ti bere ni ilu Ibadan. Bi oruko re “Ero-Amohun-Maworan” ni a n pe o. anfaani gbigbo oro ati riri aworan awon eniyan inu re wo je iranlowo ti ko ni afirwe ninu gbigbe ede ati asa Yoruba laruge. Ona kaan naa niyi ti a fi gbe ero eni si ori eto, ti ibanisoro si n waye.
(iii) Redio: Ojo redie naa tip e ni ile Yoruba. Bii oruko re ‘ero-asoromagbesi’, oro lasan ni a n ti won n so ni ori eto okan-o-jokan won. Anfaani wa fun eniyan lati gbe ero won si ori afefe lati fi danilaraya, ko ni lekoo, ni lekoo ati fi laniloye.
(iv) Pako Alarimole lebaa Titi ati Ina Adari-Oko: Awon patako alarimole wa kaakiri oju popo ti won n juwe tabi dari eni si opopona laarin ilu-nla-nla. Bee ni ina adari-oko wan i ojuu Popo ti won n dari oko. Awon meta ni awon fi n paroko lilo ati diduro oko ni ikorita. Awo pupa duro fun ‘duro’, ewu wa lona; awo olomi osan ni ki a si ina oko ni imura sile lati lo, bee ni awo ewe ni ki oko maa lo.
(v) Ero-Aye-Lu-Jara: (Intaneeti). Ero ayelujara je gbagede agbaye to si sile fun teru-tomo, ti a le lo, to si wan i arowoto gbogbo eniyan.
(vi) Leta Kiko: Leta kiko je aroko aye atijo ni orisiirisii ona. Gbigbe ni a n gbe leta, gbigbe naa ni a n gbe aroko ti a ba di ni gbinrin, titu ni a n tu apo-iwe lata, titu naa ni an tu gbinrin ti a di, kika la n ka leta, wiwo ni a n ami aroko. Igba ti won bat u u ni won yoo to mo ohun to wa nibe.
(vii) Foonu: Oro naa ni a n so si inu foonu ti eni to wan i odikeji ti a pe n gbo. Bi oun naa ba fesi awa ti a pe naa yoo gbo. Ona ibanisoro yii di ilumoka ni ile Yoruba. A le wan i Eko, ki a ma takuroso pelu eni to wan i ilu Oyinbo!
(viii) Agogo: Bi o tile je pe agogo je ohun-elo iparoko aye atijo, won si n lo won bi ona ibanisoro ni ode-oni. Bi apeere:
Agogo ile isin lilu – lati pe eeyan wa josin ni soosi
Agogo omo ile wa – lati fi pea won akekoo wole
Agogo onisowo – lati fi fa onibara won mora.

ISE ASETILEWA

  1. So marun-un lara ona ibanisoro ti o mo
  2. So awon eya ara marun-un ti a fi n ba ara eni soro
  3. Daruko marun-un ni ara ona ibanisoro ni aye ode oni
    OSE KERIN-IN
    AKORI EKO: ATUNYEWO IHUN ORO
    Iro konsonanti ati iro faweli pelu ami ohun ni a n hun po di oro. Orisi oro meji ni o wa ninu ede Yoruba. Awon ni:
    (i) Oro ipinle; ati
    (ii) Oro ti a seda
  4. ORO IPINLE: Oro ipinle ni awon oro ti a ko le seda won. Apeere:
    Adie, eedu, omi, ori, oju, imu, eti, apa, ese, owo, ile, oba, odo, ojo, agbara, omo, iya ati bee bee lo.
    Abuda Oro Ipinle
    (i) Oro-ipinle maa n ni itumo kikun
    (ii) A ko le seda won. Bi apeere:
    Iya: a ko le so pe *i+ya lo di ‘iya’
    Ori: a ko le so pe *o+ri lo di ‘ori’
    Omo: a ko le so pe *o+mo lo di ‘omo’
    Oba: a ko le so pe *o+ba lo di ‘oba’
    Oro ti a seda ati oro-ipinle awon oke yii ko ni ijora itumo. Idi niyi ti a fi pe won ni oro ipinle ti a ko le seda rara.
  5. ORO ASEDA: Eyi ni awon oro-oruko ti a seda nipa lilo afomo tabi oro miiran.
    Abuda oro ti a seda
    (i) Oro aseda maa n ni oro ipinle ati afomo tabi oro miiran ti a fi kun un. Apeere:
    Afomo ibeere Oro-Ipinle Oro ti a seda
    a + de = ade
    o + re = ore
    (ii) Oro ipinle ati oro-oruko ti a seda gbodo ni ijora itumo. Apeere:
    Oro-Ipinle Oro ti a seda
    a + de = ade
    o + re = ore
    (‘de’ ati ‘ade’ ni itumo ti o jade. ‘de’ tumo si ki a fi nnkan bo nnkan ni ori; ‘ade’ ohun ti a de. ‘re’ ati ‘ore’ ni ijora itumo)

