Oro agbaso ni oro ti agba lenu oloro so fun elomiran ti ko si nitosi nigba ti isele tabi ipede naa waye. Eyi fara pe iroyin siso nipa ohun tabi eto kan pato. Nipa yiyi afosafo si afo agabran, awon eyo oro kookan gbodo yipada lati oro ti a gba so lenu eni ti o n safo taata. Awon wunren ti a ba nba pade ninu afo agbaran tabi oro agbaso niwonyi so wipe, ni, boya, salaye, beere, pase abbl. Bi apeere:
Bola beere boya o ti jeun
Akin pase pe ki won bo sita kiakia
Dosunmu so pe oun ti jeun
Won se ajodun egbe won ni ana
Boladale ni oun ko jo ye.
Ise Asetilewa
Yi awon afo asafo isale yii si oro agbaso
- Filani oju n ro mi
- Oluko: dide duro sibe Bosun
- Kolade: se o ti jeun Wole?
- Bimpe: Alabuburu ni mo la