Categories
Notes Yoruba

Akori Eko: Aroko

Awon Yoruba ni awon ona ti won n gba ba ara won soro asiri ni atijo bi ati ile je pe eni ti won n so fun ko si nitori. Ami lasan ni won yoo fi ranse ti ami naa yoo si tumo ara re. Fifi ohun kan ranse bi ami lati fi aye pataki kan ye eni ti a fi ohun naa ranse sin i a n pen i aroko.

Aroko ni ami tabi ona ede ti o leje oro kan tabi ohun to duro fun nkan miiran ti a le lo lati fi ba ara eni soro lona ijinle eyi o fun wan i orisirisi itumo ti o yato si ohun ti ami naa je kii se gbogbo aroko ni a n fin ranse sin i. Awon aroko kan wa ti o je pe ibi ti yio ti rorun fun eni ti a n paroko si lati ti ri ni a n fi won si eyi yoo fun wa ni anfaani lati le tete ri.

ORISII AROKO

  1. Aroko ikilo
  2. Aroko itonisona
  3. Aroko ikede
  4. Aroko ibawi
  5. Aroko ti n fi ero inu eni han abbl

1. AROKO IKILO: Bi eniyan ba n huwa aito bii fife iyawo ile elo miiran, ole jija tabi huwa odaran tabi ika. Won le paroko ranse si iru eni bee ki o jawo tabi ki o wa toro aforiji laijebe won yoo fi ijiya ti oto si onitohun je e. Apeere:

AMI AROKOITUMO AROKO
1. Ti won ba fi iye adiye si ehinkule okunrinWon n ki lo fun pe ki ojawo ninu ajosepo pelu obinrin olobinrin
2. Eso omo osanEyi ti e ba se ni o dara
3. Ooya ti a fi n yanuIpinya de
4. EfunOye n bow a kan o
5. Ikarahun igbinOkan mi n fa si o
6. EesanIroyin buruku ni a n gbo ni pa re
7. Okuta kekereAra wa lebi okuta
8. Awo ehoroKi o yara ma salo
9. Igbo eyi nahunKi a mu oro naa ni koko
10. Ogan ese adieJe ki a ni nnkan ti a o te
11. Ajoku owuAmi iku ni, ewu n be fun e
12. Oju ejaKi a ri nkan daju
13. Eluti afin re aroA ko ri imole nkan naa daadaa
14. Awe obiOro naa pari patapata
15. EsuruOra naa ti sun mi
16. AgbayunAdun ni oran meta
17. Owo/igbaleA gba ese re kuro lako
18. Iyepe didi lewe ranseEbe tabi imule ki eniyan ma dale
19. Kanikani tuntun ati oseIyawo eni naa ti bimo tuntun
20. Fifi iye adie ranseMo n reti re kiakia
21. Eyin aja ati osunFi oro naa se soun fi raara (aja kii sa n omo re de eegun)

APEERE AROKO IKILO

AMI AROKOITUMO AROKO
1. EesanEyi tumo sip e iroyin aburu ni won gbo si eni naa
2. Ti won ba fi irepe aso obinrin ati ada ranse si okunrin miranKi okunrin naa jawo ninu ife ikoko pelu obinrin olobinrin
3. Ti ilu kan ba fi ata ati iyo ranse si ilu keji Won ti ni ikunsinu ara won tele ki won si ma mura ogun
4. Ti a ba fi esunsu ranse si eniyanAgbo pe eni naa fe dawo e le ohun kan ti ako fe ki o dawole, ki o jawo kiakia

AROKO ATONISONA: Aroko wonyi wa lati to eniyan sona ki a maa baa ko sinu ewu tabi isoro. A kii fi aroko yii ranse, ogangan ibi ti yio ti rorun fun eni ti aranse si lati ri ni an gbe won si. Apeere:

AMI AROKOITUMO AROKO
1. Ti won ba fi eeru si ori ewe ni eba onaOde kan wa nitosi ibe tabi pe o ti gba ibe koja
2. Ti won ba ta mariwo tabi aso si oju onaEnikeni ko gbodo gba oju ona naa koja nitori ewu wa nibe

Click here to ask a question and get an answer published in the forum. Read our disclaimer.

Get paid for every topic you create in: Shoutam.com Forum!MAKE-MONEY