ORISII ONA TI A N GBA SEDA ORO-ORUKO
A le seda oro-oruko nipa awon ona wonyii:
(i) Lilo Afomo
(a) Akanpo Afomo Ibeere ati Oro Ipinle. Akanpo bee yoo di oro-oruko. Bi apeere:
Afomo Ibeere Oro Ipinle/Oro-Ise Oro-oruko ti a seda
A
a
o
o
ϙ
ϙ
ai
ai
on
on
ati Yo
se
sise
ku
gbon
re
sun
gbagbo
te
kawe
je ayo
ase
osise
oku
ogbon
ore
aisun
aigbagbo
onte
onkawe
atije

(b) Akanpo afomo Ibeere ati ipinle to je oro-oruko tabi aropo afarjoruko. Apeere:
Afomo Ibeere Mofiimu Ipinle Oro-oruko ti a seda
oni
oni
oni
ti
ti Iranu
eja
aso
emi
eyin oniranu
eleja
alaso
temi
teyin
(d) Akanpo afomo ibeere ati oro ipinle to je oro-oruko tabi aropo afarajoruko. Apeere:
Afomo Ibeere Oro-Ise Oro-Ise Oro-oruko ti a seda
A
i
i Da
tan
gba ko
je
la adako
itanje
igbala
(e) Lilo Afomo Aarin: ‘ki’, ‘de’, ‘ku’, ‘si’ ni aarin apetunpe oro ipinle to je oro-oruko. Apeere:
Mofiimu Ipinle Afomo aarin Mofiimu ipinle Oro-oruko ti a seda
Ile
owo
iran
oro
iwa
eniyan Si
de
de
ki
ki
ki ile
owo
iran
oro
iwa
eniyan ilesile
owodowo
irandiran
orokoro
iwakiwa
eniyankeniyan

(ii) Sise Apetunpe Kikun. Eyi le waye nipa:
(a) Apetunpe Oro-Oruko
Oro-Oruko Oro-Oruko Oro-oruko ti a seda
iya
ose
odun
osu
ogorun-un iya
ose
odun
osu
ogorun-un Iyaaya
Osoose
Odoodun
Osoosu
Ogoogorun-un
(b) Apetunpe Apola-Ise
Apola – Ise Apola – Ise Oro-oruko ti a seda
jaye
gbomo
wole
pana jaye
gbomo
wole
pana jayejaye
gbomogbomo
wolewole
panapana
(d) Apetunpe Elebe: Eyi n waye ti a ba fe dunrun mooro-ise. A o so oro-ise to je mofiimu ipinle di meji, ki a way o faweli ara oro-ise akoko sonu, a o wa fi faweli ‘i’ olohun oke ropo re. bi apeere:
Oro – Ise Konsonanti to bere oro – ise Mofiimu ‘i’ Oro-oruko ti a seda
Ra
ka
bi
we R
k
b
w i
i
i
i rira
kika
bibi
wiwe
(iii) Sise Akanpo Oro – Oruko. eyi le waye nipa:
(a) Akanpo oro-oruko meji inu eyi ti aranmo yoo ti han
Oro – oruko Oro – oruko Oro-oruko ti a seda
owo
ona
agbo
ewe ile
ile
ile
obe owoole
onaale
agboole
ewebe
(b) Abranpo Oro-oruko meji inu eyi ti aranmoyoo ti han
Oro – oruko Oro – oruko Oro-oruko ti a seda
ara
enu
irun Iwaju
ona
agbon araawaju
enuuna
irungbon
(d) Akanpo Afomo Ibeere ati Apetunpe Oro-Oruko. Apeere:
Afomo Ibeere Oro – Oruko Oro – Oruko Oro-oruko ti a seda
oni
oni ojumo
osu ojumo
osu olojoojumo
olosoosu

