Awon Yoruba ni awon ona ti won n gba ba ara won soro asiri ni atijo bi ati ile je pe eni ti won n so fun ko si nitori. Ami lasan ni won yoo fi ranse ti ami naa yoo si tumo ara re. Fifi ohun kan ranse bi ami lati fi aye pataki kan ye eni ti a fi ohun naa ranse sin i a n pen i aroko.
Aroko ni ami tabi ona ede ti o leje oro kan tabi ohun to duro fun nkan miiran ti a le lo lati fi ba ara eni soro lona ijinle eyi o fun wan i orisirisi itumo ti o yato si ohun ti ami naa je kii se gbogbo aroko ni a n fin ranse sin i. Awon aroko kan wa ti o je pe ibi ti yio ti rorun fun eni ti a n paroko si lati ti ri ni a n fi won si eyi yoo fun wa ni anfaani lati le tete ri.
ORISII AROKO
- Aroko ikilo
- Aroko itonisona
- Aroko ikede
- Aroko ibawi
- Aroko ti n fi ero inu eni han abbl
1. AROKO IKILO: Bi eniyan ba n huwa aito bii fife iyawo ile elo miiran, ole jija tabi huwa odaran tabi ika. Won le paroko ranse si iru eni bee ki o jawo tabi ki o wa toro aforiji laijebe won yoo fi ijiya ti oto si onitohun je e. Apeere:
AMI AROKO | ITUMO AROKO |
1. Ti won ba fi iye adiye si ehinkule okunrin | Won n ki lo fun pe ki ojawo ninu ajosepo pelu obinrin olobinrin |
2. Eso omo osan | Eyi ti e ba se ni o dara |
3. Ooya ti a fi n yanu | Ipinya de |
4. Efun | Oye n bow a kan o |
5. Ikarahun igbin | Okan mi n fa si o |
6. Eesan | Iroyin buruku ni a n gbo ni pa re |
7. Okuta kekere | Ara wa lebi okuta |
8. Awo ehoro | Ki o yara ma salo |
9. Igbo eyi nahun | Ki a mu oro naa ni koko |
10. Ogan ese adie | Je ki a ni nnkan ti a o te |
11. Ajoku owu | Ami iku ni, ewu n be fun e |
12. Oju eja | Ki a ri nkan daju |
13. Eluti afin re aro | A ko ri imole nkan naa daadaa |
14. Awe obi | Oro naa pari patapata |
15. Esuru | Ora naa ti sun mi |
16. Agbayun | Adun ni oran meta |
17. Owo/igbale | A gba ese re kuro lako |
18. Iyepe didi lewe ranse | Ebe tabi imule ki eniyan ma dale |
19. Kanikani tuntun ati ose | Iyawo eni naa ti bimo tuntun |
20. Fifi iye adie ranse | Mo n reti re kiakia |
21. Eyin aja ati osun | Fi oro naa se soun fi raara (aja kii sa n omo re de eegun) |
APEERE AROKO IKILO
AMI AROKO | ITUMO AROKO |
1. Eesan | Eyi tumo sip e iroyin aburu ni won gbo si eni naa |
2. Ti won ba fi irepe aso obinrin ati ada ranse si okunrin miran | Ki okunrin naa jawo ninu ife ikoko pelu obinrin olobinrin |
3. Ti ilu kan ba fi ata ati iyo ranse si ilu keji | Won ti ni ikunsinu ara won tele ki won si ma mura ogun |
4. Ti a ba fi esunsu ranse si eniyan | Agbo pe eni naa fe dawo e le ohun kan ti ako fe ki o dawole, ki o jawo kiakia |
AROKO ATONISONA: Aroko wonyi wa lati to eniyan sona ki a maa baa ko sinu ewu tabi isoro. A kii fi aroko yii ranse, ogangan ibi ti yio ti rorun fun eni ti aranse si lati ri ni an gbe won si. Apeere:
AMI AROKO | ITUMO AROKO |
1. Ti won ba fi eeru si ori ewe ni eba ona | Ode kan wa nitosi ibe tabi pe o ti gba ibe koja |
2. Ti won ba ta mariwo tabi aso si oju ona | Enikeni ko gbodo gba oju ona naa koja nitori ewu wa nibe |
Read our disclaimer.
AD: Take Free online baptism course: Preachi.com