(e) Akanpo Afomo Ibeere ‘oni’ mo oro-oruko meji. apeere
Afomo Ibeere Oro – oruko Oro – Oruko Oro-oruko ti a seda
oni
oni ori
aya ire
oba oloriire
alayaa
(iv) Sise asunki odidi gbolohun di oro-oruko. apeere
Gbolohun Oro-oruko ti a seda
Oluwa to sin
A kuru yejo Oluwatosin
Akuruyejo
(v) Siso oro-oruko onigbolohun po. Apeere:
Ifa ni eti – Faleti
Oye ba mi ji – Oyebamiji
Aje wo ile – Ajewole
(vi) Lilo ami asoropo oro onigbolohun. Apeere
a-duro-sigidi-koogun-o-je
a-losoo-gongo-je’su-eba-ona.

ISE AMUTILEWA

  1. Se itupale akojopo oro-oruko eniyan ti a seda wonyii:
    (i) Faleti
    (ii) Omolola
    (iii) Ifeolu
    (iv) Titilayo
    (v) Ilesanmi
    (vi) Iluyomade
    (vii) Adeoti
    (viii) Olukoyejo
    (ix) Adeyemi
    (x) Oladiran
  2. Pin awon oro-oruko wonyi si eyi ti a seda ati eyi ti a ko seda
    (i) Igunpa
    (ii) Imu
    (iii) Aso
    (iv) Oguntoye
    (v) Oko
    (vi) Ese
    (vii) Oju
    (viii) Inufele
    (ix) Erupe
    (x) Eti
    AKORI EKO: ITESIWAJU EKO LORI ONA IBANISORO
    Ibanisoro ni ona ti eniyan meji tabi ju bee lo n gba fi ero inu won han si ara lona ti o fi ye won yekeyeke. Ona yii ni a n pen i ede. Ede ni o n fun ohun ti a n so ni itumo. Bi eni meji ti won ko gbo ede ara ba n soro, bi ariwo lasan no ohun ti won n so.
    Ni aye atijo, awon baba-nla wa kii fi gbogbo enu soro. Won gba wi pe ‘gbogbo aso ko la n sa loorun’. Awon ona kan wa ti won n gba ba eni to sun mo won, to wa nitosi tabi ona jijin soro lai lo enu. Se “Asoku oro ni je omo mi gb’ena”. Won a maa lo eya ara tabi fi nnkan miiran paroko ranse si won, ti itumo ohun ti won soyoo si ye won.
    Ni ode-oni ewe, irufe ona ibanisoro yii wa, bi o tile je wi pe ona igbalode ni won n gbe e gba. Gbogbo nnkan wonyi ni a o yewo finnifinni.
    IBANISORO AYE ODE ONI
    Ni ode-oni, ede ni opomulero ona ibanisoro. Ede ni a fi n se amulo agbara lati ronu ti a o si so ero inu wa jade fun agboye: ti a fi n salaye ohunkohun. Ohn ni a fi n ba ni kedun, ti a n fi n ban i yo, ohun ni a fi n ko ni lekoo ni ile ati ile-iwe. Ede ni a fi n gbani ni iyanju, ti a tun fi n danilaraya. Pataki ede ni awujo ko kere.
    Bi ko bas i ede, redio, iwe iroyin ko le wulo. Ede ni redio ati telifison fi n danilaraya, ti won fi n ko ni lekoo, ti won fi n royin. Olaju esin ati ti eko imo sayensi ti mu aye lu jara nipa imo ero. Awon ona ibanisoro ode oni niwonyi:
    (i) Iwe Iroyin: Ipa pataki ni iwe iroyin n ko bii ona ibanisoro. Henry Town send ni o koko te “Iwe Iroyin fun awon Egba ati Yoruba” jade ni ede Yoruba ni odun 1859. Eyi ni iwe iroyin akoko ni ede Yoruba. Leyin re ni “Iwe Irohin Eko” ti A.M. Thomas je olootu re jade ni odun 1888. Odun 1891 ni Eni-owo J. Vernal gbe “Iwe Eko” jade. Eyi fi han wipe ojo iwe iroyin tip e ni ile Yoruba.
    (ii) Telifison: Ile Yoruba naa ni Telifison akoko ni ile eniyan dudu ti bere ni ilu Ibadan. Bi oruko re “Ero-Amohun-Maworan” ni a n pe o. anfaani gbigbo oro ati riri aworan awon eniyan inu re wo je iranlowo ti ko ni afirwe ninu gbigbe ede ati asa Yoruba laruge. Ona kaan naa niyi ti a fi gbe ero eni si ori eto, ti ibanisoro si n waye.
    (iii) Redio: Ojo redie naa tip e ni ile Yoruba. Bii oruko re ‘ero-asoromagbesi’, oro lasan ni a n ti won n so ni ori eto okan-o-jokan won. Anfaani wa fun eniyan lati gbe ero won si ori afefe lati fi danilaraya, ko ni lekoo, ni lekoo ati fi laniloye.
    (iv) Pako Alarimole lebaa Titi ati Ina Adari-Oko: Awon patako alarimole wa kaakiri oju popo ti won n juwe tabi dari eni si opopona laarin ilu-nla-nla. Bee ni ina adari-oko wan i ojuu Popo ti won n dari oko. Awon meta ni awon fi n paroko lilo ati diduro oko ni ikorita. Awo pupa duro fun ‘duro’, ewu wa lona; awo olomi osan ni ki a si ina oko ni imura sile lati lo, bee ni awo ewe ni ki oko maa lo.
    (v) Ero-Aye-Lu-Jara: (Intaneeti). Ero ayelujara je gbagede agbaye to si sile fun teru-tomo, ti a le lo, to si wan i arowoto gbogbo eniyan.
    (vi) Leta Kiko: Leta kiko je aroko aye atijo ni orisiirisii ona. Gbigbe ni a n gbe leta, gbigbe naa ni a n gbe aroko ti a ba di ni gbinrin, titu ni a n tu apo-iwe lata, titu naa ni an tu gbinrin ti a di, kika la n ka leta, wiwo ni a n ami aroko. Igba ti won bat u u ni won yoo to mo ohun to wa nibe.
    (vii) Foonu: Oro naa ni a n so si inu foonu ti eni to wan i odikeji ti a pe n gbo. Bi oun naa ba fesi awa ti a pe naa yoo gbo. Ona ibanisoro yii di ilumoka ni ile Yoruba. A le wan i Eko, ki a ma takuroso pelu eni to wan i ilu Oyinbo!
    (viii) Agogo: Bi o tile je pe agogo je ohun-elo iparoko aye atijo, won si n lo won bi ona ibanisoro ni ode-oni. Bi apeere:
    Agogo ile isin lilu – lati pe eeyan wa josin ni soosi
    Agogo omo ile wa – lati fi pea won akekoo wole
    Agogo onisowo – lati fi fa onibara won mora.

Click here to ask a question and get an answer published in the forum. Read our disclaimer.

Get paid for every topic you create in: Shoutam.com Forum!MAKE-MONEY